Ọwọ́ ọlapàá tẹ obìnrin tó jí ẹ̀ṣọ́ ara okù

Oríṣun àwòrán, Robert Hoetink/Getty Images
Obinrin kan ti dero atimọle lẹyin ti ọwọ tẹẹ lori ẹsun pe o ji ẹṣọ ara oku lorilẹ-ede France.
Obinrin naa ti ọjọ ori rẹ ti le ni ọgọta ọdun yọju sibi ayẹyẹ isinku naa, nibi to ti sọ fun awọn mọlẹbi oloogbe pe ọrẹ rẹ ni oun.
Idi ree ti wọn fi mu obinirin naa lọ sibi ti wọn tẹ oku ọhun si, sugbọn lẹyin ti wọn pada de ibi ti oku naa wa ni wọn ṣakiyesi pe gbogbo ẹṣọ ara rẹ ti poora.
Awọn ẹbi naa ke gbaajare, wọn si tun fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
Lẹyin iwadii awọn ọlọpaa ni ọwọ tẹ arabinrin naa to n gbe lagbegbe ti ko jinna si ile isinku naa wa.
Awọn ọlọpaa ṣawari ẹṣọ oku to ji, wọn si tun tii mọle.
Yatọ si awọn ẹṣọ ara oku ti obinrin naa ji, iwadii tun fi han pe o ji apo ilewọ ọkunrin kan to wa nibi ayẹyẹ eto isinku naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa France sọ pe iwadii awọn fi han pe obinrin naa maa n ṣo awọn ọmọ olooku lati mọ asiko ti wọn ba n sin oku mọlẹbi wọn ko le yọju sibẹ lati ṣọṣẹ.
Wọn ni afurasi ọhun yoo yọju sile ẹjọ lọdun 2022 lẹyin ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan.
- Mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́wàá tí ò lè fi kó sí páńpẹ́ LASTMA ní Eko àti ìjìyà tó tẹ̀lẹ̀ e
- Wo ìdí tí wọ́n fi ta ẹyẹlé kan ṣoṣo ní ₦893,000,000
- Buhari, rọra yá owó kí Nàìjíríà má ba á kú sóko gbèsè o- Atiku Abubakar
- Àwọn olùgbé Akinyele fí ẹ̀sùn ilẹ̀ gbígbà kan ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, ìjọba Makinde ti fèsì padà
- Akẹ́kọ̀ọ́ 32 láti Bethel Baptist School gba òmìnira lọ́wọ́ ajínigbé
- Wo àwọn Fasiti Nàìjíríà tó gbégbá orókè lágbàyé













