Insecurity: Buhari ní ẹ̀ka aláàbò Nàíjíríà tiraka àmọ́ ó yẹ kí wọn ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kede pe awọn ọms Naijiria funra wọn mọ pe ijsba oun ti sa ipa rẹ lati gbogun ti aifararọ eto aabo.
Aarẹ Buhari kede bẹẹ lasiko to n bawọn akọroyin ile ijọba sọrọ nile ijọba Aso Rock nilu Abuja lati sami ọdun Ileya.
Amọ aarẹ wa fi aidunnu rẹ han lori isesi awọn asaaju ikọ alaabo wa, o ni o yẹ ki wọn se aseyọri ju bayii lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èlé orí owóyàá China rọjú la ṣe fẹ́ gbà á - Ìjọba àpapọ̀
- N kò ri ipa ẹ̀jẹ̀ lára ọmọ mi tó kú sí iléeṣẹ́ ọṣẹ, èjò lọ́wọ́ nínú - Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ UI
- Mò máa ń fọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ìyá mi, ni ìṣe àwọn obìnrin fi wù mí - Bobrisky
- Àlàyé rèé lóríi àjọṣepọ̀ tó wà láàrin èmi àti MC Oluomo - Ronke Oshodi Oke
- Ẹ bá mi wá nọ́ńbà ìpè òbí ọmọ Mummy Calm Down jáde - Yinka Ayefele
- Ọlọ́pàá sálọ fún aráàlú l‘Okeho, nígbà tí wọn yari láti ṣun olè méjì tó kù
"Mo fẹ kawọn ọmọ Naijiria mọ daadaa nipa orilẹede wọn ati awọn ohun ta ba nilẹ lọdun 2015.
Eyi tii se ikọlu Boko Haram ni ẹkun ariwa ati tawọn ajijagbara lẹkun aarin gbungbun guusu Naijiria.
O si da mi loju pe awọn ọmọ Naijiria gan mọ pe mo ti gbiyanju lati se ohun ti agbara mi ka lori wọn."
"Awọn ohun to n sẹlẹ lẹkun iwọ oorun ati aarin gbungbun ariwa Naijiria n ba ni ninu jẹ pupọ.

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Amọ mo si nigbagbọ ninu awọn osisẹ ologun, ọlọpaa atawọn osisẹ agbofinro yoku lati ipasẹ abọ ti wọn n jẹ fun mi, sugbọn mo ro pe o yẹ ki wọn si lee se ju bayii lọ."
Bakan naa ni agbẹnusọ fun aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu, fi atẹjade kan sita lọjọ ọdun Ileya.
- Kí ìjọ mi ní Sagamu le gbòòrò ni mo fi ń ṣiṣẹ́ ajínigbé pawó - Pásítọ̀
- Àwa àti fijilanté pẹ̀lú ọdẹ́ ìbílẹ̀ ló dojú kọ adigunjalè ní First Bank Okeho - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ìtàn ọba Yorùbá tí wọn yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ Mùsùlùmí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́
- "Ọmọ mi kò tíì mọ̀ pé òun ti di ìlúmọ̀ọ́ká, ó ń wádìí bó ṣe ń rí ara rẹ̀ lórí ayélujára"
- Boko Haram da ìbọn bo ọkọ̀ gómìnà Borno, ẹ̀ṣọ́ àláàbò rẹ̀ farapa
O ni aarẹ Buhari ti fọwọ sọya fawọn ileesẹ alaabo pe oun yoo pese awọn ohun eelo to yẹ fun wọn lati lee koju aifararọ eto aabo nibikibi lorilẹede Naijiria.
Ẹ yìnbọn pa ọ̀daràn tí ẹ bá rí níbi kíbi, Buhari pàṣẹ fáwọn ológun

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Presidency
Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fawọn ologun pe ki wọn yinbọn pa ọdọran kọdaran to ba n ṣagbatẹru rogbodiyan tabi ikọlu kaakiri orilẹede Naijiria.
Aarẹ ni o ba oun lọkan jẹ bi awọn janduku ti n pawọn alaiṣẹ ati bi wọn ti n sọ ọpọ di alaabọ ara ti wọn si n tun n jawọn lole.
Aarẹ Buhari fọrọ yii lede nibi ti o ti n bawọn ọmọ ologun 17th Brigedi atawọn ọmọogun ofurufu 213 Operational Base niluu Katsina lọjọ Abamẹta.
- Ike Ekweremadu, igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tẹ́lẹ́ rí èèmọ̀ he nilùú Germany!
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Fayemi fojú Alufa to fipa bá ọmọde lòpọ̀ síta l'Ekiti
- Aṣírí ìdí ti El-Zakzaky fi padà Nàìjíríà láti India
- 'Àlàyé rèé lórí ìdí ti mo fi na ọmọ òrukàn, tí mo sì tì í mọ́ ilé ajá'
- Wo orílẹ́èdè tí wọ́n tí ń dáwó ìsìnkú ara wọn pámọ́
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
Buhari rọ awọn ologun naa ti wọn pe ọrukọ wọn ni "Operation Hadarin Daji," lati ṣiṣẹ eto aabo ti ijọba gbe fun wọn takuntakun.
Aarẹ ni ijọba ''da ẹgbẹ ọmọogun yii silẹ lati daabo bo apa iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria lọwọ awọn janduku ti wọn da ilu ru kiri, ati pe iṣẹ wọn ni lati daabo bo orilẹede Naijiria lapaapọ.''
Aarẹ sọ pe oun gẹgẹ bi olori ileeṣẹ ologun Naijiria ''gbagbọ pe awọn ọmọogun koju oṣuwọn lati ṣiṣẹ ti ijọba gbe fun wọn,'' bakan naa ni aarẹ paṣẹ fun wọn pe ki ''wọn o wa awọn ọdanran to n da rogbodiyan silẹ lọ sibi kibi ti wọn ba n farapamọ si, ki wọn si mu wọn kuro nilẹ.''
Buhari ni o to gẹ bayii nitori Naijiria pe alaafia gbọdọ jọba lorilẹede Naijiria.
Aarẹ Buhari ṣeleri pe ijọba ṣetan lati pese ohun elo ijagun ti wọn nilo lati ṣiṣẹ to wa lọwọ wọn.
Lọjọ Abamẹta yii naa ni Aarẹ Buhari pada siluu Abuja lẹyin isinmi ọdun Sallah to lọ ṣe niluu rẹ Daura lati ọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ.












