Lekki Massacre Panel Reports: - Adegboruwa ní wọn ti ṣá ọmọ ìgbìmọ̀ olùwádìí kan ní ìṣákúṣàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images/BarristerNG
Agbẹjọro to wa lara awọn ọmọ igbimọ to tanna wadi ẹsun isekupani to waye ni Lekki lasiko iwọde EndSARS, Ebun Olu-Adegboruwa ti kigbe sita o.
Adegboruwa yii lo figbe ta pe ete ti n lọ labẹnu lati gba ẹmi oun nitori abọ igbimọ oluwadii naa to ni lootọ ni wọn seku pa awọn oluwọde ni Lekki Toll Gate ni ogunjọ osu kẹwa ọdun 2020.
Atẹjade kan ti Adegboruwa fisita lọjọ Aje lati ke gbajare nipa iku to n rọ dẹdẹ lori rẹ naa, lo pe akori rẹ ni "Ijọba ni kẹ mu ti ohunkohun ba sẹlẹ si mi."
- Nigeria police brutality probe: Ohun tí akọròyìn BBC rí rèé lásìkò ikọlù níbi ìwọ́de Lekki
- Ta ló gé orí ọkùnrin mẹ́ta ní Lekki?
- Buhari, máṣe gbá ìpànìyàn Lekki sórí ààtàn, kò yẹ́ kí ológun yin ọ̀dọ́ níbọn - Bode George
- EndSARS: Atúpalẹ́ rèé lórí ìkọlù tó wáyé ní Lekki Toll Gate lọ́jọ́ 20 Oct, 2020
- A dúro bí iké lẹ́yìn ìròyìn táa gbé jáde nípa Lekki Tollgate; CNN tako Lai Mohammed
- Lẹ́yìn ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí wọn ti Lekki Toll Gate pa, ẹ wo owó gọbọi tíjọba Eko ń pàdánù
Bẹẹ ba gbagbe, igbimọ oluwadii nipa isekupani to waye lasiko iwọde EndSARS ni iloro Lekki naa, lo gbe abọ iwadi rẹ kalẹ laipẹ yii.
Ninu abs iwadi oloju ewe ọọdunrun ati mẹsan naa si lo ti tọkasi pe eeyan mẹsan lo dagbere faye ni iloro Lekki lasiko iwọde EndSARS nigba tawọn ologun ya bo ibi iwọde naa lagunjọ osu Kẹwa ọdun 2020.
Adegboruwa, ẹni to soju awọn ikọ ajafẹtọẹni ninu igbimọ oluwadii ọhun ni se ni awọn osisẹ ọba kan n doju ifiyajẹni kọ awọn ọmọ igbimọ naa.
"Lati igba ta ti gbe abọ iwadi igbimọ naa kalẹ, ọpọ idunkooko mọ ni ati ikọlu ni mo n ri lati ọdọ awọn asoju ijọba, paapaa lawọn oju ewe iwe iroyin.
N ko sẹ ẹsẹ kankan yatọ si pe mo dara pọ mọ awọn eeyan nla lorilẹede yii, ti wsn ko ni abawọn kankan, lati soju ẹgbẹ awọn agbẹjọro ati ajafẹtọẹni pẹlu awọn mẹkunnu fun isẹ ilu.
- "Àgbà Yorùbá dalẹ̀ Sunday Igboho, wọ́n fi sílẹ̀ bíi ọmọ òrukàn"
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
- Àìsàn ‘Dementia’ ló ń bá ọkọ́ mi Olu Jacobs fínra láti ọdún díẹ̀ - Joke Silva
- Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú kí irun pọ̀ lára obìnrin láì ṣe ọkùnrin
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
Gbajumọ agbẹjọro ijọba meji lo si ti ru ọkan araalu soke lati ta ko mi lori mohunmaworan pklu awọn ẹsun ti ko lẹsẹ nlẹ.
Amọ gbogbo igbesẹ yii ni n ko jẹ ko tu irun kankan lara mi tabi gba lati mu ki idunkooko ijsba pa mi lẹnu mọ.
Mo wa n rọ awọn ọmọ Naijiria, awọn akẹẹgbẹ mi lẹnu isẹ agbẹjọro, awọn ajafẹtọẹni atawọn ọmọ Naijiria pe ijọba ni kẹ mu, ti ohunkohun ba sẹlẹ si mi."
Adegboruwa tun fikun pe ni alẹ ọjọ Aiku ni wọn kọlu ọkan lara awọn ọmọ igbimọ oluwadi nipa isekupani to waye ni Lekki naa, Arabinrin Kamsiyochukwu Ibe, ti wọn si sa ni isakusa.
O ni isẹlẹ naa fihan pe wọn mọọmọ fẹ gba ẹmi rẹ ni, ti awọn aworan ti agbẹjọro rẹ si safihan rẹ bii ẹri to daju nipa ikọlu naa, fi idi ero naa mulẹ.
Agba amofin naa ni oun jẹ ipe ijọba lati wa sisẹ sin ilu ni pẹlu otitọ inu pe wsn gbe igbimọ naa kalẹ lati sọ otitọ pọnbele, eyi ti awọn ti se.
O ni iyoku wa ku sọwọ ijọba atawọn ọmọ Naijiria lati se ohun to tọ pẹlu abọ igbimọ oluwadi naa.



















