Ìgbẹ́jọ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn olùkọ lú ní Ekiti tí bẹ̀rẹ̀, agbẹjọ́rò ní àfi kí ìjọba sàn 15mílíọ̀nù owó gbà má bínú

Oríṣun àwòrán, Google
Agbẹjọro to n soju ọmọ ọdun mẹjọ Gift Agenoisa ti wọn lu lẹgba nile ẹkọ Mary Immaculate Secondary School , Ado- Ekiti ti sọ pe awọn ko ni yẹ titi ti Gift yoo fi gba idajọ to yẹ.
Owo gbaa ma binu miliọnu mẹẹdogun ni awọn obi Gift n beere fun lọdọ ijọba ipinlẹ Ekiti ti wọn si fẹ ki wọn faaye gba ọmọ naa lati pada sile ẹkọ.
Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC agbẹjọro Gift Timmy Omotoso,sọ pe yatọ si pe awọn olukọ lu ọmọde naa, wọn tun sọ fun pe ko ma pada wa si ile ẹkọ naa mọ.
- Ayédèrú sọ̀wédowo lọ̀gá àgbà ọlọ́pàá fún wa, pọ́ún ló ń ta bí a bá múu dé báǹkì
- Mercy Aigbe kò le rìn torí ìjàmbá tó ní
- Ara mi bó fẹ́lẹ-fẹ̀lẹ lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ immigration lù mí mọ́ ọfíìsì mi - Alaga Ibadan North
- Gómìnà ìpínlẹ̀ kan rèé tó ní kí aráàlú ó lọ ra ìbọn láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn agbébọn
O ni nitori pe awọn ko fẹ ki ẹtọ rẹ di titẹmọlẹ lẹyin ti ile ẹkọ ko jẹ ko pada si kilasi lo mu ki awọn gba ile ẹjọ lọ.
O ṣalaye pe awọn gbiyanju pupọ lati kan si ijọba ipinlẹ Ekiti, iyawo Gomina, ati ileeṣẹ eto ẹkọ lati yanju ọrọ yi ṣaaju ṣugbọn pabo lo ja si.
Agbẹjọro Omotosho ni igbẹjọ ti bẹrẹ awọn si ni ireti pe ire lawọn yoo mu dari bọ lati ile ẹjọ.
''Adajọ ti bẹrẹ si ni gbẹjọ wa ṣugbọn wọn ti sunjọ igbẹjọ si ọjọ kejilelogun oṣu kẹsan ti wọn ni ka tun pada si ile ẹjọ.''
Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju ree
Gẹgẹ bi agbẹjọro Omotosho to tun jẹ ajafẹtọmọniyan ti ṣe sọ,lọjọ ti Gift yoo pe ọdun mẹjọ ni awọn olukọ da sẹria fun pe o ṣe irun ti ko bofin mu wa sile ẹkọ.
O ni wọn lu ni ẹgba ogun titi de bi pe gbogbo ara rẹ bo ti Gift si pada wa daku.
''Wọn ko ẹgba yẹn bo lori ara debi pe o ni ifarapa lẹyin, ni ọwọ ati aya.Nigba ti ifarapa yẹn wa pọ fun, niṣe lo daku''

Oríṣun àwòrán, Ekiti State Government
Omotosho ni nigba tawọn ile ẹkọ ri wi pe Gift ti daku ni wọn to ṣẹṣẹ pe obi rẹ lori ago pe ki wọn wa si ile ẹkọ.
O ni abalọ ababọ ni pe wọn gbe Gift pada lọ si ile lati lọ tọju rẹ ṣugbọn o jẹ iyalẹnu pe nigba ti ara rẹ ya to fẹ pada si ile ẹkọ, awọn alaṣẹ ileewe ko gbaa laaye.
Agbẹjọro ni awọn gbiyanju lati kan si ileeṣẹ eto ẹkọ, iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti ati ileeṣẹ to n mopjuto ọrọ obinrin ati ọmọde.
Gẹgẹ bo yti ṣe ṣalaye ileeṣẹ to n mojuto ọrọ obinrin ati ọmọde nikan lo kan si awọn pada lori ọrọ yi.
''Ọmọ ọdun mẹjọ ti ko mọ nkankan ni akẹkọọ ti awọn olukọ yi lu laludaku.Se ọmọ yi lomu owo lọwọ ara rẹ lọ si ile gẹrigẹri pe ki wọn ge irun fun ni?ṣebi ti ọmọ ba ṣe ṣe ko yẹ ki wọn pe awọn obi rẹ lati fẹjọ sun ni?''














