Covid-19 Delta variant Update: Ẹ̀dà Delta Variant COVID-19 ń gbèrú síi ní Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ra abẹ́rẹ́ àjẹsára 176,000

Oríṣun àwòrán, other
Bi ọwọ kẹta ajakalẹ arun COVID-19 tun ti ṣe n gbilẹ sii lorilẹede Naijiria, ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti sọ pe ẹda kokoro arun naa ti wọn n pe ni Delta variant ti n gbilẹ sii lorilẹede Naijiria bayii ati pe lojumọ eeyan ẹẹdẹgbẹrin lo n ko arun naa.
Ni bayii, aadọjọ ẹgbẹrun abẹrẹ ajẹsara Johnson and Johnson ni Naijiria n reti lọjọbọ.
- Apostle Suleman lo ọlọ́pàá láti fi ìyà jẹ oníbàárà mi, ó fi sí àtìmọ́lé torí ọ̀rọ̀ tó sọ - Amòfin
- Ẹ̀rú ní ìran Bode George, kò ní orírun nílẹ̀ Yorubá, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yà wá lẹ́nu - YWG
- Àwọn aráàlú Igboho bẹ̀rẹ̀ ìjà ẹ̀mí fún ìdáǹdè Sunday Igboho
- Agbẹjọ́rò 31 láti ìpínlẹ̀ 21 lápá oke ọya dúró ti Abba Kyari lórí ẹ̀sùn jìbìtì pẹ̀lú Hushpuppi
Ko din ni ẹgbẹrin o din mẹwaa eeyan to tun ti ko aarun naa laarin wakati mẹrinlelogun sẹyin bi o tilẹ jẹ pe bi awọn eeyan ṣe n ṣe ayẹwo si ko mu ori ya to.
Lorilẹede Naijiria, o le ni miliọnu meji eeyan ti o ti ṣe ayẹwo kokoro arun naa, ninu eyi ti nnkan bii ọgọsan ẹgbẹrun eeyan ti ko arun naa to si ran ẹgbẹrun meji ati igba o din marun un eeyan lọ sọrun.
Bakan naa lawọn ibudo ayẹwo arun naa kaakiri orilẹede Naijiria wa ni ṣiṣi pẹlu bi awọn dokita ilewosan ẹkọṣẹ iṣegun kaakiri orilẹede Naijiria ṣe n gun le iyanṣẹlodi lọwọlọwọ bayii lori.
Amọṣa, ijsba apapọ kede pe awọn ti ra abẹrẹ ajẹsara Johnson and Johnson to to ẹgbẹrun lọna ọgbọn gẹgẹ bi ara igbesẹ lati jawe sobi gbigba abẹrẹ ajẹsara arun ọhun.
Bakan naa ni ijsba orilẹede Naijiria tun fi kun un pe oun ṣi n tiraka lati rii pe ọwọ keji abẹrẹ ajẹsara naa tẹ awọn lọwọ lati lee ri pe ọpọ eeyan lo tun n gba abẹrẹ ajẹsara naa bẹrẹ lati sjọ Iṣẹgun ọsẹ to n bọ.
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, nnkan bii miliọnu mẹrin eeyan lo ti gba abẹrẹ ajọsara COVID-19 pẹlu AstraZenecca ninu igba miliọnu eeyan to wa lorilẹede Naijiria.













