Nigeria Insecurity: Kọmíṣánà ètò ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Niger ní ajínigbé fi òun ṣe ẹ̀sín àti ẹlẹ́yà, ìyà jẹ òun

Oríṣun àwòrán, Premium times
Kọmisanna fun eto iroyin nipinlẹ Niger, Mohammed Idris ti pada darapọ mọ awọn akẹẹgbẹ ati ọrẹ rẹ ni ọjọ Ọjọbọ, lẹyin to gba ominira lọwọ awọn ajinigbe.
Ọjọ Aiku to kọja ni awọn ajinigbe naa kọlu u ni bi aago mọkanla alẹ, ile rẹ to wa ni abule Babban Tunga ni ijọba ibilẹ Tafa, ni wọn ti ji gbe.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lasiko ti Olori ile aṣofin ipinlẹ naa, Alhaji Abdullahi Bello ki kaabọ pada, Ọgbẹni Idris sọ pe inu òjò ni awọn ajinigbe naa ni ki oun sun si fun ọjọ meji, ko to o di pe wọn fun ni nkan lati bora.
Kọmisanna naa ṣapejuwe bi wọn ṣe ji gbe gẹgẹ bi nkan iwọsi ati ifiniṣe ẹlẹya. O ni oun ko gbadura iriri naa fun ẹnikẹni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sapara-Williams: Ọmọ Oòduà tó kọ́kọ́ dábàá pé kí ilẹ̀ Yorùbá dúró lábẹ́ àkóso kan ṣoṣo
- Wo ìye owó tí lítà epo pẹtirólú kan yóò jẹ́ lẹ́yìn ìpàdé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba
- Àwọn ajagungbalẹ̀ gba ilẹ̀ tó yẹ fún kíkọ́ iléèwé girama ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Wo oúnjẹ́ àdàpọ̀ mẹ́fà tó lè di májèlé nínú àgọ́ ara
- A kú oríire! Oró agbọ́n leè wo àìsàn jẹjẹrẹ ọmú sàn, wo ohun tí wàá lò pọ̀ mọ́ra wọn
- Ẹ fura o! Àjọ elétò ìdìbò INEC kígbe síta lórí ọ̀nà tuntun tí àwọn kan fẹ́ gbà ṣọṣẹ́ fún ìbò 2023
- Ọpọ Obìnrin ní inú wọn kún fún ìbànújẹ lásìkò yìí nítorí wọn kò yó ìfẹ lónà tó yẹ- Tonto Dikeh
- Wo ànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
Idris sọ pe ninu ile oun ni wọn ti gbe oun lẹyin ti wọn ja gbogbo ilẹkun.
"Wọn gbe mi lọ si ibi ti mi o mọ. Nibẹ si ni wọn ti fi mi si inu ojo fun wakati mejidinlaadọta, lai si ounjẹ tabi omi, ti wọn si tun de mi ni ọwọ ati ẹsẹ."
O ni ṣugbọn dipo ki agbara wọn bori oun, oun ni oun bori wọn, nitori pe o de asiko kan ti wọn bẹrẹ si ni ṣaajo oun.
"Wọn tu mi silẹ, wọn si tun fun mi ni burẹdi ati omi, pẹlu nkan lati bora.
Ọgbẹni Idris sọ pe agbara Ọlọrun lo gba oun silẹ, nitori pe awọn ko san owo kankan.
















