Petrol Price: Sylva ní ẹ̀fẹ̀ ní àbá àwọn gómìnà tó dábàá èlé owó epo àmọ́ ìjọba yóò jíròrò pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́

Ile epo

Oríṣun àwòrán, IPMAN

Ijọba apapọ Naijiria tun ti tẹnumọ pe oun ko ni pinnu lori iye ti lita epo tẹtirolu yoo jẹ afi to ba fẹnu ọrọ jona lori rẹ pẹlu ẹgbẹ osisẹ nilẹ wa.

Saaju ni ẹgbẹ awọn gomina ti kọkọ dabaa pe ki lita epo kan wa laarin ọrinlelọọdunrun naira (N380) si irinwo ati mẹjọ naira (N405) amọ tijọba ko tii buwọlu.

O wa yan pe owo lita epo yoo si wa bo se wa, titi tawsn ẹgbẹ osisẹ yoo fi pari ijiroro wọn pẹlu ijọba lori iye to yẹ ki owo lita epo kan jẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti Minisita abẹle fun ọrọ epo rọbi, Timipre Sylva fisita ti wa salaye pe lita epo petrolu kan ko le kọja naira mejilelọgọjọ (N162) si naira marunlelọgọjọ (N165) lẹyin ipade naa.

"O se dandan ka fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ijọba apapọ ko kanju lati fi owo kun owo lita epo pẹtirolu, ko le ba iye ti wọn n ta epo lọja agbaye bayii.

Àkọlé fídíò, Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Bi owo epo se wa lati osu Kẹfa ọdun yii naa ni yoo wa titi ta fi pari ifikunlukun wa pẹlu ẹgbẹ osisẹ.

Ọ si pọn dandan ka se alaye yii nitori iroyin kan to n lọ kiri nipa ipinnu ẹgbẹ awọn gomina to dabaa afikun owo lita epo pẹtirolu kan.

Mo wa n rọ awọn alagbata epo lati mase sọ owo ọja wọn di ọwọn tabi ti ileepo wọn pa, ki ọwọn gogo epo le wa fun araalu."

Amin iyasọtọ kan

Àwọn 'Task Force' ìpínlẹ Eko ti ilé ìta oògùn ogún ní Shomolu, Bariga àti Oworonshoki

aworan ile oogun kan ti wọn ti pa

Oríṣun àwòrán, other

Àwọn 'Task Force' ìpínlẹ Eko ti ilé ìta oògùn ogún ní Shomolu, Bariga àti Oworonshoki

Kọmisọnna fun eto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi ti fi atẹjade sita lori awọn ile itaja oogun ti wọn ti pa.

O ni idi pataki ti wọn fi gbe awọn ile itaja oogun naa ti pa ni nitori pe wọn ko tẹle ofin to ni i se pẹlu tita oogun ni ipinlẹ Eko.

Abayomi ni awọn miran tun n fi nkan mii kun oogun tita ni eyi ti wọn ko dẹ ni agbara lati maa se ni eyi to tako ofin.

Àkọlé fídíò, Oladuni Giwa-Osagie: Òrùka mẹ́fà ní ọkọ́ mi fi bèèrè láti fẹ́ mi lẹ́ni ọdún 47

Ojọgbọn Abayomi ni titi awọn ile itaja oogun yii tọna labẹ ofin Section C34 to lodi si ayederu oogun ati awọn igbesẹ aitana lori ohun jijẹ ti Naijiria tọdun 1999.

O tun ni awọn ile itaja oogun ti ọrọ kan mii sẹlẹ nitori pe wọn ko ni aaye a n ko oogun pamọ si lọna to yẹ nigba ti awọn miran ko ni iwe ominira lati maa ta oogun bẹẹ ni awọn mii ni awọn oogun to ti bajẹ ti ọjọ ti lọ lori wọn lori igba.

Àkọlé fídíò, Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Bakan naa ni Abayomi ni awọn mii ni oogun ti ko yẹ ki wan ni lori igba lasiko ayẹwo ijọba sile itaja wọn ni ipinlẹ Eko.

O salaye lori awọn to ni asẹ lati ta ẹyọ ẹyọ ati awan to ni asẹ lati ta oogun ni pali ni pali.

Bakan naa lo ni ijọba ipinlẹ Eko yoo tẹsiwaju lati maa ko ayederu oogun kuro nilẹ ati lati maa se ayẹwo to yẹ fun awọn ile itaja oogun ki ọkan ara ilu le tubọ balẹ sii lori eto ilera wọn.

Àkọlé fídíò, Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú