Amotekun: Afurasí ajínigbé mẹ́rin náà ní àwọn ti gba ₦6.4m ati ₦1.2m lọ́wọ́ àwọn tí wọn jí gbé sẹ́yìn

Fulani

Oríṣun àwòrán, thechroniclernewspaper

Ọwọ awọn oṣiṣẹ ikọ Amotekun ti tẹ awọn afurasi ajinigbe mẹrin kan loju ọna marosẹ Iseyin si Oyo, nipinlẹ oyo.

Awọn ọdọkunrin mẹrin ọhun ni wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kogi, Niger, Kano ati Sokoto.

Iroyin ni inu oko kan ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa ni Odo-Ogun loju ọna Iseyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn afurasin ọhun ṣalaye fun ikọ Amotekun pe, awọn lo wa nidii iṣẹlẹ ijinigbe meji to waye lagbegbe naa nibi ti wọn ti gba owo ti iye rẹ to ₦6.4m ati ₦1.2m lọwọ awọn ti wọn ji gbe.

Àkọlé fídíò, Ọlatunji, akẹ́kọ̀ọ́gboyè 'graduate' tó ń ta àkàrà 'Ó ta lẹ́nu' nílùú Osogbo

Wọn tun ṣalaye pe wọn fi miliọnu mẹta lara owo itusilẹ ti wọn gba lọwọ awọn ti wọn ji gbe naa ṣọwọ si agbodegba wọn kan niluu Kano, ti yoo fi owo naa ra maalu ranṣẹ si awọn.

Ọwọ tẹ awọn afurasi Fulani naa lasiko ti wọn n gbiyanju lati ji agbẹ kan gbe lagbegbe ti wọn n pe ni "Mighty Farm" ni Odo-Ogun, wọn si ka awọn ohun ija oloro bii ibọn, ada ati ọbẹ mo wọn lọwọ.

Ikọ Amotekun sọ fun awọn akọroyin pe wọn ti ko awọn afurasi naa lọ si agọ ọlọpaa Iseyin fun iwadii ni kikun.

Ti ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn afurasi Fulani yoo ji awọn eeyan gbe lagbegbe Iṣeyin.

Bẹẹ naa ni awọn afurasi ọdaran maa n kọlu awọn ilu kereje lagbegbe ọhun ti wọn si n maa n fi ẹmi ọpọ eeyan ṣofo nibẹ.

Ṣugbọn gomina Seyi Makinde ti ṣeleri fun awọn eeyan agbegbe naa pe ifẹmiṣofo ko ni waye mọ nibẹ niwọn igba ti oun ba ṣi wa lori oye gẹgẹ bii gomina ipnlẹ ọhun, ati pe ki wọn di ẹbi ọrọ naa ru oun ti irufẹ isẹlẹ bẹẹ ba tun waye.

Àkọlé fídíò, Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji