LASTMA, Lagos Traffic Offence:: Mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́wàá tí ò lè fi kó sí páńpẹ́ LASTMA ní Eko àti ìjìyà tó tẹ̀lẹ̀ e

Oríṣun àwòrán, Tellerafrica
Die ree ninu awọn ẹsẹ mẹrinlelọgọta ti awakọ le tasẹ agẹrẹ si nilu Eko
Bi ọrọ ba kan iwakuwa ọkọ ni Naijiria, awọn awakọ ipinlẹ Eko ko gbẹyin Wo ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn márùn ún tí àwọn èèyàn ilú Eko fi kan àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA
Idi ti eleyi si fi ri bẹ ni pe iruwa ogiri wa lo pọ ni Eko.
Ninu awọn awakọ ipinlẹ yi la ti ri awọn to mọ ọkọ wa ati awọn miran to n fi agidi wa ọkọ.
- Ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yóò wáyé ní Eko, Oyo, Ogun, Ondo àti ìpínlẹ̀ 30 míì láàrín ọjọ́ mẹ́ta- NiMet
- Wo ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ fún àgbà nọ́ọ̀sì tó ta ọmọ ọdún mẹ́fà ní N200,000
- Reach, orúkọ ọkọ̀ òfurufú tíwọ́n bi ọmọ Afganistan ọjọ́si si náà ni wọ́n sọ ọmọbìnrin ọ̀hún
- Ìkọlù tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ ológun ní Kaduna le jẹ́ ète láti fi ìjọba Buhari ṣe ẹlẹ́yà - Garba Shehu
- Kò sí ọmọ Zambia kan tó má sùn pẹ̀lú ebi mọ́ lásìkò tèmi gẹ́gẹ́ bíi Aàrẹ- Hichilema ṣèlérí
Bi awọn agba ṣe n sọ pe nilu ti ko si ẹsẹ, ko si ofin nibẹ.
Fawọn to ba daran ẹsẹ iwakuwa ọkọ loju popo ni Eko, awọn ijiya kan wa ti ijọba la kalẹ.
Ijiya naa to mẹrinlelọgọta ṣugbọn nitori aaye ati akoko, a o ṣe atupalẹ mẹwaa ninu wọn ati ijiya to tẹle.
Kiko ero kọja iye to yẹ:
Bi awọn ẹsọ oju popo tabi LASTMA bi wọn ti se n pe wọn nilu Eko ba gba awakọ to ko ero to kọja iye to yẹ mu, ijiya nla wa fun iru ẹni bẹ.
Labẹ ofin wọn le gba ọkọ iru awakọ bẹ.Yoo san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta Naira tbi ko si se ẹwọn oṣu mẹta tabi oṣu mẹfa
Lilo ẹrọ ibanisọrọ lasiko ti o ba n wakọ:
Awọn to ba fẹran lati maa lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ lati pe eeyan tabi gba ipe lasiko ti wọn n wa ọkọ ni ẹsẹ yi ba wi.
Yatọ si akoba to le ṣe fun ẹni to n wa ọkọ, o tun le ṣakoba fun awọn awakọ mii.
Ijiya to wa fun ẹsẹ yi ni pe ti ẹni naa ba jẹ ẹlẹṣẹ fun igba akọkọ yo san ẹgbẹrun lọna ogun Naira.
Bi o ba ti ṣẹ iru ẹṣẹ yi tẹlẹ yoo san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira.
Wọn tun le ni ko ṣe iṣẹ isinru oṣu mẹta.
- Buhari, rọra yá owó kí Nàìjíríà má ba á kú sóko gbèsè o- Atiku Abubakar
- Wo iye ìgbà tí wọ́n ti jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Nàìjíiríà
- Àwọn olùgbé Akinyele fí ẹ̀sùn ilẹ̀ gbígbà kan ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, ìjọba Makinde ti fèsì padà
- Àwọn òbí ta dúkìá, ilé ẹ̀kọ́ Islamiya ta ilẹ̀ wá N61m owó ìtúsílẹ̀ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Tegina tó gbòmìnira
- Ìtàn Ìjàpá àti ọbọ ni ìjọba àpapọ̀, àwọn agbófinró ń sọ nípa Igboho - Wole Soyinka
Wiwa ọkọ pẹlu ilẹkun ni ṣiṣi:
Awọn ọlọkọ Sienna to maa n gbe ero lo kundun ki wọn maa se eleyi paapa awọn ti ọkọ wọn ko ba ni ẹrọ amuletutu taa mọ si Airconditioner.
Ijiya fawọn to ba ṣẹ lakọkọ ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira.
Bi o ba ti kọja igba akọkọ, ẹni naa yoo san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira.
Wọn tun le ni ko ṣe iṣẹ isinru oṣu kan.
Awakọ to ba n ba ẹsọ oju popo ṣagidi:
Ijiya ẹṣẹ yi ni pe wọn yoo gba ọkọ iru awakọ to baa n ba LASTMA ṣagidi loju popo.
Bi o ba jẹ igba akọkọ ree to ṣẹ, yoo san ẹgbẹrun lọna ogun Naira.

Oríṣun àwòrán, lastma
Bi o ba ti n hu iru iwa bẹ tẹlẹ, yoo san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira.
Wọn tun le ni ko lọ gba idanilẹkọ ni ileesẹ awọn adari oju popo.
Ọ́kọ agbowo Bullion Van to gba One Way:
Iru nkan bayi ko jẹ tuntun lọwọ awọn awakọ ọkọ to n gbe owo taa mọ si Bullion Van.
Ijiya rẹ wa ni ipele meji si mẹta.

Oríṣun àwòrán, LASTMA
Akọkọ wọn yoo gba ọkọ naa.Boya yoo jẹ pẹlu owo inu rẹ ofin ko sọ.
Ẹlẹẹkeji ni pe awọn to ni ọkọ yi yoo san owo itanran ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira.
Diduro lati gbe ero loju ọna marose:
Ijiya yi wa fun ero ati awakọ.
Ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ni owo itanran fun gbigbe ero ni aaye ti kii ṣe ibudo akero.

Oríṣun àwòrán, @LASTMA
Yatọ si owo, dirẹba yoo lọ si ile ẹkọ LASDRI lati lọ tun ẹkọ ọkọ́ wiwa kọ.
Ijiya ẹwọn oṣu mẹta naa wa fun ẹsẹ yi.
Wiwa ọkọ lai de igbanu taa mọ si seatbelt:
Ẹgbẹrun lọna ogun tabi lọna ọgbọn ni ijiya ẹsẹ yi.
Bi eeyan ba tasẹ agẹrẹ ofin nipasẹ́ iwa yi wọn tun le gba ọkọ rẹ tabi ki wọn ni ko lo igbanu rẹ.
Kika owo tabi ki eeyan maa ṣe nkan mii lasiko to n wa ọkọ:
Ẹgbẹrun lọna ogun tabi lọna ọgbọn ni ijiya ẹsẹ yi iyẹn fun ẹni to ba ṣe ni igba akọkọ tabi igba ẹkeeji.
Wọn tun le ni ko ko ṣe iṣẹ adugbo oloṣumẹta.
Wiwa ọkọ gba oju aaye ọkọ nla BRT
Ati onile ati alejo lo mọ pe aala BRT yatọ si awọn ọkọ to ku ni ipinlẹ Eko.
Fun awakọ to ba keti ikun to lọ gba oju ọna BRT, ijiya Ẹgbẹrun lọna ogun tabi lọna ọgbọn ni ijiya ẹsẹ yi.
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé ẹjọ́ sọ pé kí Lizzy Anjorin san 9.5m fún ẹni tó pé lẹ́jọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀?
- Pòrò-pòrò ni omijé n dà níbi ètò ìsìnkú Mohammed, ọmọ Gani Fawehinmi
- Báyìí tí Osun pé ọgbọ̀n ọdún, a máa yi ǹkan padà- Gomina Oyetola
- Ẹgbẹ́ ọmọ bíbí gúúsù Kaduna tún ti sọ̀rọ̀ pé ìkọlù sí iléeṣẹ́ ológun NDA kò jẹ́ ìyàlẹ́nu
- Channels TV sọ̀rọ̀ sókè lórí ìròyìn pé DSS ti gbé òṣìṣẹ́ wọn lórí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú Ortom
Wọn tun le sọ ẹni bẹ si isẹ isnru oṣu mẹfa tabi ọdun kan.
Yoo tun lọ si ọdọ awọn LASDRI lati lọ tun ọkọ wiwa kọ.
Lilu oṣiṣẹ LASTMA:
Ijiya ẹṣẹ yi le kenka.
Ẹni ba da ẹsẹ pe o lu oṣiṣẹ LASTMA yo san ẹgbẹrun lọna ọgọrun un Naira tabi ko si lọ sẹwọn oṣu mẹfa.
Yatọ si eleyi yoo tun san owo gba maa binu fun oṣiṣẹ LASTMA ti wọn ba ri pe o ṣiwọ lu.
Wo ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn márùn ún tí àwọn èèyàn ilú Eko fi kan àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA
Odu ni ileeṣẹ LASTMA nipinlẹ Eko, kii ṣe aimọ fun oloko awọn eeyan ipinlẹ naa, to fi mọ awọn eeyan ipinlẹ mii.
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo da ileeṣẹ naa silẹ lọdun 2000 lati le mu adinku ba sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ loju popo, ati lati mu adinku ba iye ijamba ọkọ to n weaye nibẹ.
Ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti da ileeṣẹ naa silẹ, oniruru iwa ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa n wu ti ọpọ olugbe ilu Eko si sọ pe ko tẹ awọn lọrun.
Lara wwọn ẹṣun ti awọn eeyan fi kan LASTMA ree.
- Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ẹ̀bẹ̀ DSS láti dáwọn ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho mẹ́rin tó gb'òmìnira padà s'atìmọ́lé
- Àwọn jàndùkú agbébọn tún yìnbọn pa èèyàn tó lé ní 30 nílùú Jos
- Famodun, Alága APC Osun., lọ jáwọ́ nínú ẹjọ́ APC tó wà nílé ẹjọ́- Gomina Oyetola
- "Ó yẹ kí àwọn ẹ́ṣọ́ aláàbò lè mọ̀ pé àwọn jàndùkú fẹ́ kọlu ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà, NDA kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé"
Fifi panpẹ ofin mu awọn awakọ lọna aitọ
Ọpọ igba ni awọn awakọ nipinlẹ Eko ti fẹsun kan awọn oṣiṣẹ Lastma pe wọn fi panpẹ ofin mu awọn awakọ lọna aitọ.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn eeyan kan to ba BBC sọrọ sọ, wọn ni awọn oṣiṣẹ LASTMA maa n mọọmọ ṣi awọn eeyan lọna lati gba oju ọna ti ko tọ ki wọn le mu wọn lọna ati gba owo lọwọ wọn.
Irọ pipa
Ọpọ eeyan lo ti fẹsun kan LASTMA pe ti wọn ba mu awọn tan, ni ṣe ni wọn maa n pa irọ mọ awọn loju wọn lori ohun to ṣẹlẹ, eyii ti ko dun mọ awọn ninu.
Gbigba owo lọwọ awọn awakọ lọna ti ko tọ
Awọn ti BBC ba sọrọ sọ pe ọpọ igba ti LASTMA ba mu awọn, kii ṣe lati pa oju popo mọ nikan, ṣugbọn wọn maa n mu awọn lọna ati gba owo lọwọ wọn.
Lootọ ni ijọba ipinlẹ Eko ni awọn ofin to rọ mọ irin ajo oju popo ati ijiya to tọ si irufẹ ẹni to ba tapa si awọn ofin naa.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn awakọ kan ba BBC sọ, awọn oṣiṣẹ LASTMA maa n halẹ mọ awọn pe wọn yoo foju bale ẹjọ, eyii to maa n mu ki awọn san owo ọmọ gọ fun awọn oṣiṣẹ LASTMA ọhun.
- Wo ǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa ilé ẹ̀kọ́ ológun NDA táwọn jàndùkú kọlù ní Kaduna
- Ǹkan mọ́kànlá tí o ni láti mọ̀ nípa Sẹnatọ Biyi Durojaiye tó d'Ólògbé
- Mẹ́fà nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Islamiyya Tegina ti kú, àwọn ajínigbé ṣì ń bèèrè N200m
- Tètè wá gbé òkú eèyàn rẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ a ó sìn wọ́n papọ̀ mọ́ tí 200 lópin ọ̀sẹ̀- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Èèyàn márùn ún kú, ọ̀pọ̀ míì farapa lásìkò rògbòdìyàn àwọn ọmọ onílẹ̀ l'EKo
Idunkoko mọ araalu
Ọpọ awakọ to ba BBC sọrọ fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ LASTMA pe wọn maa n dukoko mọ awọn loju popo.
Ẹnikan ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede sọ pe "Awọn LASTMA kan sọ fun mi pe wọn maa fun ni tikẹẹti ti a ba de ọọfisi wọn, idi ree ti mo ṣe fun wọn ni ẹgbẹrun marun un naira ki ma baa tẹle wọn lọ si ọọfisi naa."
O tẹsiwaju pe "Ihalẹ awọn LASTMA ti pọ ju, iwa naa si jẹ eyii to buru jai nitori owo ti wọn fẹ gba naa ni."
Owo ti ko ni ẹri
Awọn eeyan ilu Eko tun maa n fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ LASTMA pe wọn maa n gba owo lọwọ awọn lai fun wọn ni iwe pelebe ti yoo duro gẹgẹ bii ẹri owo ti wọn san.
Arakunrin mii ti a tun ba sọrọ ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede ni "Nigba ti wọn bere owo lọwọ mi ki n ma ba tẹle wọn lọ si ọọfisi, mo bere risiiti owo naa lọwọ wọn ṣugbọn wọn ko le pese eri owo sisian ọhun.
Awọn mii tilẹ tun sọ pe ijọba ipinlẹ Eko ti fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ni iye owo to yẹ ki wọn maa pa wọle lojojumọ, eyii to mu ki wọn maa wu iwa Baṣorun Gaa loju popo, ṣugbọn a ko le fidi otitọ ọrọ naa mulẹ.
Bo tilẹ jẹ pe lootọ ni ọpọ awọn awakọ ti fi oniruru ẹsu kan LASTMA l'Eko, ọpọ anfani ni ileeṣẹ ọhun ti ṣe fun awọn eeyan ipinlẹ ọhun.
Lara anfani naa ni bi ileeṣẹ naa ṣe gba ọpọ eeyan siṣẹ, ati adinku to de ba sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ nipinlẹ Eko.
- Tètè wá gbé òkú eèyàn rẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ a ó sìn wọ́n papọ̀ mọ́ tí 200 lópin ọ̀sẹ̀- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Ìjà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o, àwọn dókítà NARD tó ń yanṣẹ́lódì fárígá pẹ̀lú ìjọba
- Secondus, alága PDP ní òun kò bẹ̀rù àṣẹ ilé ẹjọ́, kí ẹgbẹ́ má bàjẹ́ ni tòun
- Ìdí rèé ti mo fi ní kí aráàlú máa di ìhámọ́ra ogun nítorí àwọn janduku- Gómìnà Katsina
- Èèyàn márùn ún kú, ọ̀pọ̀ míì farapa lásìkò rògbòdìyàn àwọn ọmọ onílẹ̀ l'EKo
- Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé

























