New York Governor resign: Gómìnà New York kọ̀wé fipò sílẹ̀ látàrí pé wọn ní ó hùwà kò tó sí àwọn obìnrin kan

Lori awuyewuye to ti n ja ranyinranyin lori ayelujara lori oro gomina Andrew Cuomo ni iroyin mii ti jade.
Opo awon obinrin kan ni won koko jade sita pe Gomina Andrew Cuomo to n tuko ipinle New York ni orile-ede America n fowo pa awon lara lona aito.
Gomina Andrew Cuomo ni won fi esun kan pe o n hùwà lọ́nà tí kò tọ̀nà sì àwọn obinrin naa.
Gomina yii wa soro sita pe oun moomo kuro nipo lasiko yii ki ise ilu le tesiwaju ni ipinle New York ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Loni ojo Isegun ni Gomina Andrew ni ikowefiposile naa yoo bere lojo merinla si oni.
Agbara isakoso ipinle New York yoo bo sowo Ogagun Kathy Hochul.
Ogbeni Cuomo to je eni odun metalelogota ni enu ti n kun pe ko kowe fipo sile lati ose to koja.
Koda, Aare Joe Biden gan an gba a ni moran pe ko se bée.

Okan ninu awon obinrin mokanla to ni Gomina huwa ko to si awon jade sita lojo Aje fun igba akoko.
Brittany Commisso to je akowe amugbalegbe gomina Andrew Cuomo lo soro lori amohunmaworan to n beere fun idajo ododo lori esun naa.
Sugbon gomina Andrew ni iro ni won n pa mo oun ki o to kowe fipo sile













