Nigeria Insecurity: Rashidi Ladoja àtàwọn àgbà Yorùbá míì sọ òkò ọ̀rọ̀ sáwọn gómìnà Òkè Ọya tó wá bẹ̀bẹ̀

Ladoja ati awọn gomina apa oke ọya

Oríṣun àwòrán, Nigerian Tribune

Agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni agba ti ko ba kẹhun sọrọ, o di dandan ko kẹ itan sare.

Eyi lo mu ki awọn agbaagba lẹkun ariwa Naijiria to n kọminu lori ikunsinu iran Yoruba si ijọba aarẹ Buhari se bẹrẹ idirẹbẹ.

Igbesẹ naa, ni wọn lo wa lati tu ẹya Yoruba ninu, ti wọn si n tọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba lọ lati rọ wọn pe ki wọn gba alaafia laaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan naa, ni iwadii kan sọ pe wọn jẹ gbajumọ ninu ijọba Buhari, ti wọn si ti n lọ labẹlẹ lati wa ẹyọnu ẹya Yoruba.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Tribune se sọ, lara awọn eekan lẹkun ariwa to n lọ kaakiri naa ni Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Bala Buni, Abubakar Badaru ti Jigawa ati Atiku Bagudu tipinlẹ Kebbi.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ladoja ní bí ìjọba kò bá fi ẹ̀lẹ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ajìjàgbara míì yóò dìde

Iroyin naa ni laarin ọsẹ mẹta, awọn eekan ariwa naa ti lọ sile awọn agbaagba ilẹ Yoruba kan bii alagba Reuben Fasoranti ati Oloye Olu Falae.

Awọn yoku ni Oloye Rashidi Ladoja, Ayo Opadokun, Dokita Kunle Olajide ati Aarẹ Musulumi ilẹ Yoruba, Edo ati Delta, Alhaji Daud Akinola.

Lẹyin ọpọ ipade ti wọn se nilu Ibadan Akure ati Abeokuta, awọn alejo lati ẹkun ariwa naa pẹlu awọn to gba wsn lalejo ni ko sọ ohunkohun fawọn akọroyin lori igbesẹ wọn ọhun.

Iroyin naa ni kii se pe awọn eeyan naa wa lati fa oju awọn agbaagba Yoruba mọra nitori ibo 2023, gẹgẹ bii iroyin to n lọ nigboro.

Gẹgẹ bi iwe iroyin naa se sọ, Ladoja lasiko ipade naa bu ẹnu atẹ lu ipo ti orilẹede yii wa labẹ isejọba Buhari ati iyansipo awọn eeyan ti ko tọ.

Bakan naa ni wọn ni Ladoja tun sọ fun awọn alejo naa pe se ni Buhari ati isejọba rẹ n se ẹya Yoruba bii eru ti wọn ko loju ogun.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Fun apẹrẹ, Ladoja ni ijọba apapọ si awọn ẹnu bode to wa ni ẹkun ariwa Naijiria, to si ti ẹnu bode to wa ni guusu, eyi to wa lati sẹ eegun ẹyin ọrọ aje wọn.

O fikun pe awọn asọbode n kọlu awọn ọja nlanla gbogbo nilẹ Yoruba lati beere ibi ti wọn ti ri ọja ko wọle amọ ti awọn olokoowo lati ariwa, bii Dangote ati Bua n gba ẹnu bode naa kọja.

Ko tan sibẹ, Ladoja tun sọ pe o ti han gbangba pe ẹkun ariwa ti setan lati pin kuro lara Naijiria pẹlu bi ijọba Buhari se n ya owo to fi n pese ohun eelo amayedẹrun si ẹkun ariwa nikan ati ilẹ Niger pẹlu.

Bakan naa lo ni se bi ohun ti Sunday Igboho sọ naa ni Emir ilu Mubi sọ, ẹni to fun awọn Fulani darandaran ni gbdeke ọjọ lati fi ilu rẹ silẹ amọ to jẹ pe Igboho nikan ni wọn n fi iya jẹ.

Ohun ti Ladoja sọ naa ni awọn agbaagba Yoruba yoku naa sọ fawsn alejo lati Oke Ọya naa, ti wọn si panupọ sọ pe ọrọ ibo 2023 kọ lo kan bayii.

Àkọlé fídíò, Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ