Attack on Akintoye house: Ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá ní kí Buhari yé dúnkokò mọ́ Igboho, Akintoye àti Kanu

Agbarijọpọ ẹgbẹ ọmọ Yoruba to n pe fun iyapa iran Yoruba lara Naijiria, ti kilọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko jawọ lọrọ Sunday Igboho, Nnamdi Kanu ati Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti wọn n pe fun iyapa lara orilẹ-ede Naijiria.
Ẹgbẹ Yoruba ni didunkoko mọ awọn mẹtẹẹta ko ni fopin si ipe fun iyapa lara orilẹ-ede Naijiria.
Ẹgbẹ naa fi idi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ ọhun, Ọmọwe Steve Abioye fi sita.
Ẹgbẹ agbarijọpọ ọmọ Yoruba to n pe fun iyapa naa wa fi aidunnu rẹ han si ikọlu tawọn agbebọn ṣe si ile Ọjọgbọn Akintoye niluu Ado-Ekiti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Ẹ̀kùn Àríwá pahùndà, ó fẹ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà míì láti yan ààrẹ
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
- Ọwọ́ tẹ oníṣègùn níbi tó ti ń sin ọmọ tuntun láàyè pẹ̀lú ọfọ̀ àti àyájọ́
- Tinubu, àtúntò Nàíjíríà ni ko wá ná, ko tó du ipò ààrẹ - Pa Adebanjo
- Ọta ìbọn ń já bọ́ láti òrùlé ilé Banji Akintoye
- "Bí ọmọ rẹ kò bá gba First Class ní fásitì Ibadan, máṣe yọjú fún ayẹyẹ ìkẹkọọjáde"
Ẹgbẹ naa ni "ẹni iyi ni Ọjọgbọn Akintoye jẹ, o si ti kopa ribiribi ninu idasoke awujọ, ilẹ Yoruba ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ ki o bẹrẹ si ni fun iyapa iran Yoruba lara Naijiria.
Akintoye bẹrẹ si ni pe fun iyapa lara Naijiria lẹyin ti awọn eeyan apa ariwa Naijiria ko faramọ atunto iṣejọba Naijiria.
Fun idi eyi, a n kepe ijọba apapọ lati ṣe iwadii ikọlu si kọ ile Ọjọgbọn Akintoye niluu Ado-Ekiti ati pe ki ijọba fi awọn ọdaran to ṣiṣẹ ibi jofin.
Eyi ni yoo jẹ k'awọn ọmọ Naijiria le mọ pe ijọba ko lo wa nidi ọrọ naa.
Ohun kan to le mu opin ba ipe fun iyapa lara Naijiria ni ki Buhari ṣeto lati da Naijiria pada si iwe ofin ilẹ wa ọdun 1966 to fun ẹkun kọọkan lagbara lati da wa.
Ọna miran ni pe ijọba Buhari ni lati ṣe agbeyẹwo abọ apero ọmọ Naijiria to waye lasiko ijọba Aarẹ ana, Goodluck Jonathan.
Ijọba Buhari gbọdọ mọ pe igbesẹ lati pa Igboho, Kanu ati Ọjọgbọn Akintoye kọ ni ọna lati dẹkun ipe fun iyapa lara orilẹ-ede Naijiria.
Koda, awọn eeyan mii yoo tun dide yatọ sí Igboho, Kanu ati Akintoye ayafi ti ijọba ba gba lati ṣe atunto Naijiria loku."

Ọta ìbọn ń já bọ́ láti òrùlé ilé Banji Akintoye

Ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Ekiti lo ti mu ike ọta ibọn AK47 ti wọn ri nile adari ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye, lẹyin ti awọn agbebọn ti a ko mọ ẹyẹ to ṣu wọn, ṣabẹwo si ile rẹ ni Satide to kọja.
Ọlọdẹ to n ṣọ ile naa, Mudasiru Olanrewaju, sọ fun BBC News Yoruba nilu Ado Ekiti pe awọn ọlọpa lo mu ọta naa lakoko ti wọn ṣe abẹwo si ile naa lẹyin awuyewuye to waye lori iṣẹlẹ ọun.
Olanrewaju ṣalaye pe awọn agbebọn ti oun ko ri ṣabẹwo si ile alagba Banji Akintoye, ẹni to ti le ni ọgọrin ọdun, to wa lagbegbe Similoluwa nilu Ado Ekiti, ni aago mẹfa kọja iṣẹju diẹ laarọ ọjọ Satide.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari ti já kulẹ bí ìbò Anambra bá forí ṣánpọn - Onímọ òṣèlú
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ó fi sísọ́ọ̀sì gún aya rẹ̀ pa
- Ìjọba Ethiopia figbe ta pe ogun ń bọ, ó kéde ìlú kò fara rọ
- Mọ̀ sì nípa Femi Osibona tó ni ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi
- Àsìta ìbọn bá àkẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan, bí ọ̀rọ̀ ṣe wáyé rèé
- Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
- Ọwọ́ Amotekun tẹ ọ̀dọ́ 18 tó rìn gbéregbère wọ Akure láti òkè ọya
- Ó di dandan kí a wa iṣu dé ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí ó wó ní Ikoyi-Tinubu
- Ọ̀gá báńkì rẹ́wọ̀n he torí ó fi N219m owó oníbàárà kọ́ ilé, ra ilẹ̀
- Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
O ni awọn janduju naa lo da ibọn bo orule ati ogiri yara oun to wa lẹgbẹ fẹnsi ile naa, nibiti wọn gba wọ inu ọgba.
O ni oun ko ri ẹnikẹni nigba ti ohun jade amọ oun ri ike ọta ibọn nilẹ ati tabili kan ti o bajẹ lẹyin wakati diẹ tohun fẹẹ lo wẹ
O wipe lọgan lohun fi iṣẹlẹ naa to olori alaabo adugbo naa, Omotayo Olatunji, leti to si pe awọn ọlọpa.
Olanrewaju fikun pe awọn ọlọpa wa lọjọ naa ti wọn si tun pada wa lọjọru, ti wọn fi gba ike ọta ibọn naa lọ.
Ọga awọn ẹṣọ agbegbe ọhun, Olatunji, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ wipe igba akọkọ niyi ti irufẹ iṣẹlẹ naa yoo ṣẹ ni agbeegbe naa.
O fikun pe awọn agbaagba lagbegbe naa ti forikori lori bi eto aabo yoo ṣe nipọn sii lagbeegbe naa.
Alakoso fun ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua nipinlẹ Ekiti, Alufa Praise Ayodele wa bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu naa, o si rọ ileesẹ ọlọpa lati tu iṣu ọrọ naa de isalẹ ikoko.

Ọlọpaa ni isẹlẹ ile Akintoye kii se ikọlu:
Alukoro fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, ni iṣẹlẹ ọhun ni awọn akọroyin ti pariwo rẹ ju bo ṣe yẹ lọ tori pe kii ṣe ikọlu bi wọn ṣe wi.
Abutu ṣee lalaye pe ileesẹ ọlọpa ti mu ike ọta ibọn ti wọn ri nibẹ fun ayẹwo to peye lati le ṣiṣọ loju eegun ọrọ naa.
Bo tilẹ jẹ pe oju ọta ṣi wa lara ile alagba Akintoye ti a ko si tii mọ awọn to ṣe iṣẹ naa, alaafia lo ti pada jọba lagbegbe ọun.

Àwọn agbébọn kọlu ilé adarí Ilana Omo Oodua Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye l'Ado-Ekiti

Oríṣun àwòrán, Banji Akintoye
Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua to n pe fun iyapa orile-ede Yoruba lara Naijiria ti kede pe awọn agbebọn kan kọlu ile adari ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Banji Akintoye to wa niluu Ado-Ekiti.
Alukoro ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe ọjọ Abamẹta, Ọgbọnjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2021 ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Adeleye sọ pe awọn agbebọn naa gun ori aga to wa ni iwaju ile Akintoye ti wọn sì bẹrẹ sí ní yinbọn mọ geeti ile naa.
- Nàìjíríà kò fararọ fún ẹ̀yà Yorùbá, Buhari ń dọdẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi - Akintoye
- Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation ló ń tan aráàlú jẹ láì sọ òtítọ́ - Seyi Makinde
- Oyinlola kí Arapaja kú orííre bó ṣe borí ìbò igbákejì alága PDP fún ẹkùn Gúúsù
- Ta ni Ọjọgbọn Adebanji Akintoye tó borí Tinubu láti di olórí àwọn Yoruba?
- Sé lóòtọ́ ni wọ́n ti fi Sunday Igboho sílẹ̀ ní Cotonou?
Amọ, Ọjọgbọn Akintoye ko sì nile lasiko ikọlu naa ko sí si ẹni tó farapa nibi iṣẹlẹ ọhun.
Alukoro ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ni ọta ibọn ti o ṣeeṣe ki o jẹ AK-47 wa nilẹ ninu ile Ọjọgbọn Akintoye.

Oríṣun àwòrán, ẹgbẹ Ilana Omo Oodua
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Ọmọbibi ilu Ado-Ekiti ni Akintoye n ṣe.
Ọjọgbọn Akintoye ṣoju ipinlẹ Ondo atijọ gẹgẹ bí sẹnẹtọ laarin ọdun 1979 sí 1983 nigba ijọba Ààrẹ Shehu Shagari.
Akintoye lo n ṣe agbatẹru ipe fún iyapa iran Yoruba kuro lara Naijiria.





















