Breastfeeding: Wo àwọn oúnjẹ́ tí yóò mú kí omi ọmú pọ̀ si fún ìyálọ́mọ́

Pẹpẹ suupu ati iyan

Oríṣun àwòrán, FOODACE/INSTAGRAM

Ọpọlọpọ ounjẹ lo wa, to le ṣe awọn iyalọmọ to n fun ọmọ ni ọyan ni anfaani, ki omi ọmu wọn le pọ si.

Iru ounjẹ ti obinrin to n tọ ikoko lọwọ ba jẹ, ni yoo sọ bi ilera oun ati ọmọ rẹ yoo se ri.

Ṣugbọn ṣa, ọpọlọpọ obinrin lo maa n jẹ oriṣiriṣi 'ijẹkujẹ', lasiko ti wọn ba n fun ọmọ ni ọmu, nitori pe wọn ko mọ nipa iru ounjẹ ti wọn le ma a jẹ.

BBC ba onimọ nipa ounjẹ, Florence Uchendu ati onimọ nipa bi obinrin ṣe n fun ọmọ ni ọmu, Maryam Sanuth sọrọ, lati ṣalaye iru ounjẹ ti obinrin le ma a jẹ, ki omi ọmu rẹ le pọ si.

Gẹgẹ bi Arabinrin Sanuth Maryam ṣe sọ, ti oyun obinrin ba ti pe ogún ọsẹ, ni ọmu rẹ yoo ti ma a ni omi.

Àkọlé fídíò, Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

O ṣalaye pe lasiko yii ni obinrin yoo ṣakiyesi pe ọmu oun n tobi si i.

Ni kete ti obinrin naa ba si bimọ tan, eroja ara ti wọn n pe ni prolactin ati oxytocin yoo bẹrẹ si ni jade sinu ọmu.

Pẹpẹ suupu ati iṣu

Oríṣun àwòrán, NTANTA DELICACIES / INSTAGRAM

Awọn ounjẹ to le mu ki omi ọmu pọ si:

  • Pẹpẹ suupu eyiun ọbẹ alata suẹsuẹ to gbona
  • Pẹpẹ suupu to gbona pẹlu iṣu
  • Tii
  • Oogun oyinbo
Àkọlé fídíò, Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Ol

Florence Uchendu sọ pe, o ṣe pataki fun obinrin to sẹṣẹ bimọ lati ma a jẹ awọn nkan wọnyii, nitori pe o ni ipa pataki fun ipese omi ọmu.

O ni wọn tun ma n mu ki awọn ẹjẹ to di sinu ile ọmọ, tete ṣan jade kuro ninu ara.

Yatọ si eyi, o tun sọ pe yoo jẹ ki ọmu obinrin duro daadaa.

Ogi ati miliiki

Oríṣun àwòrán, CHEFMIDE / INSTAGRAM

Ẹkọ mimu:

Arabinrin Sanuth sọ pe mimu ẹkọ gbigbona naa ṣe koko fun ipese omi ọyan.

Uchendu paapaa fikun pe, lootọ ni ẹkọ mimu dara fun obinrin to n fun ọmọ ni ọmu, amọ o dara ko mu ẹkọ naa pẹlu miliki lai ni ṣuga, to le koba ọmọ tuntun.

O ni eroja aṣara loore protein to wa ninu miliki ṣe pataki fun awọn obinrin to n fun ọmọ ni ọyan.

Galiiki

Ata ilẹ ati alubọsa ayu (Ginger ati Garlic)

Arabinrin Maryam Sanuth sọ pe galiiki ni anfaani pupọ, paapaa fun awọn obinrin to n fun ọmọ ni ọyan.

O ni wọn tun le fi sinu omi ti ko gbona ju, fun mimu.

Oats

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oats

Sanuth sọ pe eroja aṣaraloore Fiber ati ọpọlọpọ eroja mii lo wa ninu oat, eyi to mu ko dara fun iyalọmọ ni jijẹ ni gbogbo igba.

Bakan naa lo tun ni awọn ounjẹ onikoro bi imumu ati ẹpa naa dara.

Imumu

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM / UTAKAEGBE

Àkọlé àwòrán, Imumu yii wa lara eroja ti wọn fi n ṣe Kunnu Aya

Imumu, ti wọn n pe ni tigernut ni ede Gẹẹsi, ni wọn fi n ṣe Kunnu Aya.

O ni ti obinrin ba n mu bi ẹẹmẹta lojumọ, yoo mu ki omi pọ daadaa ni ọmu rẹ, o

Ẹpa

Moringa

O ni iyalọmọ le ma a mu ṣibi ewe moringa ti wọn gun lojoojumọ.

Florence Uchendu sọ pe o ṣe koko fun obinrin to n fun ọmọ ni ọmu lati ma a jẹun daadaa, nitori pe yoo tete ma a rẹ ẹ.

Ewe Moringa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Onimọ sọ pe ewe Moringa dara fun obinrin to n fdun ọmọ lọmu

Fun awọn obinrin to ni aisan itọ ṣuga, Uchendu sọ pe bi wọn ṣe n jẹun tẹlẹ ki wọn o to bimọ, naa ni ki wọn o tẹsiwaju.

O ni o le jẹ ọgẹdẹ dodo ti ko pọn, tabi iṣu sise.