Who are the Talibans: Àwọn wo gan ni Taliban to da ojú ìjọba bolẹ̀ ní Afganistan?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun 2001 ni awọn ọmọ ogun Afganistan ni adehun pẹlu ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika le Taliban kuro lori ijọba ilẹ naa, ṣugbọn laarin oṣu diẹ ni Taliban bẹrẹ awọn ikọlu kan pẹlu erongba lati gba ijọba pada lọwọ ijọba.
Lẹyin ogun ọdun ni Afganistan, ilẹ Amẹrika pinnu lati ko gbogbo jagunjagun rẹ kuro nilẹ naa titi oṣu Kẹsan an ọdun yii.
Ni 2018, Taliban ni ijiroro pẹlu ijọba Amẹrika, ṣugbọn nigba ti yoo fi di oṣu Keji ọdun 2020, awọn mejeji wọnu adehun alaafia niluu Doha, eyii to n tumọ si pe ijọba Amẹrika yoo ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni Afganistan.
Adehun naa tun sọ pe ikọ Taliban ko ni ṣe ikọlu si ikọ ọmọ ogun Afganistan mọ, bakan naa ni Taliban ko ni de awọn agbegbe kan ti wọn jọjọ fọwọ si ninu adehun ọhun.
Ṣugbọn lẹyin ọdun kan, Taliban bẹrẹ si n kọlu awọn ọmọ ogun ilẹ Afganistan atawọn eeyan ilu, eyii to mu ki Taliban ni ilọsiwaju ninu akitiyan rẹ lati ja ijọba gba.
Bi Taliban ṣe de ijọba
Nnkan bii ibẹrẹ ọdun 1990 ni wọn da Taliban silẹ lagbegbe oke ọya orilẹ-ede Afganistan lẹyin ti awọn ọmọ ogun Soviet Union fi ilẹ naa silẹ.
Iroyin ni wọn bẹrẹ pẹlu awọn eto ẹsin, eyii ti ilẹ Saudi Arabia n ṣagbatẹru rẹ lọdun naa lọhun nibi ti wọn ti maa n waasu nipa eṣin Sunni, to jẹ apakan ẹsin Islam.
Lọdun naa lọhun, Taliban ṣeleri lati da alaafia pada si agbegbe Pashun, eyii ti ko jina si ala Pakistan ati Afganistan, wọn si tun ṣeleri pe awọn yoo ri daju pe ofin Sharia to ba ẹsin Islam mu ni awọn yoo maa lo latio dari ilu ti awọn ba de ori alefa.


Lati Guusu iwọ-oorun Afganistan, Taliban bẹrẹ si n gbajumọ siwaju si. Ni 1995, wọn gba agbegbe Herat to jẹ ala Iran, lẹyin ọdun diẹ si wọn tun gba olu ilu ilẹ naa, iyẹn Kabul lẹyin ti wọn ti kọkọ rọ Aarẹ Burhanuddi Rabani loye.
Nigba ti yoo fi di ọdun 1998, Taliban ti n dari nnkan bii ida aadọrin ilẹ naa.
Awọn eeyan ilẹ naa kọkọ tẹwọ gba ijọba Taliban nitori wọn gba wọn lọwọ wahala awọn mujahideen, wọn si tun ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa lati gbogun ti iwa ajẹbanu.
Ṣugbọn Taliban gbe awọn ofin tuntun kan kalẹ labẹ ofin Sharia, bii ki wọn maa bẹ apaayan lori, ki wọn maa ge ọwọ awọn to ba jale, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni Taliban tun fofin de tẹlifiṣọn wiwo, gbigbọ taka-sufe, lilọ si ile sinima, bẹẹ ni wọn ko tun faye gba ọmọbinrin ti ọjọ ori rẹ ko tii pe mẹwaa lati maa lọ sile ẹkọ.
Nigba to ya, awọn araalu bẹrẹ si n fẹsun kan Taliban pe wọn n tẹ ẹtọ awọn eeyan loju mọlẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe orilẹ-ede Pakistan n sẹ pe oun ko lọwọ ninu iṣẹjọba Taliban, o wa lara awọn orilẹ-ede to tẹwọ gba ẹgbẹ naa, toun ti Saudi Arabia ati United Aran Emirates, UAE.
Nigba to ya, Taliba n dukoko mọ Pakistan pe oun yoo da oju ijọba rẹ bolẹ lagbegbe Ariwa-iwọ-oorun rẹ.
Ni 2021, Taliban yinbọn lu Malala Yousafzai, to jẹ ọmọ ilẹ Pakistan lasiko to n bọ lati ilu Mingora.
Lẹyin ọdun meji si asiko naa ni Taliban kọlu ile ẹkọ kan lagbegbe Peshawar.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibugbe fun ẹgbẹ Al-Qaeda
Ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ Taliban nitori atilẹyin ti wọn ṣe fun ẹgbẹ agbesumọmi Al-Qaeda lẹyin ti wọn kọlu ile itaja agbaye, World Trade Center lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2011.
Ninu oṣu Kẹwaa ọdun kan naa ni ijọba Amẹrika ko ọmọ ogun rẹ lọ si Afganistan to si bẹrẹ si n kọlu awọn ọmọ ogun Taliban, eyii to da oju ijọba ẹgbẹ naa bolẹ to si le ẹgbẹ naa kuro lori iṣejọba orilẹ-ede ọhun.
Ninu awọn ikọlu ọhun ni Amẹrika ti mu awọn adari ẹgbẹ naa bii Mullah Mohammad Omara ti Osama Bin Laden.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ogun ilẹ okeere pọ ni Afganistan, ẹgbẹ naa gbiyanju lati gba ijọba pada, eyii to da orilẹ-ede ọhun pada sinu ibẹru bojo ti awọn eeyan rẹ ko tii ri lati ọdun 2001.

Oríṣun àwòrán, AFP
Lọdun 2016, ijọba Amẹrika ṣekupa Mullar mansour to jẹ ọkan pataki lara aọn olori ẹgbẹ naa, ṣugbọn ẹgbẹ ọhun fi igabkeji rẹ, Mawlawi Hibatullah Akhundzada rọpo rẹ, oun ṣi ni olori naa titi di oni.
Bi Amẹrika ṣe fi Afganistan silẹ
Lẹyin ti Taliban tọwọ bọwe alafia pẹlu ọmọ ogun ilẹ okeere lọdun 2020, wọn dẹwọ igbogun ti awọn ohun meremere ati ile ijọba laari ilu, ṣugbọn wọn bẹrẹ si n ṣekupa awọn eekan ilu.
Lara awọn eekan ti wọn wọn n doju ija kọ ni awọn akọroyin, adajọ, ajafẹtọ ọmọniyan, awọn obinrin to di ipo agbara mu, eti bẹẹ lọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan n kọminu lori aṣeyọri ti Taliban n ṣe ni Afganistan, Aarẹ Amẹrika, Joe Biden kede ninu oṣu Kẹrin ọdun 2021 pe oun yoo koo gbogbo ọmọ ogun ilẹ Amẹrika kuro lorilẹ-ede naa ko ti di ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun kan naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ọpọ ọdun ti Amẹika ti n gbogun ti Taliban, Taliban bẹrẹ si n ṣaṣeyọri ni bo ṣe n gba awọn agbege kan pada lọwọ ijọba ilẹ naa lẹyin ti Amẹrika yọ ọwọ rẹ kuro ninu ogun ọhun.
Ni bayii, ọpọ eeyan lo gabgbọ pe agbara ti Taliban ni lọwọ ti pọ ju idiyele agbara ti wọn ni lọdun 2001, ni bi wọn ṣe ni ẹgbẹrun marundinlaadọrun un ọmọ ogun ni ikawọ gẹgẹ bii Nato ṣe sọ.
Itẹsiwaju naa pọ to bẹ ti adari ikọ ọmọ ogun Amẹrika si Afganistan, Austin Miller fi sọ pe, o ṣeeṣe ki ogun abẹlẹ bẹ silẹ lorilẹ-ede ọhun.
Ẹwẹ, pupọ ninu awọn ilu ti Taliban gba ni ko lọwọ ija ninu lẹyin ti awọn ọmọ ogun Afganistan jọwọ ohun ija wọn ki awọn alaiṣẹ ma baa ba ija ọhun lọ.
Bakan naa, iroyin kan lati ilẹ Amẹrika ti sọ ṣaaju pe o ṣeeṣe ki Taliban gba ijọba Afganistan laarin oṣu mẹfa ti Amẹrika ba le ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro nilẹ ọhun.












