Salawa Abeni: Mi ò mọ̀ pé mo lè di ọgọ́ta ọdún láyé pẹlú àìlera mi

Salawa Abeni n se omije lọjọ nibi ayyẹ ọjọ ibi rẹ

Oríṣun àwòrán, officialsalawaabeni/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹni ọdun ba laye, o yẹ ko ṣọpẹ fún Eleduwa fun idasi ati abo rẹ.

Eyi gan an ló jẹ ki gbajugbaja Olorin Waka, Queen Salawa Abeni dupẹ lọwọ Ọba Oke to da a sì di ẹni ọgọta ọdun loke eepẹ.

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2021 yii ni awọn Salawa dawọọ ọjọ ibi ọgọta ọdun fun ùn ni ile itura Oriental niluu Eko eleyii ti ko mọ nipa rẹ titi di ọjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Salawa Abeni, lasiko to n ba iwe iroyin City People sọrọ, o ni sọ pe o ku diẹ ki oun daku lẹyin ti oun ri ero biba ninu gbọngan tawọn ọmọ rẹ ti ṣeto kalẹ ni ile itura naa nibi ti alejo to to ẹẹdẹgbẹrin ti joko.

"Ti ko ba jẹ pe awọn kan dì mi mu lapa ọtun ati osi ni, ko si ọgbọn rẹ, n ko ba daku.

Àkọlé fídíò, Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53

Mí o le gbagbọ ohun ti mo ri, mi o lero pe awọn ọmọ mi le ṣe iru nkan bayii ti n ko sí ni mọ.

Ọrọ naa dabi iditẹ gbajoba awọn ologun ni, ọpọ to sun mọ mi lo mọ nipa rẹ ṣugbọn wọn ko sọ fun mi.

Àmọ́, inu mi dun, ayọ mi kun, mi o tiẹ le ṣalaye bi inu ṣe dun to lọjọ naa.

Ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ati gbogbo eeyan to gbimọ pọ pẹlú awọn ọmọ mi lati ṣe ayẹyẹ yii fún mi.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Mí o mọ pe awọn eeyan si tun ni ifẹ mi bayii.

Iyalẹnu nla lo jẹ fun mi nigba ti ọmọbinrin mi n ṣalaye awọn to fi owo ranṣẹ sí oun fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun mi.

O sọ fun mi pe lori foonu mi loun ti ri nọmba ọpọ ọrẹ mi ti oun sí bẹrẹ sí ni mura fun ayẹyẹ naa," Salawa lo sọ bẹẹ.

Queen Salawa ni "lasiko awẹ Ramadan loṣu karun ùn gan an ni ọjọ ibi mi ti mo pe ọgọta ọdun laye.

Amọ, mi o le ṣe ayẹyẹ naa tori awẹ to wà nita.

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

Ṣugbọn lati aago mejila oru ọjọ ti mo pe ọgọta ọdun yìí ni mo yi nilẹ titi di aago mẹrin aarọ ti mo n dupẹ lọwọ Ọlọrun.

Mí o mọ pe mo lè di ọgọta ọdun laye pẹlu gbogbo nkan ti mo ti la kọja laye."

Lori bo ya o si maa tẹsiwaju ninu orin kikọ lẹyin to pe ọgọta ọdun laye, Salawa ni oun si maa kọ ọrin lọ ni o.

O ni niwọn igba to jẹ pe awọn agbaagba ninu iṣẹ orin kikọ bi Ebenezer Obey, King Sunny Ade ati Alhaji Kollington Ayinla ko tii fẹyin ti ninu orin kikọ.

"Mo mọ ibi ti ori n gbe mi lọ, mo sí mọ pe Eledumare maa mu mi de ibẹ.

Ẹnikẹni to ba maa dé ibi gíga laye, waa ni ipenija iṣubu ṣugbọn wa a tun dide pada.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Bi ọrọ mi ṣe rí niyẹn, eyi dẹ ni mo gbagbọ pẹlu ọrọ aye mi," Queen Salawa lo ṣalaye bẹẹ.