Yoruba Nation: Iba Gani Adams fi ọ̀rọ̀ ranṣẹ sí Buhari lórí àfojúsùn Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Iba gani
Aare-onakakanfo of Ilẹ Yoruba, Aare Gani Adams ti ke si ijọba aarẹ Muhammadu Buhari lati pa ọkan pọ lori nnkan ti o fẹ ṣe, yala lati gba ki awọn ọmọ Yoruba lọ lọtọ tabi ki o moju to nnkan ti awọn Gomina Guusu n sọ lori atunto Naijiria.
Atunto yii, gẹgẹ bo se sọ, yoo fun ẹkun kọọkan lanfaani lati maa ṣe ijọba ara wọn.
Gani Adams sọ eyi ni ilu Osogbo lasiko ti wọn n se ipade awọn agbaagba ilẹ Yoruba ti ẹgbẹ ọmọ Oodua ṣe.
- Ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation ń fa aáwọ̀ láàrin Gani Adams àti Sunday Igboho
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Gani Adams kọ lẹ́tà sí àjọ UN, AU, US lórí ààbò tó mẹ́hẹ àti ìpànìyàn darandaran
- Gani Adams tutọ́ sókè fójú gbà lórí ìkọlu sílé Sunday Igboho
- Ó lé yọrí sí ogun, tí ìjọba Naijiria bá fi ìyà jẹ Sunday Igboho bí ọ̀daràn - Gani Adams
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Ẹ̀yin Fulani, ẹ yàgò fún ilẹ̀ Yorùbá lásìkò yìí- Iba Gani Adams
Iba ṣalaye pe ni ti oun, ki iran yoruba da wa lọtọ ni oun faramọ ati pe oun ko ni sinmi lati tẹsiwaju lati ma lepa idaduro iran yoruba.
Aarẹ ọna Kakanfo gboriyin fun awọn gomina Guusu fun igboya wọn lati bere fun eto ijọba ẹlẹkun jẹkun lọwọ ijọba apapọ.
Gani Adams ni ẹgbẹ oun yoo tubọ maa ja fun gbigba ominira Yoruba ni ilana to ba ofin mu, ti ko si mu jagidjagan dani.
Bakan naa lo sọ pe awọn alatilẹyin oun nilẹ okeere yoo tẹle ọjọgbọn Akintoye ọwọọwọ, lọ si ipade apero ajọ isọkan agbaye ninu osu Kẹsan-an ọdun 2021.
Iba Gani Adams wa fi ọ̀rọ̀ ranṣẹ sí àarẹ Muhammadu Buhari lórí ìjàgbara ìran Yorùbá lati pe fun idibo ti yoo fi han pe iran yoruba fẹ da duro, tabi lati gba orilede tuntun.
"A o le tẹsiwaju lati ma jiya jiṣẹ, a o le maa gbe ninu ilu ti a ko dabi ọmọ ilu miiran.
"A fi ara mọ ipinu àwọn gomina iwọ-oorun Guusu lori iṣejọba ẹlẹkun jẹkun.
Awa gẹgẹ bi jagunjagun yoo tẹsiwaju lati maa pe fun iyapa ẹya yoruba, sugbọn nnkan ti o kere julọ ti a beere fun ni ijọba ẹkunjẹkun



















