Osun Osogbo festival 2021: Ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí nìkan kò lè ṣé, ẹ dáàbò bo ara yín lọ́nà ìbílẹ̀ - Elebuibon

Elebuibon

Oríṣun àwòrán, arabaosogbo1

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Araba awo ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ti ke si awọn ọmọ Yoruba lati bẹrẹ si n dabo bo ara wọn ni ọna ibilẹ lọwọ awọn ti wọn ba fẹ da ẹmi wọn legbodo.

O ni asiko ti to fun awọn ọmọ Yoruba lati maa lo ọna ibilẹ lati dabo bo ara wọn yatọ si lilọ ile ijọsin tabi Mọṣalaṣi fun adura gbigba.

Elebuibon lo sọ ọrọ naa nibi ọdun Osun Osogbo ti ọdun 2021.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Araba awo ilu Osogbo naa sọ pe asiko ti to fun iran Yoruba lati ṣe awari ati amulo awọn aṣa ati iṣe ti Eledua fi da wọn lọla.

O ni "Asiko ti to ki awọn eeeyan ṣe awari ara wọn, a si ni lati ṣe igbeleke awọn aṣa ati iṣẹ ti Eledumare fun wa."

"Osun jẹ ọkan lara awọn aṣa ti Eledumare fun wa, mo si gba awọn ọmọ Yoruba niyanju lati ji giri si awọn aṣa ati iṣẹ wa lọna ati le maa ba Eledumare sọrọ."

Àkọlé fídíò, Wikipedia: Ẹ̀nìkan sọ fún mi pé iṣẹ́ ìdọ̀tí ni màá ṣe ni mo ṣe ń ta ìwé

Elebuibon pari ọrọ rẹ pe "A ni lati ji giri ki a si maa dabo bo ara wa lọna ibilẹ, kii ṣe ki a kan maa lọ si ṣọọṣi ati ati Mọṣalaṣi nikan lati maa gbadura, a gbọdọ bẹrẹ si n lo ilana ibilẹ."

Ọpọ ero kaakiri Naijiria lo peju sibi ọdun Osun Osogbo naa bo tilẹ jẹ pe arun Covid-19 n ba gbogbo agbaye finra.

Lara awọn eeyan jankan-jankan nilẹ Yoruba to peju sibi ọdun naa lọdun yii yatọ si Elebuibon ni Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, awọn ọba alaye, atawọn eeyan nla nla mii.

Àkọlé fídíò, Oladuni Giwa-Osagie: Òrùka mẹ́fà ní ọkọ́ mi fi bèèrè láti fẹ́ mi lẹ́ni ọdún 47