Mushin cultist attack: Dúkìá olówó iyebíye ṣòfò lásìkò ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn l'Eko

Mushin attack
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Inu ibanujẹ ati iporuru ọkan ni awọn eeyan adugbo Akinbode, to wa ni Mushin, nipinlẹ Eko wa bayii lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan kọlu adugbo naa.

Akọroyin BBC to ṣabẹwo si adugbo naa jabọ pe iṣẹlẹ ọhun waye ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Aje.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, aarọ ọjọ Aje ni ija kan kọkọ waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ki awọn ọlọpa to pana aawọ ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Aje kan naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun tun pada wa lati kọlu adugbo naa.

Lara awọn nnkan ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ṣe ni bi wọn ṣe dana sun ọpọ ṣọọbu, kẹkẹ Maruwa, ti wọn si tun ja awọn eeyan agbegbe naa lole.

Mushin attack

Ti kii ba ṣe igbiyanju awọn ọdọ adugbo naa, o ṣeeṣe ki nnkan bajẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Gẹgẹ bii ohun ti akọroyion BBC Yoruba foju ri, yatọ si awọn ṣọọbu ti wọn dana sun, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa tun ba ọpọlọpọ ọkọ to wa ni adugbo naa jẹ.

Oṣiṣẹ eto abo kan ti BBC ba sọrọ ṣalaye pe awọn ti gbọ iroyin pe awọn awọn eeyan to ṣe ikọlu naa tun ti n ko ara wọn jọ lati pada ṣọṣẹ.

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Ọkan lara awọn ti ṣoọbu wọn jona ninu iṣẹlẹ naa ṣalaye fun BBC pe gbogbo igba ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa maa n ja ladugbo ọhun.

Obinrin naa sọ pe ẹran tolotolo ni oun n ta ti ọja si kun inu ṣọọbu oun bamu, ṣugbọn o ṣeni lanu pe gbogbo ọja naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa jo nina.

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Ẹlomiran to tun ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe oriṣiriṣi ohun ija oloro ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ko lọwọ lati wa ṣọṣẹ.

Wọn ṣalaye fun BBC pe yatọ si pe wọn da adugbo naa ru ti wọn tun jo awọn ṣọọbu nina, wọn tun wọ inu iyẹwu awọn eeyan adugbo naa ti wọn si ja wọn lole.

Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko fi lede, wọn ni awọn gbiyanju lati pa ina to sọ lara awọn ṣọọbu adugbo naa, ṣugbọn awọn ọdọ adugbo ọhun ko fun awọn laaye lati ṣisẹ nitori wọn n binu lasiko ti awọn de ibẹ.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ