Sunday Igboho Aide: Omiyale ni DSS rọ̀jọ̀ ibọn sí Igboho, wọ́n wá pa á ni, àmọ́ ó bọ́ lọ́wọ́ wọn

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Aide: Omiyale ni DSS rọ̀jọ̀ ibọn sí Igboho, wọ́n wá pa ni àmọ́ ó bọ́

Yoruba ni ẹni to yẹ ki iku pa amọ to ba si ni fila, o yẹ ko maa dupẹ ni.

Idi ree ti ọkan lara awọn alatẹle Sunday Igboho, Ọmọọba Onaolapo Ademola Omiyale fi n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹmi rẹ ko bọ lọjọ tawọn osisẹ DSS ya bo ile Sunday Igboho.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Kinni, osu Keje ọdun 2021 ni awọn DSS kọlu ile Igboho to wa ni adugbo Soka nilu Ibadan ni deede aago kan abọ oru, ti wọn si ko awọn eeyan, ba ọpọ dukia jẹ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti oju rẹ ri lọjọ naa ati ni ahamọ DSS, Omiyale ni bawọn agbofinro naa se de, ni oun ti ransẹ si iya oun pe ko fi asọ funfun sin oun.

O fikun pe oun ti n ke keu to jẹ mọ ti oku pẹlu ireti pe opin yoo de ba ẹmi oun ni alẹ ọjọ naa.

Omiyale ni awọn DSS foju kan Sunday Igboho lọjọ naa, ti wsn si da ọpọ ọta ibọn bo o amọ akọni ọmọ Yoruba nii se.

O ni awọn DSS mọọmọ wa pa Igboho lọjọ naa ni, o si yẹ ko ku amọ o papa bọ mọ wọn lọwọ.

Nigba to n salaye ohun ti oju rẹ ri ni ahamọ DSS ki wọn to gba oniduro wọn, Omiyale ni irẹsi ti ko jinna, lai si iyọ tabi ata ni awọn n jẹ.

O tun ni ọbẹ dudu to da bii ọili mọto ni wọn fi n se ọbẹ ti awọn n jẹ, bẹẹ ni otutu ikọlu DSS naa ko si ti kuro ni ara oun rara.