ILana Omo Oodua: Ẹgbẹ́ IOO jáwé gbélé ẹ fún Otunba Olukoya, fòǹtẹ̀ lu Adeleye àti Akinwande

Igboho pẹlu Baba Akintoye

Oríṣun àwòrán, other

Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua to n beere fun idasilẹ orilẹede iran Yoruba ti salaye nipa awọn ohun to fa awuyewuye to n waye ninu ẹgbẹ naa.

Ninu atẹ́jade kan ti ẹgbẹ naa fi sọwọ si BBC Yoruba, o ni oun ti ja ewe gbele ẹ fun Otunba Folasade Olukoya, tii se ọkan lara awọn asoju rẹ ninu ẹgbẹ ajijagbara fun iyapa Naijiria lapapọ, NINAS.

Bakan naa ni ẹgbẹ ọhun tun ṣalaye ninu atẹjade naa pe, Ọgbẹni Maxwell Adeleye ati Dokita Kayode Akinwande yoo si maa tẹsiwaju pẹlu ipo wọn lati ṣoju Ilana Omo Oodua ninu ẹgbẹ NINAS.

Ọjọgbọn Banji Akintoye to jẹ aarẹ Ilana Omo Oodua ni alaga ẹgbẹ NINAS ni Naijiria.

Ṣaaju ni Ọgbẹni Tony Nnadi, Esq to jẹ akọwe ẹgbẹ ajijagbara LNC (Lower Niger Congress) sọ pe Ọgbẹni Adeleye ko si lara awọn aṣoju ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ni NINAS mọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ìjọba Buhari ló ní ẹ̀bi, ẹ yé dá ẹ̀bi rú àwọn tó ń bèrè fún 'Yoruba Nation'

Ṣugbọn ẹgbẹ naa daa pada pe ko si ohun to jọ bẹẹ, ati pe awada kẹri kẹri ni ọrọ naa.

Wọn Ọgbẹni Adeleye si ni agbẹnusọ Ọjọgbọn Akintoye ati fun ẹgbẹ Ilana Omo Oodua.

Amọ, ẹgbẹ IOU ṣalaye ninu atẹjade ti wọn sita pe Otunba Olukoya kii ṣe aṣoju awọn mọ ninu ẹgbẹ NINAS nitori o ti fi ẹgbẹ naa silẹ.

Wọn rọ awọn ẹgbẹ ajijagbara mii lati mọ bayii pe Otunba Olukoya kii ṣe aṣoju ẹgbẹ OOU mọ.

''A n fi akoko yii sọ fawọn eeyan pe Ọgbẹ Nnadi ko le maa la le wa lọwọ ninu ẹgbẹ IOU.

A rọ Ọgbẹni Nnadi lati gbaju mọ ohun ti o ka an, ki o ye sọrọ gẹgẹ bi alatako iran Yoruba.

Akojọpọ ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede tuntun ni ẹgbẹ NINAS jẹ, kii ṣe Nnadi lo ni ẹgbẹ naa.

Lakotan, a fi ọntẹ lu Ọgbẹni Adeleye ati Dokita Akinwande gẹgẹ bi aṣoju wa nitori wọn fihan pe ọmọ Yoruba atata ni wọn jẹ.

A o maa kede ẹni ti yoo rọpa Olukoya gẹgẹ bi ọkan lara aṣoju mẹta ti a ni ninu ẹgbẹ NINAS,'' ẹgbẹ IOU lo ṣalaye bẹẹ.

Ogun ọmọ ẹgbẹ IOU to fi mọ Ọjọgbọn Akintoye gan an lo buwọlu atẹjade naa.

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀