Sunday Igboho: Alhaji Fatai ti kò ríràn ní ìbọn bà níbí tó ti ń wá ọ̀nà kiri láti sá pamọ́

Alhaji Fatai ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Yoruba ni asegbe kankan ko si, asepamọ lo wa.

Idi ree ti asiri se tu nipa eeyan meji to jade laye lasiko ti awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS se ikọlu sile asaaju ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ta tun mọ si Igboho.

Agbẹjọro fun awọn eeyan ti DSS ko nile Sunday Igboho, Amofin Pelumi Olajengbesi lo ti wa sisọ loju rẹ nipa iru iku gbigbona to pa awọn mejeeji naa lọjọ Kinni osu Keje ọdun 2021 ti isẹlẹ naa waye.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olajengbesi ni ọkan ninu awọn eeyan naa, ti orukọ rẹ n jẹ Alhaji Fatai ni ko riran bo se yẹ.

Bẹẹ ba si gbagbe, agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki naa ti sọ saaju lọjọ ti isẹlẹ naa waye pe ori irun kiki ni Alhaji Fatai wa, nigba ti awọn DSS de.

Alhaji Fati ati Adogan

Olajengbesi wa tẹ siwaju pe ni kete ti awọn osisẹ agbofinro naa de, ni ọkunrin yii n tarara kiri lai mọ ibi ti yoo ya si, tori ipenija airiran rẹ.

"Ibi ti ọkunrin yii ti n wa ọna ti yoo gba sa pamọ ni ibọn ti awọn osisẹ DSS n yin laibikita ti baa, to si jade laye."

Ile iwẹ ti Adogan sa si ni ibọn DSS ti ba a:

Nigba to tun n salaye bi ẹnikeji, ti ọpọ eeyan mọ si Adogan se ku lati ọwọ osisẹ DSS bakan naa nile Sunday Igboho, Amofin agba naa salaye pe ibi ti ọkunrin naa sa pamọ si ni ibọn ti lọ baa.

Olajengbesi ni ni kete ti awọn osisẹ DSS gunlẹ si ile Igboho ni wọn n yinbọn kiri laibikita, ti wọn ko si fẹ mọ boya ibọn ba ẹnikẹni.

"Inu ile iwẹ kan ni Adogan sa pamọ si ki biọn ma baa ba amọ inu baluwẹ ọhun naa ni ibọn ti baa."

Olajengbesi wa ni ọpọ asiri lo wa nilẹ, ti ko tii tu sita nipa iwa ika ti awọn DSS hu nile Sunday Igboho eyi ti ko tii han fun araye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O si woye pe ọna bi asiri naa ko se ni tu lo mu ki awọn osisẹ DSS yii fi aake kọri lati ko awọn eeyan mẹrin silẹ ninu awọn mejila ti wọn ko nile Igboho.

Saaju ni awọn eeyan ti isẹlẹ ikọlu DSS naa se oju wọn nile Sunday Igboho ti kede pe awọn osisẹ Dss wọ oku awọn eeyan mejeeji naa lọ silu Abuja, ti ẹjẹ ara wọn si n kan silẹ.

Lati ọjọ naa, ko si ẹni to fi oju kan oku wọn titidi oni.

Àkọlé fídíò, Kola Tubosun: Ọ̀pọ̀ ọmọ òyìnbó ló ń kọ́ èdè Yorùbá, ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ gbé èdè abínibí lárugẹ