Nigeria Foreign Loan: Mínísítà fétò ìṣúná ní ìdàgbàsókè bá ọrọ̀ ajé Nàíjíríà ní 2021 ju ti 2014 lọ

Mínísíta ètò ìsúná àti ètò ìlú Zainab Ahmed, tí ni kí àwọn ọmọ Nàìjíríà má fòyà lórí owó tí ìjọba àpapọ̀ ń yá láti fi kún ètò ìsúná ìlú.
Làsìkò tó ń bá àwọn òníròyìn sọ̀rọ̀ nílu Abuja, ló ti fi dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú pé orí pípé ni ijoba fi ń yàwó, tí wọn sì ń lò ó fún ètò ìdàgbàsókè ati amuludun.
Èyí tún kún bí ó ṣe ṣàlàyé pé ìdàgbàsókè to bá ètò ọ̀rọ̀ ajé ni osu mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2021 tí ju èyí tí Naijiria ti rí láti ọdún 2014.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
- Eégún ń tọpinpin kónílé ó gbélé nílẹ̀ Igbo, nǹkan yan
- Ẹ̀yin olùwọ́de Yoruba Nation, Arewa ń fẹ́ kẹ jáwọ́ àmọ́... - Àgbàgbà Yoruba
- Sunday Igboho, Nnamdi Kanu tó ń dàámú wa ti kó sẹ́wọ̀n, Ọlọ́run wa kò sùn - Miyetti Allah
- Ajínigbé kọlu ìjọ David Oyedepo, wọ́n jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ
- Àjàlú ńlá ń bọ̀ Buhari múra, màrìwò eégún lásán lo rí ní NDA - Fr Mbaka
- Sunday Igboho tún dá Malami mọ́lẹ̀ fún ìgbà kejì nílé ẹjọ́
- DSS tú mẹ́jọ sílẹ̀ nínú àwọn ọmọlẹyìn Igboho, mẹ́rin ṣì wà ní àhámọ́
- Alálẹ̀ ló fi èmi àti Sunday Igboho pamọ́ sí àhámọ́ kí ewu le ré wa kọjá - Oba Ogboni
Ó fi kún pé ó ti eto oro aje Nàìjíríà tí lè ní idà márùn-ún àti díẹ̀ ni tẹ̀lé ń tẹle báyìí láti àsìkò òfin kóníléógbéle ọdún 2020.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ìyàtọ̀ to tí bá ètò ọ̀rọ̀ ajé tí a bá fi we irú àsìkò yìí ni ọdún tó kọjá nípa ìdàgbàsókè, kọjá sísọ.
O ni gbogbo èka àwọn tó ń pèsè ìrànwọ́ lo ṣe dáadáa julọ pẹ̀lú ìdàgbàsókè idà mẹsan àti díẹ̀, èyí tó gòkè julọ láti ọdún 2010.
Ahmed fìdí rẹ múlẹ̀ pé àwọn àmì yíi fi hàn pé gbogbo ètò ọ̀rọ̀ ajé tí ń gbéra ju ti àsìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Coronavirus lọ.

Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ nílùú Oyo nítorí lẹ́tà tí àwọn adigunjalè kọ sí bánkì kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oṣiṣẹ alaabo lẹyin ti iroyin jade pe awọn adigunjale kọ lẹta si banki kan ni agbegbe Owode, nilu Ọyọ, nipinlẹ Oyo pe awọn n bọ wa a ja lole.
Iroyin sọ pe ni nkan bi oṣu kan sẹyin ni awọn adigunjale naa kọ lẹta ọhun.
Iwe iroyin The Nation jabọ pe oṣiṣẹ alaabo to wa lẹnu ọna abawọle si banki naa ni wọn fun ni lẹta naa lọjọ ti wọn wa.
Ti wọn si sọ fun pe ko fi jiṣẹ fun ọga agba banki naa.
Eyi si la gbọ pe o mu awọn ileeṣẹ alaabo bẹrẹ eto aabo to l'agbara fun gbogbo awọn banki to wa ni agbegbe naa.
Wọn ni o ṣe e ṣe ko jẹ banki miran ni awọn adigunjale naa fẹ ẹ kọlu, amọ ti wọn fẹ ẹ fi lẹta ti wọn ru awọn oṣiṣẹ alaabo loju.
Adugbo Owode jẹ gbajugbaja nilu Ọyọ, nibẹ si ni ọpọ ile itaja nla ati awọn banki wa.
Owode ko fi bẹẹ jina si aafin Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamide Adeyẹmi, bẹẹ no ko jina si yunifasiti to wa ni ilu naa, ati olu ileeṣẹ ọlọpaa Agbegbe Ọyọ.
Ọpọ igba ni iroyin ti jade pe awọn adigunjale kọ lẹta si adugbo tabi ileeṣẹ pe awọn n bọ wa a ja wọn lole.
Eyi to ma n fa ibẹru laarin olugbe adygbo naa.
Wo nkan ti o le ṣe, ti adigunjale ba kọ lẹta ikọlu si adugbo tabi ileeṣẹ rẹ:
Onimọ kan nipa eto aabo, Ọgbẹni Akin Adeyi ti sọrọ lori nkan ti awọn araalu le ṣe nigbakuugba ti wọn ba gba lẹta ẹru lọwọ adigunjale.
Nigba ti BBC ba sọrọ, Ọgbẹni Adeyi sọ pe nkan akọkọ fun iru adugbo bẹẹ lati sẹ ni pe ki wọn o bẹrẹ si ni fi oju silẹ lati ri awọn nkan to yẹ.
"O yẹ ki awọn ara adugbo naa yẹ ara wọn wo, lati mọ awọn eeyan buruku to n gbabọde laarin wọn."
O ni o sẹ pataki fun awọn to ba n gbe niru adugbo bẹẹ, lati ma ṣe akiyesi irinsi gbogbo eeyan ni adugbo wọn, paapaa awọn to ba jẹ ajeeji tabi ti iṣesi wọn mu ifura dani.
Bakan naa lo sọ pe ki awọn ara adugbo fi nkan ifura ti wọn ba ri to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni kiakia, nitori pe imọ ti awọn ọlọpaa ba ni, ni wọn o fi pese abo
Akin Adeyi ni: "Gbigbe igbesẹ oju ni alakan fi n sọri ni ọna abayọ to le dena iru awọn nkan bayii."













