Anambra 2021 Election: Buhari pàṣẹ fáwọn ọ̀gá ológún láti rí pe ìbò gómìnà wáyé

Oríṣun àwòrán, Eze Kenneth Okereke
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ṣeleri pe ko si ẹni to le da eto ijọba tiwantiwa duro lorilẹede yii.
Eyi ko ṣeyin bi ikọ to n pe fun ominira ilẹ Biafra, IPOB ṣe ni ko ni si eto idibo sipo gomina nipinlẹ Anambra, eleyii to yẹ ko waye ni Ọjọ Kẹfa, Osu Kọkanla, ọdun 2021.
IPOB ni awọn yoo paṣẹ ofin konile o gbele fun ọjọ mẹfa, ti ijọba Naijiria ko ba fi adari wọn Nnamdi Kanu silẹ ki Ọjọ Kẹrin, Osu Kọkanla, ọdun 2021 to pe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Omi inú ọ̀rá ní mo lọ rà, tí orí ṣe yọ mí níbi ilé tó dà wó - Ọlọ́pàá
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ló mú kí ìjọba gbógun ti orísùn ọrọ̀ ajé mi - Yomi Fabiyi figbe ta
- EFCC gbé bàbá olówó Obi Cubana
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
- Bá wo ní ilé alájà 21 ṣe wó ní Ikòyí? Ẹ ṣèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní kíákíá - Sanwo-Olu yarí
- Èèyàn tó há sí abẹ́ ilé tó wó kò sí ẹni tó lè sọ ṣùgbọ́n òkú mẹ́rin là ri-Ọlópàá
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ìyà tó ń jẹ Ife lórí òpópónà tó bàjẹ́ kò tọ́, Buhari, Oyetola, ẹ wá nǹkan ṣe sí - Ooni
Amọ ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Anambra ti ni ko si ọrọ ninu idunkoko ikọ IPOB nitori ko si ẹnikẹni to le da idbo naa duro ninu oṣu kejila.
Bakan naa ni ileeṣẹ to n risi eto aabo lorilẹede Naijitia ni Aarẹ Buhari ti paṣẹ fun wọn lati pese aabo to rinlẹ ni gbogbo agbegbe ipinlẹ Anambra.
''Aarẹ Buhari ti paṣẹ pe ko gbọdọ si ẹnikẹni ti yoo da idibo naa duro bi IPOB tilẹ dunkoko ju bẹẹ lọ
A ko ni gba ẹgbẹ tabi ẹnikẹni laaye lati da omi alaafia ilu ru, eleyii to ti jasi iku ọpọlọpọ eniyan ni ẹkun naa.
Aarẹ ti paṣẹ pe ki ikọ ọmọogun Naijiria ati gbogbo awọn ẹṣọ agbofinro ri daju pe idibo naa ko yẹṣẹ, ki wọn si kun gbogbo agbegbe naa.''
Bakan naa ni aarẹ Buhari ni awọn agbebọn ti wọn n da ẹkun ariwa ru yoo ri ọwọ ijọba laipẹ nitori wahala ni yoo jẹ fun wọn.
Buhari ni awọn agbebọn ko ni ri ibi salọ nitori gbogbo agbegbe ati kọrọ ti wọn n fori pamọ si ni awọn yoo gbakoso rẹ.
O fikun pe awọn agbebọn naa yoo foju wina ofin fun gbogbo ipaniyan ati aibalẹ ọkan ti wọn fun awọn eniyan ni agbegbe naa.


















