Sunday Igboho: Ooni, Olujinmi, Olugbon, Akin Osuntokun àtàwọn àgbàgbà Yorùbá forí korí

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho/Instagram
Ooni Ile Ife àtàwọn èèkàn ilẹ̀ Yorùbá ṣèpàdé ìdákọ́nkọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ṣe ipade pọ pẹlu awọn eekan nilẹ Yoruba lori bawọn ọlọpaa ṣe mu Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ sí Sunday Igboho ni Cotonou, orilẹede Benin.
Iroyin sọ pe Sẹnẹtọ Abiodun Olujimi to n ṣoju ẹkun Guusu Ekiti, Ọgbẹni Akin Osuntokun to jẹ oladamọran lori ọrọ oṣelu sí aarẹ Naijiria tẹlẹ rí, Olusegun Obasanjo ati Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Eko f'ẹgbẹ PDP, Jimi Agbaje wa nibi ipade idakọnkọ ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ẹ̀yìn ọba Yorùbá, ẹ dìde láti gbe Sunday Igboho níjà kó le jàré nílẹ̀ Benin"
- "Ìdí tí ìjọba Benin Republic kò ṣe ní le è fa Igboho lé Nàíjíríà lọ́wọ́ ree"
- Inú ìrora ni Sunday Igboho wà pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́-ṣẹkẹ̀ ní àhámọ́ - Agbẹjọ́rò
- Sé lóòtọ́ ni wọ́n ti fi Sunday Igboho sílẹ̀ ní Cotonou?
- Sunday Igboho àti aya rẹ́, Ropo ni ọlọ́pàá Interpol mu ní Cotonou - Agbẹjọ́rò
- Kìí ṣe tuntun pẹ ìjọba Buhari tí mú Sunday Igboho, àmọ́ ọ̀nà àbáyọ sí ìtúsílẹ̀ rẹ̀ rèé - Agbẹnusọ Sunday Igboho
- Buhari, tú Sunday Igboho sílẹ̀ bo ṣe tú Boko Haram tó ronúpíwàda sílẹ̀ - Ladoja
Igbakeji alaga igbimọ awọn lọba lọba ipinlẹ Oyo, Oba Francis Alao, Olugbon ti Orile Igbon ti oun naa wa nibi ipade ọhun ṣalaye pe, awọn ọrọ to ni ṣe pẹlu idagbasoke Naijiria lawọn pe ipade naa fun kawọn to sọrọ lori bi wọn ṣe mu Igboho.
"Ooni lo pe wa si ipade lati sọ asọyepọ lori bi a ṣe le pada maa ṣe nkan ni itubi inubi bi ti tẹlẹ.
Ọpọ nkan lo ti bajẹ lorilẹede Naijiria lati bi ọdun melo kan sẹyin ninu eto oṣelu, ọrọ aje at'awọn nkan mii.
A fẹ ṣe atunṣe ọpọ awọn nkan yii.
A ni lati mọ nipa ohun to n lọ lọwọ lorilẹede Naijiria, a maa ba ọpọ eeyan ati oniruuru ẹgbẹ sọrọ lati ri pe nkan pada bọ sipo.
Gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba ni a mẹnu ba nibi ba ninu ipade naa.
Gbogbo ọba alade ni a maa ba sọrọ nitori asiko ti to lati ṣe atunṣe ohun to ti bajẹ," Olugbon lo sọ bẹẹ.
Amọ wọn ko sọ ohun ti wọn fi ẹnu ọrọ jona le lori nipa isẹlẹ to n waye si Sunday Igboho fun awọn akọroyin.
Alẹ ọjọ Aje ni awọn agbofinro mu Igboho ni papakọ ofurufu Cadjehoun ni Cotonou nibi ti iroyin kan ti sọ pe o ti fẹ rinrin ajo lọ si orileede Germany.
Ni bii ọsẹ mẹta sẹyin ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS kede pe awọn n wa Igboho lori ẹsun pe o ko ohun ija ogun pamọ sile, amọ o ni ko si ohun to jọ bẹẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ijọba apapọ ti paṣẹ fawọn oṣiṣẹ eleto abo lati fọwọ ofin mu Igboho nibi kibi ti wọn ba ti ri i.


















