POS operator murder: Ọlọ́pàá mú afurasí tó pa oniṣowo ẹrọ igbowo POS kan, wọ́n ni àbọ̀dé ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho lọwọ́ tẹ̀ẹ́

aworan apaniyan kan

Oríṣun àwòrán, other

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi kan ti orukọ rẹ n jẹ Kẹhinde Jẹlili fun pipa oniṣowo ẹrọ igbowo POS kan ti orukọ rẹ n jẹ Abiọdun Ọdẹbunmi ati awakọ Uber kan ti o n jẹ Idowu Ademiluyi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣalaye pe lẹyin oṣu mẹta ti wọn ti n wa Jẹlili, ti ọpọ mọ si Oluọmọ lọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ tẹẹ.

DSP Oyeyẹmi tun fi kun un pe ilu Cotonou lorilẹede Benin Republic ni afurasi naa ti nbọ lẹyin to lọ peju sibi igbẹjọ ọkan lara awọn aṣiwaju idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Igboho nibẹ.

O ni ọwọ ba afurasi naa pẹlu awọn afurasi apanijaye mẹta miran ti wọn pe orukọ wọn ni Abiọdun Akinọla, Johnson Fakẹyẹ ati Jamiu Akinọla. Wọn dana sun awọn dukia oloogbe Ọdẹbunmi naa lẹyin ti wọn ji miliọnu mẹrin lọwọ rẹ.

Bakan naa ni ọlọpaa tun gba ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry, Toyota Corolla ati Toyota Rave 4 tawọn afurasi naa gba lẹyin ti wọn pa awọn to ni ọkọ naa.

ki ni ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua sọ?

Àkọlé fídíò, Ondo state citizen killed in Jos: àwọn Fúlàní ìpínlẹ̀ Ondo tí wọ́n pa mọ̀lẹ́bí wọn ní

Amọṣa, ilana ọmọ Oodua to jẹ agbarijọpọ ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba ṣalaye pe awọn ọlọpaa kan fẹ sọ oloye Sunday Adeyẹms loruks buruku ni nipa siso iṣẹ afurasi ti wọn mu mọ igbẹjọ rẹ.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ ilana ọmọ Oodua ti Ọjọgbọn Banji Akintoye n dari rẹ, Maxwell Adelẹyẹ ṣalaye pe ko si afurasi naa tabi afurasi yoowu ṣe lee ls sibi igbẹjọ Oloye Sunday Igboho ni Cotonou nitoripe awsn adajọ atawọn mọlẹbi rẹ kọọkan ni wọn gba laaye lati wọ ile ẹjọ.

O niẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua kii ṣe ẹgbẹ awọn ọdaran bẹẹni kii faye gba ohun ija oloro lawọn iwọde rẹ.

O ni iṣẹlẹ iku ọdọbinrin Jumọkẹ ti wọn ba oku rẹ lasiko iwọde Yoruba nation nilu Eko ati bi ọlọpaa ṣe yi ohun pada lọpọ igba lori ọrọ naa fihan pe ileeṣẹ ọlọpaa nilo ati mojuto ara rẹ ati pẹlu pe wọn n gbiyanju ati ta ẹrẹ si aṣọ ala ijijagbara Yoruba Nation.

Àkọlé fídíò, Ohun ti Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sátánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́