Timothy Adegoke: Aya onílé ìtura sàlàyé ipò tí ọkọ rẹ̀ wà lórí ẹ̀sùn ìṣekúpani

Rahmon Adedoyin

Oríṣun àwòrán, Ramon Adedoyin/Facebook

Yoruba ni ọrọ okeere, bi ko ba din ọkan, yoo le ọkan ni.

Oniruuru iroyin si lo ti n jade sori ayelujara nipa iku akẹkọọ kan, Timothy Adegoke, to ku sile itura Hilton to wa nilu Ile Ife.

Koda, awọn ọlọpaa ti ko awọn afurasi kan si ahamọ lori isẹlẹ naa, to fi mọ ẹni to ni ile itura naa, Ọmọọba Rahmon Adedoyin.

Ọna lati tan imọlẹ sawọn ahesọ ọrọ naa lo mu ki iyawo Adedoyin kigbe sita lati sẹ ọpọ awọn iroyin ti ko fi ẹsẹ mulẹ, to n jade lori isẹlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo sọrọ lori awọn ẹsun ti ko fifi eniyan se etutu ọla eyi ti wọn n fi kan ọkọ rẹ lori ayelujara, eyi to ni ko ri bẹẹ.

Nigba to n ba iwe iroyin Premium Times sọrọ, aya Adedoyin ni ọmọ Naijiria rere ni ọkọ oun, bẹẹ ni kii lọwọ ninu isẹ ibi rara.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ yé tan ara yín, èmi mo ni aṣọ 100 yard tó jábọ́ lát'ọ̀run táwọn ará Ondo ń ya mọ́ ara wọn lọ́wọ́'

"Ọkọ mi ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ isekupani naa, lootọ ni ọkunrin naa ku sile wa, ti awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii nipa rẹ.

Ọpọ eeyan lo n kigbe kiri pe ọkọ mi ti salọ, eyi ko ri bẹẹ rara, ọkọ mi ko sa lọ sibikibi, awọn ohun to n sẹlẹ yii wa lati dan igbagbọ wa wo lasan ni.

Ohun gbogbo to pamọ, kedere lo han si Ọlọrun ọba amọ mo kọkọ daro pẹlu awọn mọlẹbi oloogbe, mo si mọ pe ọpọ awọn to n tan ayederu iroyin naa ka ni iku alaisi ka lara.

Amọ ju gbogbo rẹ lọ, mo n ba awọn idile ti isẹlẹ naa sẹlẹ si kẹdun iku eeyan wọn to lọ, paapaa iyawo oloogbe."

Bẹẹ ba gbagbe, Timothy Adegoke lo jẹ akẹkọọ to n gboye-koye ni fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife, to si duro sile itura Hilton fun idanwo to fẹ se ni Ife.

Amọ se ni ọkunrin naa di awati, ti wọn si ri oku rẹ lẹyin o rẹyin nibi ti wọn sin si lẹba ile itura ọhun.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'