Sunday Igboho: Agbẹjọ́rò rẹ̀ ní àwọn ọlọ́pàá rò pé ajìjàgbara náà yóò di ológbò tàbí pòórá ní àhámọ́, ni wọ́n ṣe só lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho
Asiri ti tu lori idi ti wọn fi so ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho lọwọ ati ẹsẹ ni ahamọ ọlọpaa to kọ wa nilu Cotonou, ki wọn to gbe lọ si ọgbọ ẹwọn.
Olusegun Falola, tii se ọ̀kan lara awọn agbẹjọro Igboho lo tu asiri naa sita fawọn akọroyin.
Falola ni awọn ọlọpaa ilẹ Benin ti gbọ nipa agbara ajijagbara naa, ti wọn si lo le di ologbo, tabi ko poora.
O ni idi ree ti wọn se fi ẹ̀wọ̀n so mọlẹ ni ọwọ ati ẹsẹ, ko maa ba raye poora gẹgẹ bo se maa n se ni ahamọ awọn ọlọpaa naa.
"Nigba ti mo kọkọ de lati ilu Paris lọ wo Sunday Igboho ni ahamọ to wa, wọn so ni ọwọ ati ẹsẹ ni.
Iroyin ti tan de etigbọ awọn ọlọpaa ni orilẹede Benin nipa akanda ẹda ti Sunday Igboho jẹ, ti wọn gba pe o le di ologbo tabi ko sadede poora lojiji.
Ẹru si n ba awọn ọlọpaa naa nipa agbara ti Igboho ni, wọn ni tawọn ba fi tu ẹwọn lọwọ rẹ, to si salọ, wọn gba isẹ lọwọ ọlọpa to wa lẹnu isẹ tabi ki wọn se adinku okun apa rẹ.
- Oníkẹ̀kẹ̀ 'Maruwa ló dóòlà ẹ̀mí bí bẹ́ẹ̀ kọ́ mí o ba tí bá iṣẹ̀lẹ̀ Jos lọ
- Ọjọ́ burúkú, ọjọ́ ìbànújẹ́ ní òní jẹ́ fún wa lágbègbè Niger Delta - PANDEF
- Àwọn agbébọn gbé akẹ́kọ̀ọ́ 15 ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ni Zamfara, wọ́n tún pa èèyàn mẹ́rin
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ń dáàbò bo ara yín lọ́nà ìbílẹ̀ - Elebuibon
- Buhari, tètè mú ọ̀kan nínú ìdásílẹ̀ Yoruba Nation àbí ìjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn - Gani Adams
- Ẹ̀yin ajìjàgbara orílẹ̀èdè Yoruba àti Biafra, òfo ní aáyan yín - Abdulsalam Abubakar
Gẹgẹ bo se wi, bi oun se tete se abẹwo si lati da si ọrọ naa lo mu ki wọn tu sẹkẹsẹkẹ ọwọ ati ẹsẹ rẹ.
Wayi o, Agbẹjọro naa tun ti sisọ loju idi ti wọn ko se tii fi Synday Igboho silẹ ni ahamọ to wa nilu Cotonou."
Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe o seese ki wọn ti gba ẹmi ajijagbara naa, to ba se pe awọn ijọba ilẹ Benin fi silẹ loju ẹsẹ ni.
















