Afeez Akintunde: Ẹbí alága NURTW tí afurasí sọ́jà gbé nílùú Oyo sọ pé ó ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru

Oríṣun àwòrán, Akintunde Afeez
Iroyin miran tun ti jade nipa awọn oṣiṣẹ alaabo to ṣe e ṣe ko gbe Alaga ẹgbẹ awakọ ero, NURTW, tẹlẹ nilu Oyo, Alhaji Afeez Maruf Akintunde nile rẹ lọsẹ to kọja.
Ṣaaju ni ẹbi Akintunde kàn si BBC pe ni Ọjọru to kọja ni awọn kan to mura bi ọmọ ologun yabo ile rẹ to wa nilu Oyo, ti wọn si gbe e lọ sibi ti ẹbi rẹ ko mọ.
Ninu iroyin ti ileeṣẹ akoroyin jọ Naijiria, NAN, fi sita, ọmọ rẹ, Ọgbẹni Azeez Akbar sọ pe awọn ọmọ ikọ Operation Burst lo gbe baba oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Jàndùkú kọlù mi, gé mi lára bíi olè torí mo jẹ́rìí tako ìjọba níbi ìwádìí ìpànìyàn Endsars Lekki''
- Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
Operation Burst ni ikọ alaabo ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe kalẹ lati maa mojuto eto aabo. Awọn sọja ati awọn oṣiṣẹ alaabo mi si lo wa ninu ikọ̀ naa.
Ọgbẹni Akbar sọ pe ni owurọ kutu ni iṣẹlẹ naa waye. O ni koda, towẹẹli ti baba oun ro mọ idi ni wọn kọkọ fẹ fi maa gbe lọ, ki awọn ẹbi to bẹbẹ pe ki wọn o jẹ ko wọ aṣọ.
"Ileeṣẹ ajọ Operation Burst to wa nilu Oyo ni wọn kọkọ gbe baba oun lọ, ṣugbọn lẹyin iṣẹju diẹ, wọn fi nkan bo o loju, wọn si gbe lọ si ibi ti a ko mọ.
"Nigba to tun di bi aago mọkanla alẹ ọjọ naa, wọn gbe pada wa sile lati mu foonu rẹ. Lati igba naa si ni a ko ti mọ ibi to wa mọ."
O ni awọn ti de ọfiisi Operation Burst nilu Oyo, nibi ti wọn ti sọ fun awọn pe "lati ilu Abuja ni awọn ti gba aṣẹ pe ki awọn ṣeto bi ọwọ yoo ṣe tẹ Alhaji Akintunde".
Bakan naa lo sọ pe baba oun ni aisan ẹjẹ riru, to si ṣeeṣe ki ilera rẹ buru si ti ko ba fi ri oogun rẹ lo tabi jẹ awọn ounjẹ to yẹ.

Afurasí ológun gbé alága NURTW tẹ́lẹ̀ l'Oyo pé ó ń ṣe onígbọ̀wọ́ Sunday Igboho

Awọn afurasi osisẹ ologun kan ti gbe alaga ẹgbẹ awakọ ero NURTW tẹlẹri nilu Ọyọ, Alhaji Afeez Maroof Akintunde lori ẹsun pe o n se onigbọwọ Sunday Igboho ati fifọ ọgba ẹwọn Abolongo.
L'owurọ Ọjọbọ, ọjọ Kejidinlogun osu Kọkanla ọdun 2021 ni awọn agbẹbọn to wọ aṣo ologun yawọ ile gbajugbaja oloṣelu naa.
Akintunde, to tun jẹ alaga tẹlẹri fun ẹgbẹ awakọ, NURTW nilu Ọyọ, ti awọn eeyan mọ si 'Tula Ọyọ', ni awọn ologun gbe lọ lai darukọ ibi ti wọn ti wa tabi ṣe afihan iwe to fun wọn laṣẹ lati gbe igbesẹ naa.
- Bí Buhari bá fi Sunday Igboho sílẹ̀, ìṣọ̀kan yóò padà sí Naijiria - Oluwo
- "Àgbà Yorùbá dalẹ̀ Sunday Igboho, wọ́n fi sílẹ̀ bíi ọmọ òrukàn"
- "Buhari, Sanwo-Olu, ẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí àwọn ọ̀dọ́ tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS"
- Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà ń ṣèdárò Baba Suwe tó jáde láyé
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- "Davido kò ran èmi gbajúmọ̀ lọ́wọ́, ọmọ òrukàn ló fẹ́ kó ₦250 fún"
- Ìjọba fẹ́ pa mí torí àbọ̀ ìwádìí ìkú olùwọ́de EndSARS ní Lekki - Adegboruwa figbe ta
Ọkan lara awọn ọmọ Akintunde to ba BBC Yoruba sọrọ, Alhaji Afeez Akbar ṣe alaye pe, ni nnkan bi i aago meje aabọ owurọ ni iṣẹlẹ naa waye ni ile wọn to n bẹ nilu Ọyọ.
O ni baba oun ro aṣọ mọ idi lasiko to n mura lati wọ ile iwẹ ni awọn afurasi aṣoju ileeṣẹ ologun to di ihamọra ogun naa ya wọle.
O ni kete ti wọn wọle ni wọn nawọ gan Alhaji Akintunde lai se ayẹwo ohunkohun ninu ile naa.
Akbar fi kun ọrọ rẹ pe, lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ti aya Akintunde bẹ, ni wọn to fun ọkọ rẹ lanfani lati wọ aṣọ, ti wọn si gbe lọ.
Idile Akintunde fi idi ọrọ mulẹ pe, gbogbo awọn afurasi ọmọ ologun to yawọ ile naa lo di ihamọra ogun, to fi mọ awakọ to gbe wọn wa.
O ni gbogbo aṣọ ti wọn wọ wa, ni ko si orukọ lara rẹ.
Awọn mọlẹbi Akintunde ni iwadiii ati ọfintoto tawọn se ṣe fi idi rẹ mulẹ pe ilu Abuja ni wọn gbe lọ, ti o si wa ni akata ẹka ileesẹ ologun kan lọwọlọwọ bayii.
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ologun kọkọ jiyan ọrọ naa nigba ti ọkan lara awọn mọlẹbi Alhaji Akintunde pe wọn lori ẹrọ ibanisọrọ.
Akbar ni lara ẹsun ti wọn fi kan ni pe Alhaji Afeez Akintunde wa lara awọn to n ba Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ eeyan n pe ni 'Sunday Igboho ko owo jọ, lati pe fun idasile orilẹede Yoruba.
Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan wi pe Akintunde mọ si bi awọn agbebọn kan ṣe ya wọ ọgba ẹwọn Abolongo nilu Ọyọ lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹẹwa, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn silẹ.
Akbar ṣe alaye siwaju si i pe, baba oun ko mọ ohunkohun nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
O ni lọwọ bayii, baba oun ko ni to ẹgbẹrun mẹwa naira ninu apo asunwọn rẹ. "Nibo lo ti wa fẹ ri owo ṣe onigbọwọ fun Sunday Igboho?".
O fi kun ọrọ rẹ wi pe ijọba lanfani lati ṣe iṣe iwadii ni gbogbo ọna, ki wọn si fi idi otitọ mulẹ.


















