Baba Fryo: Ṣé àìmọkan àbí ìwà ìkà ni Davido ṣe fi èmi gbajúmọ̀ sílẹ̀ lásìkò ìṣòro, tó ń kó owó fún ọmọ òrukàn?

Baba Fryo ati Davido

Oríṣun àwòrán, Instagram/baba fryo/davido

Friday Igwe, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Fryo, tii se akọrin takasufe kan ti sọ pe gbajugbaja akọrin Davido ati awọn akọrin mii pa oun ti lasiko ti oun ni ipenija.

Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ lọjọ Aiku, Baba Fryo sọ pe ko bojumu bi Davido ṣe kede pe oun yoo ko miliọnu lọna ọtalerugba din mẹwaa, 250 million Naira, fun awọn ile itọju awọn ọmọ ti ko ni obi.

Ọsẹ to kọja ni Davido ṣe eto ikowojọ kan lori ayelujara laarin awọn ọrẹ, akẹẹgbẹ ati awọn ololufẹ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Owo to ri kojọ si to miliọnu lọna igba Naira. Lẹyin naa lo kede pe oun naa yoo fi aadọta miliọnu Naira kun owo naa lati pin fun awọn ile ti wọn ti n tọju awọn ọmọ ti ko ni obi jakejado Naijiria.

Baba Fryo sọ pe lasiko ti oun ni ipenija, oun kesi awọn gbajugbaja akọrin bii Davido ati Tuface Idibia, ṣugbọn ko si ẹni to da oun loun fun iranlọwọ.

Àkọlé fídíò, EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé àmọ́ torí ìwọ́de

O ni nkan to panilẹrin ni bi Davido ṣe fẹ fi owo naa tọrọ fun awọn alaini.

"Iyalẹnu lo jẹ fun mi lati gbọ nipa igba miliọnu Naira lori ayelujara. O jẹ nkan to pa mi lẹrin pe, wọn ko ran emi ti mo jẹ gbajumọ lọwọ, ṣugbọn awọn ile itọju awọn ọmọ ti ko lòbí, ti ẹnikẹni ko mọ ri iranlọwọ gba."

O ni oun gba awọn ọmọ Naijiria ati gbogbo alawọ dudu ni imọran pe ki wọn o fi opin si iru iwa bẹẹ.

O ni kii sẹ pe oun ni oore ṣiṣe ko dara, amọ "ibeere mi ni pe ki lo de ti wọn ko ran emi ti mo jẹ gbajumọ, ti awọn eniyan mọ lọwọ?"

Fryo ni oun ko ni ki ẹnikẹni mase bu oun lori ohun ti oun sọ naa, amọ oun ti sọ ohun ti oun fẹ sọ, ipakọ ko si gbọ suti.

Taa ni Baba Fryo?

Friday Igwe ni orukọ abisọ rẹ. O si jẹ gbajugbaja akọrin takasufe lati Ajegule nilu Eko.

Ọkan lara awọn akọrin ti ogo wọn buyọ ni nkan bi ọdun 1990 si 2000 ni Baba Fryo.

O gbajumọ fun orin rẹ "Dem go dey pose", to gbe jade ni nkan bi ọdun 1990.

Akẹẹgbẹ ni Baba Fryo jẹ fun awọn olorin 'Ghetto' miran bii Daddy Fresh ati Daddy Showkey.

Botilẹ jẹ pe Ajegunle lo gbe dagba, ọmọ ipinẹ Delta ni awọn obi rẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ìjọba Buhari ló ní ẹ̀bi, ẹ yé dá ẹ̀bi rú àwọn tó ń bèrè fún 'Yoruba Nation'