Sunday Igboho: Okei-Odumakin ké sí ìjọba Benin Republic látí fí Sunday Igboho silẹ̀ kó lé é gba Germany lọ

Joe Odumakin and Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan ati aarẹ Women Arise Centre for Change, Joe Odumakin ti kesi ijọba orilẹede Benin Republic lati fi Sunday Igboho silẹ ni waranṣeṣa.

Odumakin ninu atẹjade to fi lede ni ki awọn eniyan sọra fun iroyin ẹlẹjẹ nipa Sunday Igboho nitori o le dena gbogbo eto ti wọn n ṣe lati gba itusilẹ rẹ.

O ni igbagbọ oun ni pe ijọba Benin Republic jẹ ijọba to bọwọ fun ofin ọmọniyan, to si n tẹlẹ aṣẹ eto ijọba tiwantiwa, nitori naa ki wọn tete mura si ibeere Sunday Igboho fun ominira ni orilẹede miran lati sa asala fun ẹmi rẹ.

'' Kii ṣe aimọ fun oloko wi pe ijọba Naijiria ko ni ayọle, ti wọn si le e tẹ oju ẹtọ Sunday Igboho mọlẹ, ti o ba pada wa si Naijiria.''

''Orilẹede Naijiria ti ko ri nkan ṣe si ikọ Boko Haram ati awọn agbebọn to n ba nkan jẹ ni Naijiria to si n pa awọn araalu, amọ awọn ajijagbara to n beere fun ẹtọ wọn ni ijọba fẹ ma a gbogun ti''

''Apẹrẹ ni bi wọn ṣe lọ mu Nnamdi Kanu lọna ti ko ba ofin mu, ti wọn si n bo gbogbo rẹ mọlẹ lai jẹ ki ẹnikẹni yoju si''

Eleyii ko dara to nitori ẹtọ ọmọniyan ni lati ni anfaani si igbeaye to rọrun ati alaafia to fi mọ eto aabo to gbooro fun awọn eniyan.

Odumakin ni o ṣeni laanu pe ijọba Naijiria fi eyi silẹ, ti wọn si n le ohun ti ko si kiri, eleyii ti yoo jasi opin orilẹede Naijiria ti ijọba ba n ba bayii lọ.

Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu

Buhari, tú Sunday Igboho sílẹ̀ bo ṣe tú Boko Haram tó ronúpíwàda sílẹ̀ - Ladoja

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Rasidi Adewolu Ladoja ti sọ wi pe, ijọba apapọ lo da awọn ajijagbara bii Sunday Igboho, to n ja fun ilẹ Yoruba ati Nnamdi Kanu to n ja fun idasilẹ orilẹede Biafra silẹ.

Sunday Igboho ati Rashidi Ladoja

Oríṣun àwòrán, Others

Ladoja lo sọ bẹẹ ni ile rẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to gbadura Ileya tan ni ọjọ Iṣẹgun.

Ladoja to tun di ipo Osi Olubadan ti ilu Ibadan mu lo fesi si iroyin pe ọwọ awọn agbofinro lorilẹede Naijiria ti tẹ Sunday Igboho ni ilu Cotonou, lorilẹede Benin Republic.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ijọba apapọ to kọ lati koju awọn ipenija ijinigbe, ipaniyan awọn araalu kaakiri orilẹede Naijiria, paapaa ilẹ Yoruba lo mu awọn eniyan bi Sunday Igboho di adari fun awọn eniyan rẹ.

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ wa parọwa si ijọba apapọ lati ṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu bi wọn ṣe fi panpẹ ọba mu Sunday Igboho nitori ọpọlọpọ eniyan bii Sunday Igboho ni yoo dide ti ijọba ba fi ọwọ agbara mu awọn ti wọn mu yii.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

''Awọn eniyan bẹrẹ si ni ja fun ara wọn nitori ijọba kuna lati da abo bo awọn araalu, ti wọn si kesi awọn to le e ja fun wọn lati wa ran wọn lọwọ''

Kii ṣe pe wọn fi panpẹ ọba mu Sunday Igboho lo jẹ mi logun, bi ko ṣe wi pe ijọba apapọ gan an lo lẹbi ọrọ yii nitori awọn lo jẹ ki iru awọn eniyan bayii dide.

Ẹ wo iru ipaniyan to waye ni ilu Igangan ati awọn agbegbe miran. Awọn wọn yii yoo sọ wi pe awọn ni baba iṣalẹ kan, ti wọn yoo si fi wọn silẹ.''

Awọn Fulani darandaran ti pa ọpọlọpọ eniyan, ti ninu wọn si jẹ Dokita Fatai Aborode, Alhaji Sherifat Adisa, ti ijọba ko si fi panpẹ ọba mu ẹnikẹni.''

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

''Nitori awọn eniyan bayii ni Sunday Igboho ṣe bẹrẹ si ni ja fun awọn eniyan rẹ, to si di ẹni ti wọn n bu ọla fun kaakiri.''

''Ti wọn ba mu Sunday Igboho loni, ti ijọba si kọ lati kọ ibi ara si ipenija eto aabo to mẹhẹ yii, awọn eniyan bii Sunday Igboho yoo dide''

''Ko bajẹ to eleyii ri, o si ṣeni laanu pe aarẹ Muhammadu Buhari ko kọbi ara si awọn ipenija yii.''

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

''Bii Kanu, Sunday Igboho ti jẹ adari fun awn eniyan kan, eleyii to yẹ ki ijọba apapọ ṣe jẹjẹ lori ọrọ yii''

Bakan naa ni Gomina tẹlẹri nipinlẹ Oyo naa gba ijọba apapọ ni imoran lati tu Sunday Igboho, Nnamdi Kanu silẹ bii wọn ṣe tu awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram silẹ nitori wọn ronu[piwada.

Rashidi Ladoja fikun pe ijọba mu awọn agbesunmọmi Boko Haram kan ni ọdun to kọja ti wọn si tu wọn silẹ fun ijọba ipinlẹ Borno, nitori naa ki wọn se bẹẹ fun Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu.