Bakura Agricultural College: Awọn agbébọn gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́, wọ́n tun pa ààyàn mẹ́rin ní Zamfara

Ẹnu ọna ile ẹkọ ti ijinigbe ti waye

Oríṣun àwòrán, facebook

Awọn agbebọn ti gbe awọn akẹkọọ ati olukọ ni ile ẹkọ giga College of Agriculture and Animal Health ni Bakura, nipinlẹ Zamfara.

Igbakeji Ọga Agba ile ẹkọ naa, Mallam Aliyu Bakura fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.

O sọ pe wọn tun pa eeyan mẹrin, lara wọn ni ọlọpaa kan ati oṣiṣẹ alaabo mẹta.

Ni nkan bi aago mẹwaa alẹ ni wọn wọ inu ọgba ile ẹkọ naa, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.

Bakan naa ni Mallam Bakura sọ pe akẹkọọ mẹẹdogun, olukọ kan, iyawo ati ọmọ rẹ meji ni wọn gbe lọ.

Àkọlé fídíò, Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

Mallam Bakura sọ pe awọn agbebọn naa pọ to wa, to si jẹ pe ori odi ileewe naa ni wọn gba wọle. Ti wọn si ṣe ikọlu naa fun bi wakati meji pẹlu ibọn to n dun lakọ-lakọ.

Oṣu Keje ni awọn agbebọn kan kọlu ile ẹkọ Bakura College, ti wọn si gbe Ọga ile ẹkọ naa ni ibugbe awọn olukọ.

Eyi waye lẹyin ti awọn agbebọn kan pa eeyan to le ni ogoji ni agbegbe Maradun, ti ko fi bẹẹ jina si Bakura.

Bakan naa ni ikọlu miran tun waye nibi ti wọn ti gbe awọn akẹkọọbinrin nile ẹkọ kan ni Jangebe, ti oun naa wa nitosi Bakura.