Sunday Igboho: Àwọn ẹgbẹ́ aláriwo tó gbìyànjú láti fún mi ní ówó gan, mo kọ̀ọ́- Agbẹ́jòrò Sunday Igboho

Agbẹjọ́rò àgbà fún Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mọ sí Sunday Igboho Yomi Aliyu ti ke gbajare pé ko si ẹnikẹ́ni tó ṣe ònígbọ̀wọ́ ìgbẹ́jọ Sunday Igboho àti àwọn iṣọmọ̀gbè rẹ ti DSS ko lọ ilé ẹjọ́.
Ninu àtẹjáde alábala méjì ti agbẹjọrò àgbà ní Nàìjíríà náà fọwọ́ sí ló tí ṣàlàyé pé, àwọn àhèsọ kan ń lọ níbi ti àwọn kan sọ pé àwọn ni onígbọ̀wọ́ Igbẹ́jọ Sunday Igboho àti awọn alábàṣiṣẹ́ rẹ̀.
Yomi Aliyu ni òun n fi àsìkò yìí ń sọ pé kò sí ẹnikẹni tí ó n ṣe agbátẹ̀ru ètò ìgbẹ́jọ to n lọ ni ìlú Abuja
- Gómínà ìpínlẹ̀ Kano àti Oyo fi ọjọ́ ajé àti Iṣẹgun sílẹ̀ fún ìṣìnmi ọdún Hijrah
- Obìnrin kan gbé McDonald's lọ ilé-ẹjọ́ torí ìpolówó Buger já a láàwẹ̀
- Ìdí tí wọ́n fi ń pè mi ní Maradona rèé- Ibrahim Babangida
- Láyé! Mi ò lè wo BBNaija! Ìdí tí mo fi gbá ètò náà ní "blocking" tí ẹnikẹ́ni ò gbudọ̀ wò ó nílé mi rèé'
Bakan naa ni ko sọ́wọ́ ẹnikẹni ninu ti ìlú Ibadan, àti pé owó tí kò ní ìtumọ̀ kan ti àwọn ẹgbẹ́ aláriwo kan ko wá, òun ko gbàá.
Ó ni ajìjàgbara Yorùbá ọ̀hún fúnra alára rẹ̀ ló n dá ẹrù rẹ̀ gbé láti ìgbà ti wàhálà yìí tí bẹ̀rẹ̀.
" Oníbarà mi ṣetán láti ja ìjà yìí dé ojú àmì láì gba ohunkọ́hun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
Bákan náà ni agbẹ́jọrò náà tún fi kun pé gbogbo àwọn tó n bẹnu àtẹ́ lu àwọn ofin ti ilé ẹjọ́ gbékalẹ̀ lórí gbigba onídurò àwọn òṣìsẹ́ Sunday Igboho ko ni ìtumọ̀.
O ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn tó n sọ̀rọ̀ yìí jẹ́ aláìmọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ òfin àti ètò ilé ẹjọ́
Ó ni kàkà ti wọ́n fi ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ àdájọ ilé ẹjọ́ giga ìlú Abuja, ṣe ni ó yé kí wọ́n gbé oríyìn fún nítori ìgboyà rẹ̀.
Aliyu ṣàlàyé pé pàápàá jùlọ ni ìrú àsìkò yìí tó jẹ́ pé àwọn àjọ ọtẹlẹmúyẹ ni ọba àwọn ọba lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà báyìí.
Agbẹjọrò náà ni kí àwọn ènìyàn má gbàgbé pé àwọn àjọ ọ̀tẹlẹmúyẹ náà yabo ilé adájọ́ náà ti wọ́n ni àwọn ń ṣe iṣẹ́ àwọn, sùgbọ́n ó fi hàn pé kìí ṣe láti ṣeru ba adájọ náà nikan bíko ṣe láti doju ẹ̀ka ìdájọ bolẹ̀.
Bákan náà lo tun fi kun pé kò ṣeeṣe lábẹ́ òfin láti mú oníduro kan fun gbogbo àwọn olùjẹ́jọ́.
" Bi ọ̀rọ̀ onídujro bá níra láti ṣe, a ní ore-ọ̀fẹ́ láti padà lọ si ilé ẹjọ fún àtúdá rẹ̀.
















