Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́

Yoruba ni ẹnu ti ẹnu rẹ ba to ọrọ, lo maa n sọ ọ.

Agba amofin kan lorilẹede Naijiria, to tun jẹ ajafẹtọẹni, Femi Falana ti salaye fun BBC Yoruba lori idi ti ijọba Naijiria fi n ba Sunday Igboho se ẹjọ.

Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Igboho ni ijọba Benin mu ni papakọ ofurufu kan nilu Cotonou pẹlu iyawo rẹ lasiko ti wsn n rinrin asjo lọ silẹ Germany.

Falana ni bo se yẹ ki orilẹede tẹle ofin ni ijọba Cotonou se nitori lọjọ keji ti wsn mu tọkọ-taya naa, ni wọn gbe wọn lọ sile ẹjọ.

O ni ijọba Naijiria lo fẹ di Igboho lapanyaka sinu baalu lati papakọ ofurufu lati maa gbe bọ ni Naijiria, gẹgẹ bo ti se fun Kanu lorilẹede Kenya, amọ ijọba Benin ni ko gba fun wọn.

Agba amofin naa wa salaye pe aibọwọ fun ofin ti pọ ju ni Naijiria amọ ti orilẹede Benin n bọwọ fun ofin, eyi to si mu ki Igboho wa ni ahamọ.

Bakan naa lo woye pe pe ijọba apapọ n gbe igbesẹ to tọ lori ẹsun kikopa ninu iwa lilu jibiti ti ijọba ilẹ Amẹrika fi kan ọga ọlọpaa Abba Kyari amọ ti ko se bẹẹ lori ọrọ Igboho ati Kanu.

Femi Falana tun yan pe ẹkọ nla ni bi ẹjọ Sunday Igboho se n lọ ni Cotonou n kọ awọn agbẹjọro lorilẹede Naijiria nitori bi wọn se n tẹle ofin.