Sunday Igboho: Olùgbé Benin Republic ní káwọn ọba Yorùbá máa tètè pariwo pé Igboho kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho/Instagram

Ẹnikan ti ke si awọn ọba alaye nilẹ Yoruba lati tete dide si ọrọ itusilẹ Sunday Igboho, ki ọrọ naa to bọwọ sori.

Ninu fidio kan to jade sori ayelujara ni ọmọ Yoruba kan, Oloye Agbomola Ajirotutu ti n ke gbajare pe awọn ọba Yoruba nilo lati kan si aarẹ orilẹede Benin ni kiamọsa.

Ajirotutu, to n gbe nilu Cotonou salaye pe tawọn oriade nilẹ Yoruba ba se fidio pe eeyan rere ni Igboho, eyi too seranwọ lati ri idande rẹ gba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni lootọ ni oun n se atilẹyin fun idasilẹ Yoruba Nation amọ lori ọrọ Igboho, o kere tan ọba mẹwa gbọdọ jade lati maa fọnrere pe Sunday Igboho ko sẹ rara, iya oselu lo n jẹ.

"Awọn ọba ti ko ba le wa sorilẹede Benin, le se fidio jade laarin ọjọ Isẹgun si Ọjọru pe ki aarẹ orilẹede naa mase da Igboho pada si Naijiria.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Ofin Benin lootọ ni ko le gba ijọba Naijiria laaye lati gbe Igboho lọ amọ wọn yoo se iwadi pe iru eeyan wo ni Igboho funra rẹ.

Se ọdaran ti wọn pe lo jẹ ni abi wọn n parọ mọ, amọ ohun ti awọn ọba Yoruba ba sọ bayii pe Igboho kii se eeyan buruku, ajijagbara ni.

Eyi yoo ran Igboho lọwọ pupọ lọdọ ijọba ilẹ Benin lati fi opin si gbogbo isoro to n koju, ti wọn ko si ni fa a kalẹ fun ijọba Naijiria."

Bakan naa ni Ajirotutu ni oun ko fẹ ki ẹmi eeyan lo aarẹ Benin lati tako Sunday Igboho ni se n kigbe pe kawọn agbaagba Yoruba dide, maa pariwo tori abala iwadii nipa Igboho ni Benin wa bayii.

O fikun pe awọn ọba ni orilẹede Benin ti jade sita lati gbe Igboho nija, iyoku wa ku sọwọ awọn Yoruba lati tete dide si ọrọ naa lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Okunade Sijuwade: Ìfẹ́ tí Sarun tó súnmọ́ Ooni jù láyé ní sí í ló sọ ọ́ di abọ́bakú- Adeye