Afenifere: Ilana Omo Oodua ati Babatunde Gbadamosi fara mọ pé láìsí ìwé òfin tuntun, Yorùbá ń lọ

Oludije fun ipo gomina tẹlẹ f'ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babatunde Gbadamosi ti fẹnu kò pẹlu ẹgbẹ Afenifere lati pe fún ìwe ofin tuntun fún orilẹ-ede Naijiria ṣaaju idibo ọdun 2023.
Gbadamosi sọ fún BBC Yoruba pe, ayé sì wà fun ijọba to wa lóde lati ṣe ayipada iwe ofin Naijiria ṣaaju igba ti eto idibo gbogbogbo yóò fi waye lọdun 2023.
"Ijọba ologun lo ṣe agbekalẹ iwe ofin ti a n lo lọwọ yii, Wọn kan kọọ sibẹ pe awa ọmọ Naijiria lo gbe ofin yii kalẹ lati maa dari wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Alhaji Fatai, ti DSS pa nílé Sunday Igboho ni kò ríran"
- Wo ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tí ìdaranjẹ̀ ti di èèwọ̀ ní gúúsú Nàíjíríà
- Irọ́ ní, Taskforce ló ń gba owó gọbọi lọ́wọ́ awakọ̀ Eko, kìí ṣe àwa - LASTMA
- Afurasí ajínigbé dèrò ọrun, òmíràn kó sí pańpẹ́ ọlọ́pàá ní l’Ogun
- Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù mójú lọ sọ́jà, bí kátàkárà agbábọ́ọ́lù ṣe dópin
- Ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí gbangba òde, kóo rugi oyin lábẹ́ òfin tuntun
- Wàláhà ń bọ̀, tíjọba bá ní ká gba abẹ́rẹ́ Covid-19 ní tipá - NMA, JOHESU
Ṣugbọn kii ṣe awa araalu lo ṣe agbekalẹ ofin naa. Aarẹ Naijiria ni ààrẹ to lagbara julo Lagbaye nitori bi iwe ofin ilẹ wa ṣe rí náà ni.
Ẹ jẹ ki a pada si iwe ofin Naijiria odun 1963. Ko sí Iyanjẹ níbẹ, ẹkun kọọkan lo n ṣe amojuto ẹkun rẹ pẹlu awọn nkan alumoni ti wọn ni.
Ṣugbọn bayii, gbogbo owo ori ti a ba san nipinlẹ Eko fún àpẹrẹ, Abuja ni wọn n ko o lọ.
Nitori naa, mo faramọ ki ijọba gbe iwe ofin tuntun jade ṣaaju eto idibo 2023," Gbadamosi ṣalaye.
UK ti yapa kúrò lára ajọ EU, Yoruba naa lè yapa kúrò lára Naijiria - Ilana Omo Oodua
Ẹwẹ, agbẹnusọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Maxwell Adeleye náà tún fìdí rẹ múlẹ fún BBC Yoruba pe ko ní sí ibo lọdun 2023, Lai sí iwe ofin tuntun àti atunto orilẹ-ede Naijiria.
Ọgbẹni Adeleye ni eto idibo lati beere lọwọ awọn ọmọ Naijiria Iori bo ya won sì fẹ tẹsiwaju gẹgẹ bí orilẹ-ede kan gbọdọ wáyé ṣáájú ibo ọdún 2023.
"Ijebu ati Oyo ba n ba ara wọn já, a o yanju rẹ ni itubi inubi tori èdè kan ni a n jọ n sọ.
Ṣugbọn iru rẹ ko le ṣeeṣe lọwọ yii nitori ede wa ko ye ara wa.
Oorun to wa loke si to aṣọ sa, aye sì wà láti ṣe agbekalẹ ofin tuntun ṣaaju eto idibo ọdun 2023.
Ìjọba kò le na idaji owo to ti na lori àtúnṣe iwe ofin Naijiria to n ṣe lọwọ lori agbekalẹ iwe ofin tuntun.
UK ti yapa kúrò lára ajọ EU, Yoruba naa lè yapa kúrò lára Naijiria.
Bi Naijiria ṣe wa yii ko le ṣiṣẹ, ko pe wa," Adeleye ṣalaye.

Kò sí 'Constitution' tuntun, kò sí ìbò ní Nàíjíríà ní 2023 - Afenifere

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ẹgbẹ Afenifere tun ti ke sawọn ọmọ Naijiria lati maa daabo bo ara wọn lọwọ awọn agbebọn nitori wsn ti kede ogun nilẹ yii.
Bakan naa lo ni eto atunto orilẹede yii gbọdọ wa, lati yanju awọn isoro to n ba Naijiria finra ki eto idibo to n bọ to le waye.
Awọn ọrọ yii lo jẹyọ ninu abajade ti ẹgbẹ naa fisita lẹyin ipade wọn to waye nilu Ijebu Ode lọjọ Isẹgun nile Oloye Ayo Adebanjo, tii se adele alaga wọn.
Atẹjade naa ti akọwe apapọ fun ẹgbẹ Afenifere, Jare Ajayi fisita tun ni ke sawọn agbofinro lati dẹkun bi ọpọ eeyan ti iwa wọn ko tọ se n wọ ilẹ yii wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àṣírí tú lórí ìdí tí DSS kò ṣe fi mẹ́rin sílẹ̀ nínú amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho - Amòfin Olajengbesi
- Akeredolu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l'Ondo
- Ìmáàmú àgbà kan ní Abuja ti fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí Buhari torí ìkọlù agbébọn
- O kò ní wọ ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí tó ò bá gba abẹ́rẹ́ Covid-19 - Ìjọba Ondo
- Owó ilẹ̀ òkèèrè ta yá, orí pípé la fi ya - Mínísítà
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
O ni eyi ni yoo wawọ awọn isẹ ibi to n gogo ni orilẹede yii bolẹ.
"Ẹgbẹ Afenifere ri pe awọn iwa idunkooko mọ ni to fi mọ ijinigbe ti n di tọrọ fọn kale, to si n kọ ni lominu, ti awsn eeyan wa ni Yewa, Oke Ogun atawọn agbegbe miran si n lọ fi tipa se atipo ni orilẹede Benin.
O yẹ ki ijọba atawọn agbofinro tete gbe igbesẹ lati fopin si eyi, ko si fi aabo ẹmi ati dukia to daju mulẹ.'
Ẹgbẹ naa tun wa kesi ijọba lati ri pe aabo to daju wa fun awọn eeyan to n gbe ni awọn ẹnu bode to wa ni Kogi, Oyo, Ogun, Kwara, Osun, Ekiti ati Ondo.
Bakan naa ni wọn ni iwaasu ti Afenifere yoo ma se kiri bayii ni pe ko si iwe ofin tun, ko si ibo lọdun 2023, nitori fifi akoko sofo ni ba ba se ibo pẹlu ofin ọdun 1999.
Ẹgbẹ naa tun wa kede pe gba gba gba ni oun wa lẹyin awọn gomina lẹkun guusu Naijiria ti wọn fi ofin de asa dida ẹran jẹko nigboro eyi to n gbera sọ lonii.
Bẹẹ ni wsn tun se sadankata si awsn gomina ilẹ Yoruba fun bi wọn se se agbekalẹ ikọ alabo Amotekun.


















