Obi Cubana: Gbajúmọ̀ oníṣòwò ilé ijó, Obi Cubana ṣàlàyé ìgbésí ayé rẹ̀ àti bó ṣe di ẹni tí aráyé ń wárí fún

Oríṣun àwòrán, obi cubana
Gbajumọ olowo ile ijo ni, Obinna Iyiegbu ti ọpọ eeyan mọ si Obi Cubana ti ṣalaye gulegule ijọba lorilẹede Naijiria ṣe le oun lati inu kola-koṣagbe bs sinu ọrọ.
Laipẹ yii ni gbajumọ olowo ile ijo, Obi Cubana ṣe isinku iya rẹ Innyom Ezinne Uche Iyiegbu ni ilu Oba ni ipinlẹ Anambra eyi to di ilu mọọka kaakiri agbaye, amọṣa o ṣalaye fun BBC pe ki iṣu oun to di iyan, oju rẹ ri mabo lọwọ odo.
- Gómìnà Osun, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ sókè lórí wàhàlà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ife àti Modakeke lọ́jọ́ Ẹtì
- Búlọ́kù fẹ́ dá ìjà sílẹ̀ láàrín ìjọba àtàwọn olówò búlọ́kù ìpínlẹ̀ Ondo
- Ààrẹ tẹ́lẹ̀,GEJ, Atiku Abubakar,Fayemi ati àwọn mìíràn rèé tó péjú síbi ìgbéyàwó Yusuf Buhari
- Ìkáyàsókè ní Ife, Modakẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn tàwọn kan pa ọmọ Modakeke márùn ún
- Ọlọ́pàá mú afurasí tó pa oniṣowo ẹrọ igbowo POS kan, wọ́n ni àbọ̀dé ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho lọwọ́ tẹ̀ẹ́
Obi Cubana ni lootọ loni gbogbo agbaye lo mọ awọn ile ijo oun ti ko si fẹẹ si gbajumọ kan lorilẹede Naijiria, paapaajulọ nilu Eko ati Portharcourt ti ko na ibẹ ri ṣugbọn bii ile ounjẹ loun fi bẹrẹ ni ilu Abuja.
O ni gbọnmọgbọnmọ ijọba to n fi ojojumọ da oun laamu ti wọn n sọ pe ibi ti oun gbe ile ounjẹ oun naa si ni Abuja ko bojumu ni oun fi kuku fi ilu Abuja silẹ gba ilu Portharcourt ti oun si gba Portharcourt de Owerri.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Obi Cubana ṣalaye siwaju sii pe gbogbo bi awọn eeyan ṣe pariwo pe wọn ba owo ninu jẹ to lasiko isinku iya oun, oun ko le sọ ni pato iye owo ti wọn naa nibẹ nitori pe gbogbo bi wọn ṣe n na owo naa ni awọn n fi ṣe iranwọ fun awọn eeyan to ku diẹ kaato fun nibẹ lẹsẹkẹsẹ.
Bakan naa lo tun ṣalaye pe gbogbo maluu ti wọn pa fun isinku naa ko lounka to bẹẹ gẹl to jẹ pe oun ko lee ka wọn, bẹẹni awọn ko lee pa gbogbo maluu naa tan.
Gbajumọ onile ijo naa ni pupọ awọn maluu to ku ti wọn ko pa loun pin fun gbogbo awọn ọbalaye to wa si ibi isinku naa, oun si tun pin fun awọn mọlẹbi oun ni idile baba ati iya ti o si tun ku si agbala oun nile.
"Maluu ṣi n wọle fun mi o. Mo lọ si ipinlẹ Ẹbọnyi laipẹ yii, wọn tun fun mi ni maluu mẹtala nibẹ."
Nigba to n dahun ibeere lori idi to fi jẹ pe awọn oruks bii Opium, Pablo, Montana ati bẹẹbẹẹ lọ lo n sọ awọn ile iṣẹ rẹ gbogbo, Obi Cubana ni ile ijo ni awsn ileeṣẹ oun, nibi ti awọn eeyan ti lee maa sinmi lẹyin iṣẹ wọn nitori naa oun ko le maa sọ wọn ni ile ijo St Augustine lai kii ṣe ile ijọsin nitori naa loun fi n sọ wọn ni awọn orukọ bẹẹ.
Gbajumọ oniṣowo ile ijo naa wa pari ọrọ rẹ pẹlu pe ko si iṣẹ ti ọms oun kan ba fẹ ṣe ti oun ko ni tii lẹyin koda ko jẹ iru iṣẹ ṣiṣe akoso ile ijo bii toun ni smọ bẹẹ ba fẹ tẹle.
"Ọmọ mi ọdun mẹrin ni oun fẹ maa ya aworan mo si ṣetan ati tii lẹyin. Awọn ọmọ Davido ati Wizkid n kọrin. Akaimoye awọn aworan lo jẹ pe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni wọn n ta wọn. Melo ninu wa lo lee fọwọ sọya pe oun ni millionu kan dọla ri, ṣugbọn awọn ayaworan a maa pa owo yii pẹlu aworan wọn."














