Hushpuppi Vs Abba Kyari: Falana ní ẹnú yà òun bí ìjọba ṣe fẹ́ lò ìlànà tó tọ́ fún ẹ̀sùn Kyari, tó sì ń rúfin lórí ọ̀rọ̀ Igboho àti Kanu

Femi Falana and Abba Kyari

Gbajugbaja agbejọro agba ni Naijiria, Femi Falana ti sọrọ l'ori ẹsun ti FBI fi kan Abba Kyari.

Agba agbejọro, to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana, ti sọ pe ko si bi igbakeji Ọga ọlọpaa, Abba Kyari, ṣe le bọ mọ ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ America, FBI lọwọ.

Ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ Federal Bureau of Investigation, FBI, kede ni oṣu to kọja pe Kyari gba owo riba lọwọ gbajúmọ ti wọn fi ẹsun lilu jibiti kan, Ramoni Igbalode Hushpuppi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibi ipade ijiroro ori ayelujara Twitter kan ti ẹnikan pataki lara awọn oluwọde ENDSARS, Rinu Oduala, ṣe agbatẹru rẹ ni Falana ti sọ ọrọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni boya Abba Kyari fẹ tabi kọ̀, ilẹ America yoo mu u lati koju igbẹjọ.

Àkọlé fídíò, Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́

O ni "iyalẹnu lo jẹ pe ijọba Naijiria to n lo iwa janduku lati koju àwọn to fẹ ẹ yapa kuro ni Naijiria, sọ pe oun yoo tẹle ilana to yẹ 'due process' lori ẹsun ti FBI fi kan Kyari.

Ileesẹ FBI sọ pe Hushpuppi fun Kyari ni ọpọlọpọ owo, lati fi ẹnikan ti wọn jọ n lu jibiti, Vincent Chibuzor si ẹ̀wọ̀n nitori jibiti owo to le ni miliọnu kan Dọla ti wọn lu.

Amin iyasọtọ kan

Wo ohun tílé aṣòfin fẹ́ ṣe tí Abba Kyari bá jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì lílù

Abba Kyari n gba amin ẹyẹ lọwọ olori ile asoju-sofin, Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, CrimeFighters

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ile asoju-sofin nilẹ wa ti kede pe o seese ki oun gba awọn ami ẹyẹ ti wọn ti fun ọga ọlọpaa Abba Kyari, to ba jẹbi awọn ẹsun ti ileesẹ ọlọpaa ilẹ Amẹrika, FBI fi kan-an.

Bẹẹ ba gbagbe, ajọ to n mojuto isẹ ọlọpaa lorilẹede yii lo ti pasẹ saaju pe ki Abba Kyari lọ rọọkun nile na, gẹgẹ bi ọga agba ọlọpaa nilẹ yii, Usman Baba ti beere fun.

Bẹẹ ba gbagbe ile asofin apapọ ilẹ wa lo ti kọkọ fi ami ẹyẹ da Abba Kyari lọla lọjọ Kọkanla osu Kẹfa ọdun 2020 nitori isẹ akin to n se lẹnu isẹ ọlọpaa ni Naijiria.

Laipẹ yii si ni ileesẹ ọlọpaa FBI kepe pe Abass Ramoni ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi, ti wọn lo lu jibiti owo nla lori ayelujara, ka orukọ Kyari gẹgẹ bii ara awọn eeyan to pin owo jibiti naa fun.

Nigba to n sọrọ lori ami ẹyẹ ti ile asojusofin fun Kyari, alaga igbimọ ile to wa feto iroyin ati ọrọ araalu, Benjamin Kalu salaye igbesẹ ile asojusofin lori isẹlẹ yii fun iwe iroyin Punch.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap

Kalu ni Abba Kyari ko tii ni ẹsẹ kankan lọrun lasiko yii titi ti wọn yoo fi lo jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan.

"Ohun ti ofin ilẹ wa sọ ko ni amulumala ninu. Amin ẹyẹ ti ile asofin fun kii se amin ẹyẹ kansoso to ni ree, a ko si gbọdọ tii maa gba ami ẹyẹ naa kuro lọwọ rẹ.

Afurasi lasan si ni Kyari lori awọn ẹsun ti wọn fi kan-an lasiko yii, ti ko si tii ni ẹsẹ kankan lọrun ayafi igba ti wọn ba kede pe o jẹbi awọn ẹsun naa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileesẹ ọlọpaa Amẹrika FBI lo ti sọ fun ile ẹjọ kan nilu Califonia pe Hushpuppi ati Kyari wa lara awọn afurasi mẹfa ti wọn fi ẹsun lilu jibiti kan lori ayelujara.

Apapọ owo ti wọn lo wa ninu jibiti ọhun ni Miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla.