Food Poison: Àwọn oúnjẹ́ mẹ́fà tó lè di májèlé ní àgọ́ ara ta bá jẹ wọ́n papọ̀

Bọli ati ẹpa

Oríṣun àwòrán, Pinterest

Agọ ara ọmọniyan yatọ sira wọn, ohun ti ẹda kan le jẹ ti yoo ba lara mu, si le sakoba fun agọ ara awọn eeyan miran.

Bi o tilẹ jẹ pe gbogbo ounjẹ lo ni anfaani to n se fun agọ ara amọ bi ire se wa ninu ibi, naa ni ibi wa ninu ire, ti isoro si le de ba ẹda lati ipasẹ awsn ounjk naa pẹlu.

Idi ree to fi dara ki ẹda kọọkan mọ irufẹ ounjẹ to ba lara mu ati eyi to le jẹ majele fun agọ ara ẹnikọọkan.

Bakan naa lo yẹ ki gbogbo eeyan mọ awọn ounjẹ kan to le se akoba fun agọ ara wa, to si le jasi iku ojiji, ta ba jẹ awọn ounjẹ naa papọ.

Onimọ nipa ounjẹ jijẹ, Habiba Haruna ba BBC sọrọ lori isọri ounjẹ mẹfa to le di majele ninu agọ ara fun ẹda kọọkan.

Àkọlé fídíò, Afẹ Babalọla: Iyan ni mo fẹran julọ ninu ounjẹ

Awọn ounjẹ to le di majele sara rẹ to ba jẹ wọn papọ:

Ẹja ati Miliki:

Ẹja ati Miliki jẹ ounjẹ to ni eroja asaraloore ta mọ si Protein to pọ pupọ, amọ ta ba pa ounjẹ mejeeji pọ, ta si jẹ wọn lasiko kan naa, ewu n bẹ loko longẹ.

Isoro le de ba ara wa ta ba jẹ ẹja ati miliki papọ nitori ara wa le kọ ọ.

Abala ẹya ara kan ko fẹran lati gba ounjẹ to ni eroja kan naa papọ lasiko kan naa, ta ba si se bẹẹ, o le da wahala silẹ.

Oniruuru ọna si ni ẹda kọọkan fi le se afihan pe aapapọ eroja ounjẹ mejeeji naa ko ba oun lara mu tabi pe o ti di majele ni agọ ara oun.

Ẹlomiran le maa bi nigba ti ẹlomiran le maa yagbẹ nitori pe o jẹ eroja mejeeji naa papọ, bi o tilẹ jẹ pe awsn mejeeji lo ni anfaani nla to n se fun ara.

Ọgẹdẹ ati Miliki:

Isọri eroja ounjẹ meji miran to tun le fa akoba fun agọ ara ta ba jẹ wọn papọ ni ọgẹdẹ ati miliki.

Amọ fun awsn eeyan miran, ajẹpọ miliki ati ọgẹdẹ le mu ki oorun kun wsn, ki wsn si sun daradara.

Ọgẹdẹ ni eroja kan ti wọn n pe ni Potassiun, ẹni ti eroja yii ko ba si to bo se yẹ ni agọ ara rẹ, le mu miliki mọ pọ ọgẹdẹ lai ni isoro.

Amọ fun ẹni ti o ba ni eroja Potassium to yẹ ninu ara, to ba fi jẹ ọgẹdẹ mọ miliki, isoro nla le ba agọ ara rk.

Lara irufẹ awọn isoro ti yoo maa ri ni ki ọrun maa yun, ko si maa họ, tabi ki irorẹ pupọmaa yọ loju rẹ, to si tun le ni aisan ẹjẹ riru.

Lẹmon ati Miliki:

Ti a ba fi miliki sinu eroja Lemon, kiakia ni yoo poora, tawọn eroja ara rẹ yoo si di akurẹtẹ

Idi si ree to fi jẹ pe ti ẹnikan ba po miliki papọ mọ Lemon, o le di majele ninu ara, bakan naa lo tun le jẹ ki aya maa ta eeyan.

Ẹpa ati Olive oil:

Ẹpa dara fun agọ ara, to si wulo ni gbogbo ọna, bakan naa lo ni eroja asaraloore Protein ati Carbonhydrate.

Ẹpa tun jẹ eroja kan ti awọn eeyan to sanra maa n lo lati tiirin tabi mu adinku ba ọra ara.

Bakan naa ni eroja Olive oil dara lati setọju ara, to si tun n wo ọpọ aisan amọ ta ba da pọ mọ ẹpa, ta si jẹ, o le fa wahala fun agọ ara ti ko fẹran eroja Olive oil.

Lilo oogun pẹlu ohun mimu aladun to ni eroja Lemon:

Bakan naa, ta ba lo oogun oyinbo pẹlu awọn ohun mimu aladun to ni gaasi ati eroja Lemon, o le se akoba fun agọ ara.

Onimọ nipa ounjẹ ni ta ba lo awọn ọti ẹlẹrindodo to ni gaasi ati eroja Lemon pẹlu oogun, ewu n bẹ loko longẹ.

O wa gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn mase fi ohun mimu aladun lo oogun kankan, paapaa awọn ohun mimu to ni eroja gaasi ati Lemon.

Ẹran ati ẹyin tutu:

Ti eeyan ba ko ẹran ati ẹyin tutu papọ, ewu nla ni fun agọ ara.

O le fa majele ba ara, to si tun le mu ki ẹlomin maa bi tabi yagbẹ nitori pe ko ba wsn lara mu.

Ẹran tutu le mu akoba ba ra ti a ko ba se daadaa.

Bakan naa ni onimọ nipa ounjẹ ss pe ẹyin tutu ko ni iwulo kankan fun agọ ara ayafi ta ba se tabi din, ka to jẹ.

"Ẹyin tutu ko ni igbẹkẹle, ti a ko gbọdọ gbara le rara nitori ewu ni."

O wa gba awọn eeyan nimọran lati maa jẹ awọn ounjẹ ti yoo se ara wọn loore, ti yoo si se anfaani fun ara wọn lai ni akoba ninu.

Àkọlé fídíò, Afẹ Babalọla: Iyan ni mo fẹran julọ ninu ounjẹ