Ani Chukwuemeka: Mo ṣe fídíò láti tọrọ owó tórí àìsàn ìtọ̀ ṣúgà tó fa egbo tí kò jinná ní ìdí mi

Ani Chukwuemeka ati miliọnu mẹfa naira to gba

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Oṣere tiata kan, Ani Chukwuemeka ti ri ẹ̀bùn miliọnu mẹfa Naira gba lati fi ṣe itọju ara rẹ.

O ti to asiko diẹ ti oserekunrin naa ti wa ni idubulẹ aisan, ko to o di pe Woli Jeremiah Fufeyin, fun ni owo naa ni ọjọ Aiku to kọja.

Fido kan ti wolii naa gbe soju opo Facebook rẹ lo se afihan igbesẹ naa, to si tun fun aya Ani ati ẹni to sin wa wa ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ẹnikọkan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Chukwuemeka, nigba to n fi idunnu rẹ han lori ẹ̀bùn owo naa sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun.

O ṣalaye pe lọdun 2020 ni eto ilera oun dẹnu kọlẹ, ti wọn si ṣe iṣẹ abẹ lori egbò kan to wa ni ìdí oun nilu Owerri.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Aide: Omiyale ni DSS rọ̀jọ̀ ibọn sí Igboho, wọ́n wá pa ni àmọ́ ó bọ́

Sugbọn, nkan túbọ̀ n buru si ni, nitori pe aisan itọ ṣuga to n ṣe e, se akoba pupọ fun iwosan egbo naa.

Eyi si lo mu ko ṣe fidio kan to fi si ori ayelujara lati tọrọ owo lọwọ awọn eniyan.

Ninu fidio naa, Chukwuemeka sọ pe oju oun ti fẹ ẹ fọ́ nitori kokoro 'cataract' to ti wọ inu oju kan.

Bakan naa lo ni awọn aisan to n ṣe oun ti mu ki oun ni aisan rọpa-rọsẹ, stroke.

O wa dupẹ lọwọ wolii naa fun oju aanu to si wo ati ọwọ ọrẹ to na si ọhun.

Fidio naa ni Woli Fufeyin ri, to si pe oṣere naa si ile ijọsin rẹ lati fun lowo fun itọju ara rẹ.

Igba akọkọ kọ niyi ti Woli naa fun oṣere to n ṣàìsàn ni owo.

Ani Chukwuemeka ati miliọnu mẹfa naira to gba

Oríṣun àwòrán, AFP