Arewa ní ó yẹ́ kí ìjọba Amẹ́ríkà fi ọ̀rọ̀ Abba Kyari tó aláṣẹ Nàíjíríà létí kó tó lọ sílé ẹjọ́

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, others

Agbarijọpọ ẹgbẹ bii mejilelaadọta to jẹ ẹgbẹ ọmọ bibi ẹkun ariwa Naijiria to wa labẹ aburada ẹgbẹ Arewa ti kọwe si ijọba ilẹ Amẹrika lori ẹsun to fi kan Abba Kyari.

Bẹẹ ba gbagbe, gbajumọ afurasi gbajuẹ, Ramoni Abass, ti wọn tun n pe ni Hushpuppi lo ka orukọ ọga ọlọpaa, Abba Kyari, gẹgẹ bi ara awọn eeyan to na ninu owo jibiti miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla to lu ẹnikan ni Dubai.

Ẹ́gbẹ Arẹwa naa wa n kesi ijọba ilẹ Amẹrika lati ri daju pe ko segbe rara ninu iwadi tileesẹ ọlọpaa rẹ, FBI n se lori Abba Kyari.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹgbẹ naa ni oun ko di FBI lọwọ lati se iwadii rẹ amọ awọn ilana to mu wọnu iwadiii naa, lo n kọ oun lominu.

Arewa kọ akọtun iwe ẹbẹ yii si olu ileesẹ asoju ilẹ Amẹrika to wa ni Naijiria nilu Abuja eyi ti agbẹnusọ rẹ, Abdulazeez Suleiman fọwọsi.

O ni "awọn asise wa ninu ilana ti FBI gba se iwadii naa, eyi to n dunkooko mọ ominira Naijiria bii orilẹede ati ẹtọ awọn eeyan rẹ.

Bakan naa lo ni awọn asise yii tun lewu fun aamulo ilana ofin, iran ọmọniyan ati ọlaju tawn eeyan ilẹ amẹrika n duro le lori.

Awọn asoju ẹgbẹ ajafẹtọẹni marun si lo tun buwọlu iwe ẹsun naa.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

Arewa ni FBI ti tasẹ agẹrẹ nipa ajọsepọ orilẹede kan si omiran pẹlu bi ko se kọkọ fi ọrọ naa to ileesẹ asoju ilẹ Naijiria to wa ni Amẹrika leti.

Bakan naa lo ni ko ba tiẹ dara ko tun kan si ijọba Naijiria pẹlu ko to di pe o n gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ, to si di ariwo.