Yoruba World Congress: Banji Akintoye ní àwọn ọlọ́pàá fẹ́ sọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òun sá àhámọ́

Oríṣun àwòrán, others
Ọjọgbọn Banji Akintoye to jẹ aṣiwaju igbimọ Yoruba lagbaye, Yoruba World Congress, ti salaye pe Naijiria ko fararọ fun ẹya Yoruba.
Ọjọgbọn Akintoye ni igbimọ Yoruba lagbaye, Yoruba World Congress gba alaafia laaye ninu iṣe rẹ gbogbo, ti ko si fa ijangbọn kẹsẹ rara.
Amọ o ni sibẹ aarẹ Muhammadu Buhari ṣi n lepa lati yọ orukọ igbimọ naa kuro lara awọn ẹgbẹjẹgbẹ to forukọ silẹ labẹ ijọba.
Bakan naa lo fi kun un pe, awọn agbofinro pẹlu ti n gbaradi lati bẹrẹ sifi panpẹ ọba gbe awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
Ninu ọrọ to sọ nibi ayẹyẹ ipade igbimọ awọn ẹya ti ko ni aṣoju ninu igbimọ agbaye, aṣiwaju igbimọ Yoruba lagbaye naa sọ pe ohun ti oju ẹya Yoruba n ri nilẹ yii ko dẹrun rara.
O ni awọn oyinbo amunisin Gẹẹsi, pẹlu ibẹru pe ẹya to kawe gidi ni ẹya Yoruba, wọn si sa gbogbo ipa nigba naa lati tẹri rẹ ba.
O fi kun n pe, ọṣẹ pupọ ni ijọba ologun gbogbo to wa ni ṣisẹ n tẹle, tun ṣe fun ẹya Yoruba nigba ti wọn gbẹsẹ le gbogbo dukia ajumọni ilẹ Yoruba.
O fikun pe igbesẹ naa jẹ gbogbo eleyi ti wọn ti gbe kalẹ bẹrẹ lati ọdun 1959, pupọ awọn dukia ajumọni ti wọn gbẹsẹ le naa ni wọn ko mojuto daradara, ti ọpọ si tun ti parun.
Akintoye ṣalaye fun ipade apapọ igbimọ agbaye naa pe, aisi aabo to peye, ti mu ki awọn iwa ipa bii ijinigbe, ikọlu awọn agbebọn, ikọlu laarin agbẹ ati darandaran ati bẹẹ bẹẹ lọ, di tọrọ fọnkale nilẹ Yoruba.
O wa fi kun pe, pẹlu bi ọrọ ti ṣe ri yii, ijijagbara ẹya Yoruba ti n debi to lapẹrẹ.














