Obasanjo Postrates to kings: Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, others

Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé

Aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ kii ṣe Ajeji si ti ka bu óla fun aṣa ati iṣẹṣe paapaa fun awọn obalaye.

Ni ọjọ Aiku, ọjọ kejilelogun, osu kẹjọ, ọdun 2021 ni ariwo tun sọ lori ayelujara lẹyin ti aworan Oloye Ọbasanjọ nibi ti o ti fi orokun mejeeji kunlẹ fun ọba tuntun Olu ti ilu Warri, Ogiame Atuwatse kẹta.

Ohun to jọ ọpọlọpọ loju ni pe Oloye Ọbasanjọ, ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin n wolẹ ki Olu ti ilu Warri ti ọjọ ori rẹ din diẹ ni Ogoji.

Fun awọn ti ko mọ nipa aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba, eyi lee jẹ babara.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @Obasanjo

Bẹẹ si ni Oloye Ọbasanjọ ti ṣalaye pe kii ṣe Obalaye nikan ni oun wolẹ fun bi ko ṣe gbogbo awọn agbagba iṣaaju ti wọn ti joko sori itẹ naa sẹyin.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun Oloye Obasanjo lori ọrọ iroyin fi sita, "aṣa ati iṣẹṣe ni. Alayeluwa Ogiame Atuwatse kẹta kọ lo wa lori oye mọ iṣẹṣe lo joko sibẹ bayii.

Gẹgẹ bii baba ni ilẹ Afirika, Oloye Ọbasanjọ ko ni ṣalai juba ati fi ọwọ to ba yẹ fun awọn itẹ ọbalaye gbogbo."

Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní

Ṣe igba akọkọ niyi ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ yoo wolẹ fun Ọbalaye kan?

Gẹgẹ bi atẹjade ti amugbalẹgbẹ aarẹ tẹlẹ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ fi sita ṣe sọ, O ni: "igba akọkọ kọ niyi ti aarẹ Obasanjo yoo maa wolẹ ki oriade."

O ni Obasabjọ bọwọ fun asa Yoruba pupọ ni.

Àkọlé fídíò, Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'

To ba ri bẹẹ, ẹ jẹ ka wo igba mẹta ọtọọtọ ti Oloye Ọbasanjọ ti bu ọwọ nla bayi fun awọn orilade:

1.Arole Oodua Ọọni Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja II ti ile Ifẹ.

Loṣu keji ọdun 2016 lẹyin osu kẹta ti Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi gun ori itẹ gẹgẹ bi Ọọni ti ilu ile Ife, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ bẹẹ wo.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @Obasanjo

Ninu aafin rẹ ni ile Oodua nilu ile Ifẹ ni Oloye Olusegun Obasanjo ti lọ ki i.

Gbogbo aya ni Oloye Oluṣẹ Ọbasanjọ da de ilẹ ti o si dọbalẹ kii lọjọ naa.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

2.Agura ti Gbagura, Abẹokuta.

Losu kẹjọ ọdun 2019, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ kan si Ọba Saburee Babajide Bakre to jẹ Agura ti Gbagura nilu Abẹokuta.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @Obasanjo

Tọwọtọwọ bi isẹ rẹ naa lo tun naa fẹlẹfẹlẹ niwaju kabiyesi Agura.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

3.Olu ti ilu Warri

Olu ti Ilu Warri, Ogiame Atuwatse kẹta ni ọba tuntun to ṣẹṣẹ jẹ lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ ọdun 2021.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @others

Nigba ti Oloye Õbasanjọ lọ kii ni afin rẹ lọ Aiku, erokun mejeeji lo fi kunlẹ kii.

Oloye Ọbasanjọ ko tẹti ninu ọla ati ọwọ ti o maa n fun awọn ọbalaye gẹgẹ bi ọmọ Yoruba tootọ.

Ninu aṣa Yoruba, gbogbo ọkunrin lo gbọdọ maa dọbalẹ fun oriade lainaani ọjọ ori tabi ọla tabi ọrọ ti irufẹ oriade bẹẹ ni.

Àkọlé fídíò, Wikipedia: Ẹ̀nìkan sọ fún mi pé iṣẹ́ ìdọ̀tí ni màá ṣe ni mo ṣe ń ta ìwé