Baba Suwe: Wo ìdí táwọn Alfa fi yarí láti fi pósí sin olóògbé bí ẹbí ṣe ń fẹ́

Awuyewuye bẹ silẹ nibi eto isinku gbajumọ osere tiata ati adẹrinposonu nni, Babatunde Omidina, ta tun mọ si Baba Suwe.
Awuyewuye naa lo waye laarin awọn ẹbi oloogbe ati awọn Alfa musulumi to fẹ sin oku oloogbe naa.
Idi ni pe awọn ẹbi Baba Suwe ra posi olowo iyebiye lati sin baba wọn eyi to tako ilana ẹsin ẹsin Islam.
- Ìdí rèé ta ṣe fi pósí gbe Baba Suwe tó jẹ́ Mùsùlúmì - Aya rẹ̀ àkọ́fẹ́ ṣàlàyé
- Ẹ wo ẹni tó ń jẹ́ Suwebatu nínú ẹbí Baba Suwe àti ohun tó sọ nípa olóògbé
- Bí ètò ìsìnkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé, bó ṣe ń wọ ilẹ̀ sùn lónìí
- Mọ̀ si nípa ìtàn ayé Baba Suwe tó ń wọ káà ilẹ̀ sún lónìí
- Bàbá mi máa ń sunkún torí bí kò ṣe le padà ṣeré tíátà mọ́ - Ọmọ Baba Suwe
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Wo nǹkan mẹ́jọ tí o lè má mọ̀ nípa Baba Suwe tó dolóògbé
Koda, aya akọfẹ oloogbe naa, Suwebatu Ayodele Omidina salaye fun BBC Yoruba pe awọn ọmọ ati ẹbi ọkọ oun lo fẹ ki wọn fi posi sin baba wọn tii se musulumi.
Amọ igbesẹ naa lo fa awuyewuye, ti idaduro si wa diẹ, ki wọn to bẹrẹ eto isinku naa.

Alfa agba to siwaju awọn onimọ ẹsin Islam to fẹ sin oku Baba Suwe, Sheikh Ahmad Olanrewaju Alfulani, salaye pe ilana fifi posi olowo iyebiye sin oku tako ilana ẹsin Islam.
O ni awọn apẹẹrẹ iwa ti ko ba ilana ẹsin Islam mu yii tawọn ẹbi atawọn afẹnifẹre hu nibi isinku Baba Suwe ni awọn Alfa koro oju si.
Alfa Alfulani tọkasi pe ni ilana ẹsin Islam, ni kete ti oku ba ti mi kanlẹ, ti wọn si ti kede pe o ti jade laye, ni wọn gbọdọ fi iyoku ara rẹ fun ilẹ sin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Lẹ́yìn ti mo lo ọdún 42 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n tú mi sílẹ̀ pé ń kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn"
- Èròngbà ìjọba Naijiria lórí yíyọ 'subsidy' rújú, a kò fara mọ̀-NLC
- Clem Ohameze, òṣèré tíátà ní àìlera, ó ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà lórí iṣẹ́ abẹ
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Ẹ màá múra sílẹ̀ láti ra lítà epo kan ní ₦320 sí ₦340 lọ́dún 2022- NNPC
- Tówẹ́ẹ̀lì ni bàbá mi ró mọ́ ìdí nígbà tí àwọn sọ́jà wọlé mu lọ - Ọmọ Akintunde
- Jàndùkú kọlù mi, gé mi lára bíi olè torí mo jẹ́rìí tako ìjọba níbi ìwádìí ìpànìyàn Endsars Lekki''
- Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
O fikun pe lasiko ti Baba Suwe wa laye, gbajumọ̀ musulumi ni, ti ko si fi aaye gba afẹfẹ-yẹyẹ kan lasiko isinku.
"Ọpọ nnkan ni wọn se nibi eto isinku Baba Suwe to tako ẹsin Islam. Fun apẹrẹ, wọn gbe oku rẹ sinu posi.
Koda awọn afẹnifẹre kan gan fẹ maa gbe oku rẹ jo kiri, ti awọn si sọ pe awọn yoo fi posi sin amọ ti a kọ jalẹ fun wọn nitori pe o tako ilana ẹsin Islam."
Igbesẹ awọn Alfa naa si ni ko dun mọ awọn afẹnifẹre kan ninu amọ nigbẹyin awọn mọlẹbi gba sawọn Alfa naa lẹnu, ti wọn si sin Baba Suwe lai lo posi gẹgẹ bi ẹsin Islam ti laa kalẹ.

















