Aheregbe festival: ọdún Ahérégbé àti Amólè bẹ̀rẹ̀ lónìí l'Akure, Déjì ní kí wọ́n tí gbogbo ọjà pa

Awọn ijoye a maa ṣe abẹwo si aafin Deji Akure

Ọdọọdun ni ọdun Ahérégbé àti Amólè maa n waye nilu Akure ti tọdun yi ko si yatọ si tatẹyinwa.

Niṣe lawọn araalu bọwọ fun aṣẹ ti Deji pa pe ki wọn ma ṣe ṣi ṣọọbu itaja.

Die ree ninu awọn aworan binkan ti ṣe lọ nibi ọdun yi ni Akure.

Aworan ile itaja to wa ni titipa ni Akure
Aworan ile itaja to wa ni titipa ni Akure
Aworan ile itaja to wa ni titipa ni Akure

Paroparo lawọn ile itaja ni Ọja Oba ti tẹlẹ da ti ko si si karakatra kankan to n waye nibẹ.

Ki gbogbo nkan baa le lọ leto leto, awọn eeyan kan a maa kaakiri lati ri pe awọn eeyan tẹlẹ aṣẹ yi.

Ẹnikẹni ti wọn ba ri to ṣi ṣọọbu, wn a maa ko ọja rẹ ti ko si ni si nkankan ti yoo tẹyin rẹ bọ.

Awọn ijoye a maa ṣe abẹwo si aafin Deji Akure
Awọn ijoye a maa ṣe abẹwo si aafin Deji Akure

Oríṣun àwòrán, BBC Sport

Awọn ijoye a maa ṣe abẹwo si aafin Deji Akure

Lara awọn eto to maa n waye nibi ọdun naa ni pe awọn ijoye yoo ṣe abẹwo si Deji ilu Akure.

Gbogbo ṣọ́ọ̀bù àti ọjà yóò wà ní títì pa nílùú Akure nítorí ọdún Ahérégbé àti Amólè

Deji ti ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi ti ni ki wọn ti gbogbo awọn ile itaja ati ṣọọbu to wa nilu naa nitori ọdun Aheregbe ati Amole ti yoo waye.

Awọn ọdun naa yoo waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, ati ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 yii kan naa .

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ori ade naa, Adeyeye Michael fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni igbesẹ naa ṣe pataki ki wọn le raye ṣe ọdun naa to maa n waye lọdọọdun.

Lasiko ọdun ọhun ni awọn agbagba ilu Akure maa n gbadura fun alaafia ilu naa, to fi mọ ilu Oba Ile, eyii ti ko fi bẹẹ jina si Akure.

Ko ni si kata-kara ninu awọn ilu memeji lasiko ti ọdun Aheregbe ati ọdun Amole yoo maa waye.

Ẹnikẹni to ba taja ni ayajọ ọdun naa le padanu ọja rẹ nitori awọn to n kaakiri ilu lati ri daji pe ọdun naa bo ṣe yẹ ko lọ le ko ọja irufẹ ẹnio bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ilé wó lu Bisi, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kú, wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ tó ń jẹrà, inú ìrora ló wà ṣùgbọ́n

To n tumọ si pe awọn to n kaakiri naa laṣẹ labẹ aṣa ilu Akure lati ko tabi gbẹsẹ ọja irufẹ oniṣowo bẹẹ.

Bakan ni ilu yoo ko iṣọwọ awọn miran si aarin igboro pẹlu paṣan lọwọ ti wọn a si maa ko paṣan bo ẹnikẹni to ba tapa si ilana to rọ mọ ọdun ọhun, bii ṣiṣi ṣọọbu.

Ṣaaju ni oloye Aṣamọ ti ilu Akure ti kọkọ sọ fun awọn akọroyin pe ọdun naa ṣe pataki niluu Akure ki alafia le jọba ninu ilu naa.

O fi kun pe ko pọju ti wọn ba ya ọjọ meji pere sọtọ laari n ọdun kan lati ṣe ọdun fun alaafia awọn araalu.