Olórí ijọ kan àti Olùjọ́sìn mẹ́sàn án ko ìjàmbá ọkọ̀ nílùú Eko

Ijamba Oko

Oríṣun àwòrán, others

O kere tan awọn olujọsin mẹwaa kan to fi mọ awọn ọmọde ni ori ko yọ ninu ewu ijamba ọkọ kan nilu Eko.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ko jọ lati ọdọ ileesẹ to n ri si ọrọ isẹlẹ pajawiri ni Eko, nise ni ọkọ ayọkẹlẹ wọn ya kuro lọna to si lọ ja si inu koto nla kan laudugbo Magodo ni Eko.

Ninu awọn olujọsin mẹwaa to farapa yi la ti ri awọn ọmọde ati oniwaasu kan.

Gbogbo wọn ti n gba itọju nile iwosan aladani kan ni Eko.

Ijamba naa la gbọ pe o ṣẹlẹ nigba ti ọkọ naa to ni nọmba idanimọ BDG 234 DW, ṣadede ya lọna lopopona Tokunboh Macauley lẹba Emmanuel Keshi nitori ijanu rẹ to kọṣẹ.

Àkọlé fídíò, Joke Silva: Olu, ó tó gẹ́ pẹ̀lú obìnrin yìí níkan tó ń ba ẹ ṣeré ìfẹ́ nínú sinimá

Ago mẹwaa abo aarọ sunmọ nigba ti ijamba yi waye.

Ninu alaye rẹ, ọga agba ajọ iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko,LASEMA,Dokita Olufemi Oke-Osanyintolu ni awọn oṣiṣẹ pajawiri ko pe ti wọn fi debi iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

O ni ijanu ọkọ naa lo kọṣẹ ati pe awọn ti gbe ọkọ naa kuro ninu koto ti awọn to farapa si ti n gba itọju.

Àkọlé fídíò, Test your Yoruba language skill: Wá ká jọ sọ Yorùbá...