Ghana Cathederal project: Ìmáàmù àgbà orílẹ̀èdè Ghana gbé owó kalẹ̀ fún kíkọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì

Sheikh Osmanu Nuhu Sharubutu

Oríṣun àwòrán, AFP

Imaamu agba lorilẹede Ghana, Sheikh Osmanu Nuhu Sharubutu ti gbe owo to le ni ẹgbẹrun mẹjọ dọla kalẹ lati ṣe atilẹyin fun kikọ ijọ nla kristẹni kan lorilẹede naa.

Sheikh Sharubutu kede ẹdawo naa lasiko ti awọn igbimọ majẹobajẹ ti wọn gbe kalẹ fun kikọ ṣọọṣi nla naa bẹẹ wo ni ọfiisi rẹ.

O ni igbesẹ naa ko yẹ lẹyin lilọ igi ifẹ laarin awọn ẹlẹsin gbogbo nibẹ ni alẹye

Bi o tilẹ jẹ pe Orilẹede Ghana wa lara awọn orilẹede ti alaafia ti n jọba laarin awọn ẹlẹsin gbogbo lagbaye sibẹ ẹgbẹrun mẹjọ dọla ti Imaamu agba naa da fun kikọ ṣọọṣi naa jẹ eyi to ya ọpọlọpọ lẹnu.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Ṣọọṣi apapọ naa ti n fa ọpọlọpọ awuyewuye lorilẹede naa lẹyin ti ijọba orilẹede ọhun gbe aba gbigbe igbimọ ikowojọ naa dide lati ṣe koriya fawọn ọmọ orilẹede Ghana lati lee dawo fun kikọ ṣọọṣi naa si ilu Accra tii ṣe olu ilu orilẹede naa.

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

Ile ijọsin ọhun yoo na wọn ni owo to le ni ọgọrun miliọnu dọla.

Bakan naa ni wọn fi idi rẹ mulẹ pe kiko owo rẹ jọ ko ni lọwọ ijọba ninu.

Ọpọ lo ti kọminu lori kikọ ṣọọṣi naa eleyi ti wọn ni ko tọ lasiko ti ọrọ aje dagun lorilẹede naa.

Àkọlé fídíò, Ohun ti Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sátánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́