Nothern Elders Forum: Ẹ wo ọ̀pọ̀ ohun tí ẹ̀kùn Àríwá ń fẹ́ àtúnṣe rẹ̀ nínú òfin ilẹ̀ wa

Oríṣun àwòrán, Hakeem Baba-Ahmed
Ẹgbẹ awọn agbaagba ni Ariwa Naijiria ti sọ pe ẹkùn naa yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹ̀yà to ku ni Naijiria lati yan adari to koju òṣùwọ̀n.
Ẹgbẹ naa sọ eyi gẹgẹ bi erongba tuntun lori ìpinnu rẹ pe Ariwa ni Aarẹ yoo ti wa lọdun 2023.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Ọmọwe Hakeem Baba-Ahmad, lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade to fi sita lẹyin ipade ti adari wọn, Ọjọgbọn Ango Abdullahi pè.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọn tí rí òkú Femi Osibona yọ kúrò nínú ilé tó wó ní Ikoyi
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
- Ọwọ́ tẹ oníṣègùn níbi tó ti ń sin ọmọ tuntun láàyè pẹ̀lú ọfọ̀ àti àyájọ́
- Tinubu, àtúntò Nàíjíríà ni ko wá ná, ko tó du ipò ààrẹ - Pa Adebanjo
- Ọta ìbọn ń já bọ́ láti òrùlé ilé Banji Akintoye
- "Bí ọmọ rẹ kò bá gba First Class ní fásitì Ibadan, máṣe yọjú fún ayẹyẹ ìkẹkọọjáde"
O sọ ninu atẹjade naa pe lara ohun ti wọn tun sọ nibi ipade naa ni pe, wọn fi ẹnu kò pe ki wọn wọgile awọn ajọ eleto idibo ni ipinlẹ ninu atunse ofin to n lọ lọwọ.
O ni awọn eniyan Ariwa fẹ ẹ sisẹ pọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria to kù, lati yan adari to kun oju òṣùwọ̀n, ti yoo si da ẹ̀mí igbagbọ ati ireti nipa ọjọ ọ̀la pada si ọkàn araalu.
Ẹgbẹ NEF sọ pe anfaani pupọ ni yoo jẹ fun awọn ọmọ Naijiria, ti awọn ẹgbẹ́ oṣelu miran ba wà, yatọ si PDP ati APC.
Bakan naa lo sọ pe asiko ti to fun ijọba, lati fi opin si awọn ajọ eleto idibo ni ipinlẹ, ki INEC si ma a ṣe ojúṣe wọn.
Wọn ni lootọ ni awọn naa korò oju si iṣẹ Boko Haram ni Ila Oorun Ariwa, sugbọn nkan to le mu ki awọn faramọ ki ijọba sapejuwe àwọn agbebọn naa ni agbesunmọmi, ni ti yoo ba mu ayipada rere ba eto aabo to mẹhẹ.

















