EndSARS: Àwọn ìyàwó àwọn ọlọ́pàá tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS ní sọ̀wédowo tí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá fún wọn kò gbówó jáde ní báǹkì

Aworan diẹ lara awọn ọlọpa to ku naa

Oríṣun àwòrán, livetimesng.com

Awọn iyawo awọn ọlọpaa to kagbako iku ni ipinlẹ Ọyọ lasiko iwọde EndSARS ti pariwo sita lori airi owo sọwedowo ti ijọba fun wọn gba gẹgẹ bi owo gba ma binu lori iku awọn baale wọn.

Loṣu kẹwaa ọdun 2021 ni awọn ọlọpaa yi padanu ẹmi wọn ti ijọba si fun mọlẹbi kọọkan ni sọwedowo ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun naira (N500,000).

Gẹgẹ bi wọn ti ṣe sọ fun BBC, gbogbo igba tawọn ba ti de banki lati gba owo naa, niṣe ni iwe naa maa n ta paupau lori ẹrọ ile ifowopamọ.

Ninu ọrọ ti wọn sọ nibi ipade kan ti wọn pe nilu Ibadan, wọn ni iwe sọwedowo ti n fori ko jankariwọ ninu ile nitori ko fẹ ẹ wulo fawọn.

Wọn tsiwaju pe lati igba ti ọga ọlọpaa ti fun awọn ni iwe wọn yi lati oṣu kini ọdun 2021, ijakulẹ lawọn n ba pade ni banki ni gbogbo igba.

Wọn wa ke si aarẹ Muhammadu Buhari pe ko boju wo awọn ko bawọn dide si ọrọ naa nitori iya to n jẹ awọn lati igba ti awọn ọkọ wọn ti jade laye lẹnu iṣẹ wọn ko lẹgbẹ rara.

Awọn ọlọpaa marun un lawọn janduku pa nipinlẹ Ọyọ lasiko iwọde EndSARS ti ọpọlọpọ miran si fara ṣeṣe.

Awọn ọlọpaa to ku nigba iwọde naa ni ipinlẹ Ọyọ ni Adegoke Ajibọla, Rotimi Ọladele, Peter Abegunde, James Akanmu ati Alidu Yusuf Wada.

Àkọlé fídíò, Ilé wó lu Bisi, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kú, wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ tó ń jẹrà, inú ìrora ló wà ṣùgbọ́n