Ibadan LG boss attack: Ẹgbẹ́ ALGON fún iléeṣẹ́ Immigration ní gbèǹdéke ọjọ́ kan láti fi ilé iṣé ìjọba ìbílẹ̀ Oyo sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, other
Ẹgbẹ ijọba ibilẹ, ALGON, ẹka ti ipinlẹ Oyo ti fun ajọ to n ri si wiwọle ati jijade awọn eeyan si orileede Naijiria, Nigeria Immigration Service (NIS) ni gbedeke wakati mẹrindilogun lati kaasa wọn kuro ni gbogbo ile iṣẹ ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Oyo.
Alaga ẹgbẹ ALGON l'Oyo, Họnọrebu Sikiru Sanda lo sọrọ yii fawọn akọroyin ni ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan.
Họnọrebu Sanda ni igbesẹ yii ko ṣẹyin ikọlu tawọn oṣiṣẹ NIS ṣe sí alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, Họnọrebu Sahib Yusuf.
- Láàrín ọdún méjì ₦3 bílíọ̀nù làwọn ajínigbé ti gbà nílẹ̀ Yorùbá, èèyàn 200 ni wọ́n sì ti pa- Gani Adams
- Èyí ni ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ tó gbé ìjọba Ekiti lọ síléẹjọ́ nítorí sẹ̀ríà tàwọn olùkọ́ rẹ̀ dá fún un sọ
- Mercy Aigbe kò le rìn torí ìjàmbá tó ní
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
Alaga ẹgbẹ ALGON l'Oyo ti wa kepe ọga agba ajọ NIS ni Naijiria pe lati ṣe iwadii iṣẹlẹ ọhun.
O ni awọn alaṣẹ ajọ NIS gbọdọ ri pe wọn fi awọn oṣiṣẹ wọn to fi iya jẹ alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan foju wina ofin.
Họnọrebu Sanda fikun ọrọ rẹ pe ajọ NIS gbọdọ tọrọ aforijin lọwọ alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, bi bẹẹ kọọ, ọrọ naa yoo dé ilé ẹjọ.
Nigba ti o b'awọn akọroyin sọrọ, Họnọrebu Yusuf ni oun ko ṣe ohun kan to le mu ki awọn oṣiṣẹ NIS dunkooko mọ oun.
Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan ni oun lọ yanju awọn ọrọ ọfiisi kan nile iṣẹ ajọ NIS ni ki wọn to ṣe ikọlu sí òun.
O ni ọrọ naa ko ba di nkan nla ṣugbọn oun ko fẹ da omi alaafia ipinlẹ Oyo ru ni.
Ara mi bó fẹ́lẹ-fẹ̀lẹ lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ immigration lù mí mọ́ ọfíìsì mi - Alaga Ibadan North
Gbẹgẹdẹ gbina lagbegbe Agodi nilu Ibadan nirọlẹ Ọjọru, ọjọ kejidinlogun osu kẹjọ ọdun 2021 nigba ti iroyin kan pe oṣiṣẹ ileeṣẹ wọlewọde orilẹede Naijiria kan ti di igbaju olooyi lu alaga kansu kan nilu Ibadan.
Nigba to n ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alaga ijọba ibilẹ Ibadan North, Shuaib Oladayo sọ pe kii ṣe iya diẹ ni awọn oṣiṣẹ ajọ immigration fi jẹ oun ni ọfiisi wọn.
Ọgbẹni sọ pe ẹnikan lara awọn kanselọ to wa ni ijọba ibilẹ naa lo gbọ ni ọfiisi awọn ajọ immigration pe awọn kan n fi ayederu lẹta ijọba ibilẹ naa ṣe aṣemaṣe ni ọdọ wọn.
O ṣalaye pe ẹsun naa ni oun fẹ ẹ lọ yanju, lati jẹ ko ye wọn pe kii sẹ ọdọ oun ni lẹta naa ti n wa, ki "oun to o kabuku".
- Ṣé mo jọ ẹni tó gba Benin Republic sá kúrò ní Nàìjríà ni? Lai Mohammed fèsí sí ìróyín pé Ó yọ́ kẹ́lẹ́ kúrò ní Nàìjíríà
- Gbogbo ṣọ́ọ̀bù àti ọjà yóò wà ní títì pa nílùú Akure nítorí ọdún Ahérégbé àti Amólè
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
- Ìpàdé ikọ̀ Amotekun pẹ̀lú àwọn aládúgbò ọmọ ọdún 15 tí wọ́n yìnbọn pa ní Mokola, ohun tí a gbọ́ níbẹ̀ nìyí
O ni awọn ti yanju ọrọ naa tan ni ọfiisi Ọga ajọ immigration, to si jẹ pe nibi ti oun ti n duro ni ita de kanselọ ti ọrọ kan ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan ti wa a ba oun pe ki oun kuro nibẹ.
"Mo kọkọ ro pe ọga wọn kan lo n bọ ni, kia ni mo si bọ si ẹgbẹ kan. Amọ, iyalẹnu lo jẹ pe wọn bẹrẹ si ni i fi i abuku kan mi.
"Ọga wọn kan pe mi lati tun ba wa yanju rẹ, ọfiisi rẹ loke si la wa ti mo fi sọkalẹ wa a wo awọn eniyan mi nitori ibẹru pe ija le ti bẹrẹ."
O ni aarin ija ni oun bọ si , to si jẹ pe bi oun ṣe n gbiyanju lati beere nkan to ṣẹlẹ ni awọn oṣiṣẹ immigration yabo oun.
Ọnarebu Oladayo sọ pe gbogbo ọwọ ati ẹsẹ oun lo bo fẹlẹ-fẹlẹ lasiko ti awọn oṣisẹ immigration lu oun ni alubami.
O ni ṣugbọn, oun ko fi ṣe ibinu lẹyin ti DPO ọlọpaa agbegbe Testing Ground ni Iwo-Road da si ọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, Shuaib Oladayo
O ṣalaye pe lootọ ni awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa fi ibinu sọ pe awọn ko ni i jẹ ki awọn oṣiṣẹ immigration gbe awọn ọkọ wọn to wa ninu ọgba ijọba ibilẹ naa jade nigba ti awọn oṣiṣẹ pari iṣẹ ọjọ naa, ṣugbọn oun ba awọn eniyan oun wi, lẹyin ti DPO ọlọpaa tun pe oun.
"Koda, taya ọkọ ẹnikan lara wọn ti awọn eeyan mi ti jò, mo pe fọganaisa lati fẹ ẹ.
"Ibi ti mo ti n ba fọga sọrọ, ẹyin ni mo kọ si awọn to ku. Bẹẹni ẹnikan lara awọn oṣiṣẹ immigration sare si mi. Bi ede aiyede ṣe bẹrẹ niyii, pe ṣe wọn tun fẹ ẹ wa na mi ninu ọfiisi mi ni.
O tẹsiwaju lati sọ pe bẹẹ ni awọn oṣiṣẹ immigration naa bẹrẹ si ni i yinbọn ati afẹfẹ taju-taju ni ẹnu ọna ijọba ibilẹ.
Ninu fidio to fi ranṣẹ si BBC, iro ibọn n dun lakọlakọ, ti awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn.
Nigba ti BBC kàn si agbẹnusọ ajọ immigration nipinlẹ Oyo, sọ pe oun ko le sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.
O ni idi ni pe oun ko ti i gba aṣẹ lati sọrọ, ati pe oun wa ni ileewosan ti oun ti n gba itọju nitori ọgbẹ ti oun gba lasiko wahala naa.
Kini iroyin kọkọ sọ nipa iṣẹlẹ naa?
Gbẹgẹdẹ gbina lagbegbe Agodi nilu Ibadan nirọlẹ Ọjọru, ọjọ kejidinlogun osu kẹjọ ọdun 2021 nigba ti iroyin kan pe oṣiṣẹ ileeṣẹ wọlewọde orilẹede Naijiria kan ti di igbaju olooyi lu alaga kansu kan nilu Ibadan.
Awọn oju mi too kan ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye pe agbegbe ile ijọba Government house to wa ni Agodi ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lasiko ti alaga ijọba ibilẹ ariwa Ibadan, Họnọrebu Shuaib Ọladayọ pẹlu obinrin kan lọ gba iwe irinna silẹ okeere nileeṣẹ iwọle wọde Naijiria to wa nibẹ.
- Gbogbo ṣọ́ọ̀bù àti ọjà yóò wà ní títì pa nílùú Akure nítorí ọdún Ahérégbé àti Amólè
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
- Ìpàdé ikọ̀ Amotekun pẹ̀lú àwọn aládúgbò ọmọ ọdún 15 tí wọ́n yìnbọn pa ní Mokola, ohun tí a gbọ́ níbẹ̀ nìyí
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ikú èèyàn méje nínú ẹbí kan
O tẹsiwaju pe pipe ti oṣiṣẹ Ileeṣẹ wọlewọde naa pe alaga kansu naa pe ibi to gbe ọkọ rẹ si ko bojumu to ati pe yoo ṣe idiwọ fun lilọbibọ ọkọ nibẹ lo mu ki ki Họnọrebu Shuaib o gbara ta.
Iroyin sọ pe alaga naa ke sawọn janduku kan lati lu awọn oṣiṣẹ wọlewọde naa eleyi to mu ki awọn pẹlu o lọ dira wa pẹlu awọn akẹgbẹ ti ọrọ fi di boolọ o ya fun mi.
Lasiko ti a fi ko iroyin yii jọ, a ṣi n tiraka lati kan si Họnọrebu Shuaibu ati ileeṣẹ wọlewọde Naijiria, Nigeria Immigration Service, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ.















