Sunday Igboho: Olùwọ́de yoǹbó Ooni lórí ìgbésẹ̀ láti yọ Igboho ní àhámọ̀ àmọ́ rọ Oluwo láti tún èrò rẹ̀ pa

Oluwo ati awọn oluwode

Awọn oluwọde to n pe fun itusilẹ Sunday Igboho to wa ni ahamọ nilu Cotonou, lorilẹede Benin, ti n fi ọrọ ransẹ si Oluwo tilu Iwo lasiko iwọde wọn.

Ọkan lara awọn oluwọde naa, to pe ara rẹ ni Comrade Komolafe, to jẹ ọmọbibi ilu Iwo ni oun dupẹ lọwọ Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọjaja Keji lori awọn igbesẹ to n gbe.

O ni lati igba ti wọn ti mu Sunday Igboho lalẹ ọjọ Aje ni Ooni ko ti sun, to si gbe igbimọ ẹlẹni mọkandinlọgbọn dide lati lọ ja fun itusilẹ Igboho.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ooni jẹ ka mọ pe iru wọn lo yẹ nipo oriade tori baba naa jẹ ẹni kan to ni iwa ifiraẹnijin, to si jẹ ka mọ pe gbogbo eeyan Kaarọ Oojire lo jẹ ọmọ bibi inu oun.

Mo wa n gbadura pe ori apere awọn babanla wọn ko ni gbona mọ wọn, bakan naa ni mo si n ke si awọn ọba alaye yoku lati fi ti Ooni se awokọse rere."

Àkọlé fídíò, Oluwo ilu Iwo ba BBC Yoruba sọrọ lori awuyewuye pẹlu awọn Ọba

Comrade Komolafe wa lo akoko naa lati kesi Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni pe ko maa fura pe awọn eeyan n wo oun.

"O yẹ ki Oluwo mọ pe awọn eeyan n wo ohun, wọn si n gbọ ohun to n sọ. Awọn eeyan kan lo kọkọ lo ori itẹ naa, ti wọn si lo daadaa, ti orukọ wọn ko si parẹ.

Ohun ti Oluwo si n se loni naa, itan lo n kọ, gbogbo ohun tẹ sọ ni Yidi lọjọ ọdun Ileya ana pe ki awọn eeyan kalọ si aafin yin wa lọ jẹun.

Ẹ ni ohun to sẹlẹ si Sunday Igboho ko kan yin, jẹ ka mọ iha tẹ kọ si Igboho, ko si yẹ ko ri bẹẹ rara.

Ti awọn kan ba tiẹ n sọrọ yin laidaa, awa maa n jẹri lẹyin pe ẹ ko le sọ iru rẹ nita gbangba, pe ẹ nifẹ si Sunday Igboho.

Àkọlé fídíò, Oluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya

A wa n rọ baba wa Akanbi lati yi ohun ti wọn fi n sọrọ pada lati isinsinyii lọ, Ọlọrun ko ni jẹ ki ori itẹ gbona mọ yin o.

Awa ọmọ bibi ilu Iwo ko faramọ ohun tẹ n sọ yẹn, a dẹ n fi asiko yii sọ fun a ko fara mọ ohun ti baba Oluwo n sọ.

Awa kii se ọmọ ale Iwo, ẹ dakun baba wa, ẹ maa fi suuru sọrọ, kẹ si maa gbe gbogbo igbesẹ tẹ ba le gbe lori ọrọ Igboho.

Oluwọde naa wa kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe Sunday Igboho kii se ọdalẹ tabi ọdaran, yoo si dara ki wọn tete fi silẹ.

Amin iyasọtọ kan

Ìwọ́de ńlá yóò wáyé lónìí ní London lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho/Instagram

Iroyin ti wa tẹ lọwọ pe iwọde alagbara kan yoo waye ni aarọ oni nilu London lori ọrọ Sunday Igboho.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun Oloye Sunday Igboho, Olayomi Koiki ti kede loju opo Facebook rẹ, awọn ọmọ Naijiria to tẹdo silẹ UK ni yoo korajọpọ fun iwọde naa.

O ni iwọde alagbara naa yoo waye ni ojule kẹwaa, Opopona Downing nilu London, eyi tii se ọọfisi ileesẹ olootu ijọba ilẹ UK, Boris Johnson.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ẹ jẹ ka ri pe a yọju sibi iwọde naa, ka si maa ranti pe asiko yii nikan la le dide lati ke pe awujọ agbaye nipa ohun to n lọ ni Naijiria.

Wọn ti gbe igbesẹ saaju lati gba ẹmi Sunday Igboho ni ọjọ kinni osu Keje amọ ti ko seese fun ijọba, o si yẹ ko ye wa pe ẹmi rẹ ni wọn n wa.

Àkọlé fídíò, Iyalaje Oodua: Toyin Kolade ṣàlàyé ìdí tí Ooni Ogunwusi ṣe fi jẹ Ìyálájé Oodua

Nigba to ti nira fun wọn lati ra Igboho si ọdọ wọn, ohun ti wọn fẹ se bayii ni lati gba ẹmi rẹ."

Agbẹnusọ fun Igboho ni lati ọjọ ti DSS ti kọlu ile Sunday Igboho ni awọn eeyan ti n jade ni meji mẹta lati se iwọde ni Central London lojoojumọ.

O ni awọn eeyan yii ko ni ki awọn pọ niye, ki wọn to jade, amọ ohun to se pataki ni pe awọn eeyan to n lọ lagbegbe naa n ri wọn.

"Awọn eeyan ti ẹ ko lero kuku n ri wọn, ti wọn si n se akiyesi wọn, ti wọn si n sọ pe ko si ọrọ anbojuwẹyin mọ lori ọrọ Yoruba Nation.

Ori ọrọ Yoruba Nation si la duro le lori. A ko gbọdọ sa sẹyin tabi fi oju pamọ, afigba ta ba gba Yoruba Nation."

O wa rọ awọn ọmọ Yoruba to n gbe nilu ọba lati jade wa kopa ninu iwọde naa.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y